Alfa Sule: Ọmọdé tí mò kọ́ ní lẹ́sìnì ló fún mi ní ìmísí àgbékalẹ̀ eré oníjó
Se ẹ ranti ere onijo “Alfa Sule, That is to say, o ti gan pa, awo jiginni?
Ni bii ọdun melo kan sẹyin nigba ti itakun agbaye ko tii de, ere onijo yii, ti oloyinbo n pe ni “Dance Drama” si lo gbalẹ kan.
Bo se n waye lawọn ile ẹkọ, paapaa lasiko ayẹyẹ opin ọdun, naa lo n waye lawọn ile ijọsin gbogbo, paapaa lati pe ọkan awọn eeyan pada si ọdọ Ọlọrun.
Àfìgbà tóò dúró ká jọ gbé orin tuntun wa pẹ̀lú Alhaji Mustapha Abiola jáde - Ẹnìkejì Tope Ajogbajesu
Ọpọ ọdọ si lo maa n kọrin to jade lati ara ere alujo naa kaakiri nigba naa bii ‘That is to say, o ti gan pa, eyi to di asa lasiko naa.
Amọ pupọ eeyan ni ko mọ ọkunrin to ko asa ere onijo naa de saarin wa nilẹ Yoruba, eyi to gbalẹ kan nigba naa.
Oluwa rẹ ni Oluwafemi Ajewole, ti gbogbo eeyan tun mọ si Alfa Sule.
Ara akẹkọ kan ti mo n kọ ni lẹsinni nile ni imisi ere onijo naa ti wa:
Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ lori bo se bẹrẹ ere onijo naa, Adewole ni lara akẹkọ ọmọ kekere kan ni imisi naa ti wa.
O ni ọmọ naa ni oun maa n kọ ni imọ isiro amọ ti ayọkuro ati aropọ ko tete ye ọmọ naa.
Idi si ree ti oun fi sọ ilana ayọkuro ati aropọ ninu isiro di orin kikọ, orin yii si ni ọmọde naa maa n ranti lati se amulo ilana ayọkuro ati aropọ ti oun ba gbe fun.
“Bi mo se bẹrẹ ere onijo naa ree amọ mo tun pa a ti lati lọkọ ẹkọ imọ ẹrọ ni Poly.
Sugbọn ọrọ kan ti akẹẹgbẹ mi ni kilaasi sọ nigba ta n reti olukọ wa fun wakati mẹta, ni Ọlọrun fi si mi leti lati pada sidi ere onijo naa.
Akẹẹgbẹ mi naa beere pe ‘se gbogbo wa la fi imọ ẹrọ ta n kọ yii jẹun ni?’
Ibeere naa gun mi lẹmi, mo gbadura si, ti Ọlọrun si sọ fun mi pe oun ti fi ọna ti maa gba han mi.
Lati igba naa si ni mo ti pada sidi ere alujo naa, to si di gbajugbaja ati itẹwọgba.”
Awọn Kristiẹni ijọ alasọ funfun ati Musulumi ro pe awọn ni mo fi ere onijo gbogun ti:
Alfa Sule, nigba to n salaye ọpọ ipenija to koju rẹ nidi ilana ere onijo to mu pọn naa, o salaye pe oju ri pupọ.
O ni awọn ọmọde ti ọjọ ori wọn ko ju ọdun mẹẹdogun lọ ni oun ko jọ lati sere naa, ti oye isẹ naa ko si tete ye wọn nibẹrẹ.
Bakan naa lo ni oun nikan ni oun maa n sọ gbogbo ọrọ to ba wa ninu ere onijo naa boya ni oun ọkunrin ni tabi ti obinrin.
Amọ iyawo oun lo n fọ oun obinrin bayii nigba ti oun gbe iyawo.
Pabambari ipenija to ni o tun koju oun ni ti awọn Kristiẹni to wa nijọ alasọ funfun ati awọn Musulumi ti wọn ro pe awọn ni oun fi ere onijo gbogun ti.




