Mysterious places you can't visit: Wo àwọn ibi mẹ́rin tí ènìyàn kò le fi ẹsẹ̀ tẹ̀ láyé

ÀWÒRÁN

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ní ayé ode òní, ó ṣòro láti rí ibìkan tí ènìyàn le ṣe ìnàjú lọ tí kò tíì sí lórí ayélujára ṣùgbọ́n ó ní àwọn ààyè mélòó kan tí ọwọ́jà àwọn arìnrìnàjò kò lè dé.

Bí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ààyè ìnàjú káàkiri àgbáyé ṣe máa ń wá láti gbàlejò, àwọn ibìkan wà tó jẹ́ wí pé gbọingbọin ní ilẹ̀kùn wọn wà ní títì pa fún àwọn ènìyàn láti fi ẹsẹ̀ tẹ ibẹ̀.

Àkọlé fídíò, Wọ́n jí pè mi láàrọ̀ pé ọmọ mi bímọ, ó dákú àmọ́ bí mo ṣe débẹ̀, àt'òkú ọmọ mi, àt'òkú

Onírúurú ìdí ló fa èyí, ó le jẹ́ nítorí ètò ààbò, òfin tàbí ìmọ̀ sáyẹ́ńsì, èèwọ̀ ni láti fi ẹsẹ̀ tẹ àwọn àyè yìí.

Àwọn ààyè mẹ́rin tí ènìyàn kò lè fi ẹsẹ̀ tẹ̀ tí a mú wá fún un yín nìyìí:

1. Uluru: Àpáta tí wọ́n ń pè ní ìdodo ayé

Àpáta Uluru

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Àpáta Uluru

Uluru, èyí tí wọ́n ń pè ní àpáta Ayers nígbà kan rí ló jẹ́ ibi tí àwọn arìnrìnàjò máa ń ṣe àbẹ̀wò sí ṣùgbọ́n tí wọ́n ti fi sí ara àwọn ibi tí àwọn ènìyàn kò lè dé mọ́.

Uluru tí wọ́n tún ń pè ní ìdodo ayé tó wà ní Australia jẹ́ ọ̀kan lára àwọn òkúta tó tó bi tó sì tún ga jù ní àgbáyé.

Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ rí, àwọn ènìyàn máa ń gun òkè náà láti mọ rírì ẹwà rẹ̀.

Fún àwọn ènìyàn Anangu Aborigines tí wọ́n wà nídìí àmójútó àpáta náà, ó jẹ́ àyè mímọ́ sí wọn èyí ló sì fàá tí wọ́n fi dá àwọn ènìyàn dúró láti máa gun àpáta náà ní ìbọ̀wọ̀ fún àṣà wọn.

Ní ọjọ́ karùndínlọ́gbọ̀n, oṣù kẹwàá, ọdún 2019 ni àwọn ènìyàn dá ẹsẹ̀ tẹ àpáta náà gbẹ̀yìn lẹ́yìn tí wọ́n ti fi òfin de àwọn ènìyàn láti máa gun àpáta ọ̀hún.

Fún àwọn ènìyàn Anangu, Uluru jẹ́ ẹ̀rí wí pé àwọn ẹ̀mí àìrí tó lágbára wá sílé ayé nígbà tí àwọn ènìyàn kò ì tíì máa ṣẹ̀mí.

Àwọn arìnrìnàjò ṣì le ṣe àbẹ̀wò sí ibi ìgbafẹ́ Uluru-Kata Tjuta láti lọ wòràn àpáta náà ṣùgbọ́n wọn ò lè dá ẹsẹ̀ tẹ tàbí gun àpáta náà.

2.Erékùṣù tó lóró jùlọ - "Big Burning Island: a poisoned island"

Erékùṣù tí ejò tó lóró pọ̀sí jùlọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ibí yìí ni erékùsù kejì tí ejò pọ̀ sí jùlọ ní àgbáyé, èyí tó tóbi tó hẹ́kítà márùndínláàdọ́ta, èyí tó fẹ́ẹ̀ súnmọ́ pápá ìṣéré ìgbábọ́ọ̀lù.

Ní ìpẹ̀kun Sao Paulo ní orílẹ̀ èdè Brazil ni erékùsù yìí wà.

Erékùsù Shedao tí ilẹ̀ China ló tún tóbi jùlọ ní àgbáyé.

Gẹ́gẹ́ bí onímọ̀ bàọ́lọ́jì kan, Marcelo Riberio Duarte ṣe sọ fún BBC News Brazil, ní erékùsù yìí, àwọn ejò olóró ló kún ibẹ̀ fọ́fọ́ tó jẹ́ wí pé oró wọn kò lè mú kí ẹyẹ fò mọ́ tí wan bá ti fẹnu bà á.

Riberio ní eró àwọn ejò náà lágbára lára àwọn ẹyẹ ju ti àwọn ẹranko tó ń rín nílẹ̀ lọ àti pé àwọn abo ejò ló pọ̀ ní erékùsù náà ju àwọn akọ lọ.

Àkọlé fídíò, Alfa Sule: Ọmọdé tí mò kọ́ ní lẹ́sìnì ló fún mi ní ìmísí àgbékalẹ̀ eré oníjó

Onímọ̀ ìwádìí nípa àwọn ejò olóró kan, Vidal Haddad kekere ní kò fi bẹ́ẹ̀ sí àwọn ẹranko mìíràn ní erékùsù yìí nítorí náà ẹyẹ ni àwọn ejò tó bá ti dàgbà níbẹ̀ máa ń jẹ tí àwọn kéékèèké máa ń jẹ aláǹgbá àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Ìjọba Brazil ti wá fi òfin de àwọn ènìyàn láti máa dẹ́sẹ̀ wọ erékùsù yìí nítorí àti dá ààbò bo àwọn ènìyàn àyàfi àwọn tó bá fẹ́ ṣe iṣẹ́ ìwádìí níbẹ̀ tí dókítà yóò sì tẹ̀lé wọ ibẹ̀, tí wọ́n yóò sì tẹ̀lé gbogbo ìlànà tí wọ́n bá là kalẹ̀ fún wọn.

3.Lascaux: ihò àpáta tí iṣẹ́ ọnà wà nínú rẹ̀

Lascaux: ihò àpáta tí iṣẹ́ ọnà wà nínú rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àwọn ọmọdé mẹ́rin tí wọ́n ń wá ajá wọn tó kó sínú ihò kan nínú ilẹ̀ ló ṣàwárí ihò àpáta yìí ní gúúsù orílẹ̀ èdè France lọ́dún 1940.

Ajá náà ló mú wọn lọ sí ibi tí ihò náà wà èyí tí iṣẹ́ ọnà kan tó jẹ́ àwòrán ẹṣin àti àgbọ̀nrín ló bò ó lójú.

Ní bí ọdún ẹgbẹ̀rún mẹ́tàdínlógún sẹ́yìn, iṣẹ́ ọnà yìí ló jẹ́ àpẹẹrẹ tí wọ́n ṣàwárí nígbà tí ayé wà lórúnkún pẹ̀lú ààwọ̀ ẹgbẹ̀ta àti iṣẹ́ ọnà fínfín ẹgbẹ̀rún kan.

Ogun àgbàyé kejì ṣẹ̀ṣẹ̀ ń bẹ̀rẹ̀ nígbà tí wọ́n fi ṣàwárí ṣùgbọ́n nígbà tí yóò fi di ọdún mẹ́jọ lẹ́yìn rẹ̀, ihò àpáta Lascaux ti wà ní ṣíṣí fún àwọn ènìyàn tó bá fẹ́ rí àwọn iṣẹ́ ọnà babańlá wọn.

Ní ọdún 1963 ni ìjọba ṣe ìdádúró àbẹ̀wò àwọn ènìyàn síbi àyè náà nítorí koríko ti ń hù sára ògiri ihò náà èyí tó le mú kí iṣẹ́ ọnà ọ̀hún má tọ́jọ́ lòdì sí bó ṣe wà ní ìpamọ́ kí wọ́n tó ṣe àwárí rẹ̀.

Láti bí ọgọ́ta ọdún sí àsìkò yìí, ihò inú àpáta náà ṣì wà ní títì pa fún ọmọnìyàn bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti kọ́ ohun tó farajọ́ sí ẹgbẹ́ rẹ̀ fún àwọn arìnrìnàjò tó bá fẹ́ wò ó.

4.Ilé tí wọ́n ń kó èso pamọ́ sí - "The Doomsday Vault"

Ilé tí wọ́n ń kó èso pamọ́ sí - "The Doomsday Vault"

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ní erékùṣù kan tí wọ́n ń pè ní Spitsbergen ní Norwegian Arctic Archipelago ti Svalbard, òkúta iyanrìn kan tó ga tó mítà ọgọ́fà ní ilé ìko èso pamọ́ sí.

Fún bí àádóje mítà tó ga láti ilẹ̀ àti àwọn yìnyín tó yi ká jẹ́ kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn èso tó wà nínú rẹ̀ wà ní ìpámọ́ láì bàjẹ́ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún.

Àyè ibi tí ilé ìfi èso pamọ́ sí yìí wà tí ilẹ́ mímí kìí wáyé níbẹ̀ fún ni àǹfàní láti lè fi àwọn èso náà pamọ́ síbẹ̀.

Ohun tí ibí yìí wúlò fún ni láti fi èso oúnjẹ pamọ́ fún ọjọ́ iwájú nítorí ìpèníjà le wáyé lọ́jọ́ iwájú tí àwọn èso tó bá wà níbi ìpamọ́ yìí yóò jẹ́ kí àti rí oúnjẹ rọrùn fún ẹ̀dámọnìyàn.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé gbogbo orílẹ̀ èdè àgbáyé ló ní bí wọ́n ṣe ń pa àwọn oúnjẹ wọn mọ́, ilé ìpamọ́ àwọn èso Svalbard wà fún gbogbo ayé.

Ìwádìí fi hàn wí pé kọ́kọ́rọ́ méje ni wọ́n fi ti ilé náà láti ri dájú wí pé àwọn èso tó wà nínú rẹ̀ le má bàjẹ́ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ṣùgbọ́n kò sí ènìyàn tó le fi ìdí èyí múlẹ̀ láti ọdún 2008 tí wọ́n ti ṣi gbẹ̀yìn.

Ẹ̀wẹ̀, àwọn onímọ̀ sáyẹ̀ǹsì ti ń fi ìkọlóminú hàn lórí bí àyípadà ṣe ti ń bá ojú ọjọ́ èyí tó ti ń ṣokùnfà kí àwọn yìnyín tó wà ní ibẹ̀ máa yòrò. Ní ọdún 2020, ni wọ́n ṣe àkọ́ọ́lẹ̀ pé Svalbard gbóná jùlọ.

Onímọ̀ sáyẹ̀ǹsì Kim Holmen ti àjọ Norwegian Polar sọ fún BBC wí pé àwọn ti ń ṣe àmójútó èyí.