Ọwọ́ ọlọ́pàá Osun tẹ ọ̀dọ́ mẹ̀ta pẹ̀lú ọkàn èèyàn níinú ẹrù wọn

men caught with human heart on OAU campus road

Oríṣun àwòrán, PM News

Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Osun ti tẹ awọn ọdọkunrin mẹta kan lori ẹsun fifi eeyan ṣe oogun owo lẹyinn ti wọn ka ọkan eeyan mọ wọn lọwọ.

Ninu atẹjade ti alukjoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Osun, Yemisi Opalola fi ṣọwọ si BBC Yoruba, o ni ọjọ ori awọn afurasi naa ko ju ọdun mọkanlelogun si marundinlọgbọn lọ.

Gẹgẹ bii ohun to sọ, meji lara awọn eeyan naa jẹ ẹni ọdun mọkanlelogun, nigba ti ẹni kẹta wọn jẹ ẹni ọdun marundinlọgbọn.

Atẹjajde naa ni "Ninu akitiyan ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Osun lati fọ ilu mọ lọwọ awọn ọdaran, a ti fi ṣikun ofin mu awọn ọdọ mẹta kan fun ẹsun igbenipa lati ṣẹṣo."

"Orukọ awọn afurasi naa ni Olayade Kehinde, Olufemi Oriyomi atu Raimi Sheriff."

"Ni nnkan bii aago mọkanla alẹ ni ọwọ tẹ awọn afurasi loju ọna Osogbo si fasiti OAU to wa ni Ile Ife."

Àkọlé fídíò, Alfa Sule: Ọmọdé tí mò kọ́ ní lẹ́sìnì ló fún mi ní ìmísí àgbékalẹ̀ eré oníjó

Ọkan eeyan ninu ẹru awọn afurasi

Opalola sọ pe ori alupupu ni awọn ọdọ mẹta naa wa lasiko ti awọn ọlọpaa gbiyanju lati yẹ ẹru wọn wo, amọ kaka ki wọn jẹ ki awọn ọlọpaa ṣiṣẹ wọn, ni ṣe ni wọn fẹsẹ fẹ.

Lẹyinorẹyin, ọwọ tẹ awọn eeyan naa lagbegbe Safejo, ti wọn si ba ọkan eeyan ninu eru wọn, eyii ti wọn sọ pe o jẹ ti ọkan lara awọn ọrẹ wọn.

Alukoro ọlọpaa naa fi kun pe yatọ si ọkan eeyan yi, wọn tun ba oniruru oogun abẹnugọngọ lara wọn.

Opalola ṣalaye pe ọkan lara awọn afurasi ọhun dubulẹ aisan lasiko ti iwadi n lọ lọwọ, amọ o jade laye lẹyin ti wọn gbe lọ sile iwosan, awọn si ti gbe oku rẹ lọ si ile igbokupamọsi fun ayẹwo.

O pari ọrọ rẹ pe iwadii ṣi n lọ lọwọ, awọn afurasi meji to ku yoo si foju bale ni kete ti iwadii naa ba ti pari lori ọrọ wọn.

Àkọlé fídíò, Ìwà ipá nínú ìdílé máa ń bí ìgè àti àdùbí ni tó lè já sí ikú