Seyi Makinde: Mo gbà pé mó ṣe àwọn àṣìṣe kan, kò sẹ́ni tó pé

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde/Facebook
Gomina ipinlẹ, Seyi Makinde, tun ti tẹnumọ pe oun ko ni baba isalẹ kankan.
Bakan naa lo kede pe ẹnikẹni to ba pe ara rẹ ni baba isalẹ oun, le kuro lẹyin oun lọ se atilẹyin fun oludije mii to ba wu lasiko ibo ọdun 2023.
Gomina Seyi Makinde, kede bẹẹ lasiko to n kopa lori eto ori redio kan nilu Ibadan.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Wo gbajúmọ̀ amúlùúdùn mẹ́fà tó kú láàrin oṣù márùn-ún
- Ọlọ́pàá lahun lórí afurasí tó kó oku ẹranko 183 sínú 'freezer’
- Ki ló mú bàbá fí ìbínú fọ orí ọmọ rẹ̀ oṣù kan mọlẹ?
- Wo ibi tí ọ̀rọ̀ dé dúró nípa ìjíròrò láàrin ìjọba àtàwọn ajínigbé èrò rélùwéè Kaduna
- Kí lò fa ariwo pe Wasiu Ayinde kó kúrò nílé fún Ropo, aya rẹ̀ torí pé obìnrin náà fọ léti torí obinrin miran?
- Ènìyàn 150 farapa bí ìkọlù tuntun ṣe bẹ̀rẹ̀ ní mọ́ṣáláṣí al-Aqsa
- Ooni Ilé Ife, Adeyeye Ogunwusi ti bí ọmọ míràn?
Makinde wa sọ yanya pe awọn eeyan ipinlẹ Oyo lo ni oun, kii se baba isalẹ kankan.
Nigba to n dahun ibeere lori bawọn oloselu kan to n fapa janu ninu ẹgbẹ iselu PDP se fẹsun kan pe o pa ẹgbẹ naa ti, Makinde ni oun ko ba ẹniẹni tọwọ bọwe adehun saaju ibo ọdun 2019.
"Mo gba pe mo se awọn asise kan siwa sẹyin nitori ko si ẹni ti ko le kọsẹ amọ n ko ba oloselu kankan mulẹ ohun ti maa se fun wọn ka to dibo gomina to gbe mi wọle."
O wa maa n bi mi ninu tawọn oloselu kan ba n sọ pe n ko mu adehun ta jọ fi ẹnu se sẹ, nitori n ko ni adehun kankan pẹlu ẹnikẹni.
Bakan naa lo tun tan imọlẹ si ẹsun tawọn eeyan kan fi n ẹsun kan pe oun nikan lo n da ipinnu se ninu ẹgbẹ oselu naa nipa awọn oludije ti yoo soju ẹgbẹ naa ninu ibo ọdun 2023.


















