PDP Crisis: Mo fẹ kí èmi àti Auxillary kojú ara wa lọ́dọ̀ ọlọ́pàá ní Abuja lórí ìkọlù náà

Àkọlé fídíò, PDP Crisis: Mo fẹ kí èmi àti Auxillary kojú ara wa lọ́dọ̀ ọlọ́pàá ní Abuja lórí ìkọlù náà

Laipẹ yii ni ikọlu kan waye si agba oloselu kan nipinlẹ Oyo, Alhaji Adebisi Olopoeyan lasiko ti awọn afurasi janduku kan kọ lu u.

Ni kete lẹyin ti Olopoeyan fi ẹgbẹ oselu PDP silẹ lọ si NNPP si ni isẹlẹ naa waye.

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ nipa isẹlẹ naa, Olopoeyan salaye nipa bi isẹlẹ naa se waye.

Bakan naa lo ni asaaju ajọ to n sakoso awọn ibudokọ ero nipinlẹ Oyo, PMS, Alhaji Mukaila Lamidi ni, ti pọ eeyan mọ si Auxillary ni oun fura si.

BBC Yoruba tun ba agbẹnusọ ẹgbẹ alakoso gareeji ọkọ nipinlẹ Oyo, PMS sọ̀rọ̀ lórí ìkọlù naa, ti onitọun si ni awọn ko mọ ohunkohun nipa isẹlẹ naa.