Kaduna Train attack: Ṣé lóòótọ́ ní idunadura láàrin ìjọba àti ajínigbé èrò rélùwéè Kaduna forí sanpọn?

Oríṣun àwòrán, Rotimi Amaechi/Twitter
Ibi ti ọrọ de duro lori idunadura laarin ijọba orilẹede Naijiria ati awọn agbebọn to ji awọn arinrinajo ọkọ reluwee gbe ni Kaduna ko jọ pe ọrọ wọ laarin wọn.
Idi ni pe titi di asiko ta a n ko iroyin yii jọ, awọn agbesunmọmi ọhun ṣi ko arinrinajo to fẹ ẹ to ọgọrun kan si ahamọ ni ibuba wọn.
Ikọlu ti wọn ṣe si ọkọ oju irin reluwee naa waye ni ọjọ Kejidinlọgbọn oṣu Kẹta 2022 ni Katari ni ipinlẹ Kaduna.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ki ló mú bàbá fí ìbínú fọ orí ọmọ rẹ̀ oṣù kan mọlẹ?
- Kí lò fa ariwo pe Wasiu Ayinde kó kúrò nílé fún Ropo, aya rẹ̀ torí pé obìnrin náà fọ léti torí obinrin miran?
- Ènìyàn 150 farapa bí ìkọlù tuntun ṣe bẹ̀rẹ̀ ní mọ́ṣáláṣí al-Aqsa
- Ooni Ilé Ife, Adeyeye Ogunwusi ti bí ọmọ míràn?
- Àwọn ọlọ́pàá ti mú ọmọbìnrin tó parọ́ pé wọn jí òun gbé, fi ipá ba òun lòpọ̀
- Ọ̀dọ́ afurasí adigunjalè méjì, Oyewusi àti Anini tú àṣírí bí ìyá wọn ṣe jẹ́ agbodegba wọn
- Òṣìṣẹ́ INEC kàn ku méjì, dì àwáti bí agbébọn ṣe kọlù ibùdó iforukọsilẹ
- Seyi Makinde ti sọ Auxillary di nǹkan míì sígbòrò, ọlọ́pàá gbọdọ̀ mu - Olopoeyan
- Wo ẹ̀rọ ìgbàlódé tí o lé rì sínú ọwọ́ rẹ̀ láti má a san owó ọ̀jà láì lo káàdì ATM
Ninu awọn to wa lori reluwee nigba naa, ijọba kede pe eeyan mẹjọ padanu ẹmi wọn, tawọn mẹrindinlọgbọn si farapa.
Ileeṣẹ reluwee ni awọn ko ribi kan si arinrinajo mẹtalelọgọjọ ati oṣiṣẹ reluwee meje to wa lori ọkọ naa nigba ti awọn agbebọn ṣe ikọlu si.
Ninu fọnran fidio taa ri, awọn agbesunmọmi yii sọ fun ijọba pe ki wọn mu adehun ṣẹ lori nkan tawọn n beere, kawọn to le tu awọn eeyan ti wọn ji gbe silẹ.
Ileeṣẹ iroyin Naijiria Punch jabọ pe ibeere awọn ajinigbe yii si ijọba pe ki wọn tu awọn ọgagun wọn mẹrindinlogun silẹ, jẹ eleyi ti ijọba ko faramọ.
A ko ribi fidi ọrọ yi mulẹ lati ọdọ ijọba boya wọn n duna dura pẹlu awọn ajinigbe yi tabi wọn ko bawọn sọrọ .
Bẹẹ ni ko si aridaju pe ijọba n gbe igbesẹ idunadura ti ko han si awọn araalu.
Awọn onwoye eto aabo kan sọ fun Punch pe ijọba n ba awọn agbesunmọmi yii jiroro, bẹẹ́ si ni wọn n wa ọna miran lati doola awọn arinrinajo to wa ni ahamọ.
Eleyi ti awa le fidi rẹ mulẹ ni pe, titu awọn olori agbesunmọmi silẹ ti ijọba ṣe nigba kan ri ko dẹkun ikọlu ti wọn n ṣe si araalu.
Koda ohun to sunmọ ni pe wọn n fi e owo idoola ti wọn gba ra nkan ijagun si lati koju ijọba, ti ikọlu si pọ ju tatẹyinwa lọ.
Ni Kaduna naa, Gomina Nasir El Rufai ti sọ laimọye igba pe oun ko faramọ idunadura pẹlu awọn ajinigbe.
Lawọn igba ti ikọlu waye ti awọn ajinigbe gbe araalu ,El Rufai kan bawọn kẹdun nikan ni to si ni sisan owo idoola yoo tunbọ mu kawọn ajinigbe yi laya lati tun pada wa ji eeyan gbe ni.
Eleyi ko jẹ nkan to dunmọ araalu ninu ni paapa pẹlu bi awọn ololufẹ wọn ṣe wa ni akata awọn alaburu yi.
Bi a ko ba gbagbe awọn mọlẹbi eeyan to ha si ọwọ awọn ajinigbe reluwee laipẹ yi ṣe iwọde lati fẹhonu han pe awọn ko gburo awọn eeyan wọn.
Wọn ni bi wọn wa laaye ni abi wọn ti ku, awọn ko gburo ni paapa lati ọdọ awọn ajinigbe boya wọn fẹ gba owo ni.
Amọ bi ọrọ ṣe n lọ bayi, ko daju pe awọn araalu ko ni pẹ maa gburo lati ọdọ awọn ajinigbe yii ti ijọba ko ba fi le dawọn lohun lori ibeere wọn.
Boya wọn yoo wa beere owo ni tabi wọn yoo halẹ lati pa awọn eeyan ti ijọba ko ba da awọn loun, eleyi lo ku ti a n foju sọna si lati mọ ohun ti yoo ṣẹlẹ.



















