Toddlers fed spiked Crackers: Olùdarí 'Daycare' tàwọn ọmọdé mẹ́ta tí jẹ bisikíítìi tí wọn fí igbó sí yóò fojú bá ilé ẹjọ́

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Alakoso Daycare kan ti awọn ọmọ kekeeke ti jẹ bisikiiti ti wọn yi igbo mọ, lawọn ọlọpaa ti fẹsun ṣiṣe ika fọmọde kan nilu Virginia l'Amẹrika.
Ọrọ yii jẹyọ ninu atẹjade kan ti ẹka ileeṣẹ ọlọpaa agbegbe Stanford ni orileede Amẹrika fi sita.
Gẹgẹ bi wọn ṣe sọ, ni oṣu Kẹta ọdun yii ni ọlọpaa dahun si ipe kan ti wọn ni ki wọn wa wo nkan to n ṣẹlẹ ni ile iwosan Strafford.
Ni ile iwosan naa, wọn lawọn ri awọn ọmọde mẹta kan ti ọjọ ori wọn ko ju ọdun kan lọ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Wo àwọn ibi mẹ́rin tí ènìyàn kò le fi ẹsẹ̀ tẹ̀ láyé
- Wo gbajúmọ̀ amúlùúdùn mẹ́fà tó kú láàrin oṣù márùn-ún
- Àwọn èèyàn Oyo ló ni mí, kìí ṣe Bàbá Ìsàlẹ̀ kankan - Seyi Makinde
- Ọlọ́pàá lahun lórí afurasí tó kó oku ẹranko 183 sínú 'freezer’
- Ki ló mú bàbá fí ìbínú fọ orí ọmọ rẹ̀ oṣù kan mọlẹ?
- Wo ibi tí ọ̀rọ̀ dé dúró nípa ìjíròrò láàrin ìjọba àtàwọn ajínigbé èrò rélùwéè Kaduna
- Kí lò fa ariwo pe Wasiu Ayinde kó kúrò nílé fún Ropo, aya rẹ̀ torí pé obìnrin náà fọ léti torí obinrin miran?
- Ènìyàn 150 farapa bí ìkọlù tuntun ṣe bẹ̀rẹ̀ ní mọ́ṣáláṣí al-Aqsa
- Ooni Ilé Ife, Adeyeye Ogunwusi ti bí ọmọ míràn?
Nkan taa si gbọ ni pe awọn obi wọn gbe wọn lọ si ile iwosan lẹyin ti wọn ri pe oju awọn ọmọde yi n pọn, ti wọn si n fa tikọ tikọ.
Awọn dokita ile iwosan ṣalaye fawọn agbofinro pe awọn ri ẹri pe awọn ọmọ yi ti ni alabapade eroja oogun oloro taa mọ si tetrahydrocannabinol.
Lati le mọ ibi ti ọrọ ti wọ wa, iwadii ranpẹ fihan pe ile itọju Daycare kanna lawọn ọmọ mẹta yi jijọ n lọ.
Kete ti wọn gbọ ọrọ yi ni wọn yan ọlọpaa kan lati pada lọ si itọju Daycare ọmọde ti wọn ti gbe awọn ọmọ naa wa si ile iwosan.
Nibẹ ni wọn ti ri ounjẹ ipapanu ''gold fish crackers'' ti a le pe ni bi bisikiiti tawọn ọmọde n jẹ, ti wọn fi si ẹgbẹ aga ijoko awọn ọmọ yi.
Aṣẹyinwa aṣẹyinbọ, wọn gbe bisikiiti yi lọ si ile ayẹwo laabu, ti esi to jade nibẹ si fihan pe oogun oloro igbo wa ninu eroja bisikiiti yii, iyẹn tetrahydrocannabinol.
Kini nkan ti wọn ṣe fun ẹni to ni Daycare ọmọde yi?
Arabinrin ẹni ọgọta ọdun to ni Daycare naa ko duro ki ọlọpaa wa mu, ko to lọ yọju si agọ ọlọpaa.
Nibẹ ni wọn ti fi ẹsun onigun mẹta kan lori pe o ṣe akoba fun ọmọde.
Wọn gba oniduro rẹ ni ẹgbẹrun meji dọla tii ṣe $2,000 lọwọ rẹ, ki wọn to tu silẹ lati pada sile gẹgẹ bi atẹjade ọlọpaa ṣe wi.
Bakan naa ni ile itọju ọmọde Daycare yi ti jọwọ iwe aṣẹ wọn.





















