Tinubu 2023: Ọ̀nà tí Bola Tinubu fẹ́ gbà ṣẹ́gun ìgbésùnmọ̀mí rèé tó fi ń ṣèlérí

Oríṣun àwòrán, Babajide Sanwo-Olu Twitter
Agba oṣelu ninu ẹgbẹ oṣelu All Progressive Congress (APC) Bola Ahmed Tinubu ti ṣe ileri kan lọjọ Abamẹta pe oun yoo gba Naijiria la lọwọ bi wọn ba le dibo yan oun gẹgẹ bi aarẹ.
O jẹjẹ yii lasiko to n ba ọgọọrọ awọn ọdọ to kora jọ ni gbagede Mobolaji Johnson l'Eko nitori ipolongo fun idbo yan Tinubu lọ dun 2023.
"Naijiria to wa ni isọ́kan ni ala wa", Tinubu sọ fun awọn ọdọ naa. Naijiria ti ko ni wahala ni ifọkansin wa. Naijria ti ko si iwa ipa, ti ko si igbesunmọmi. A si ṣeleri fun yin pe a o gbe e lee yin lọwọ. Ẹyin ni ọjọ ọla wa".

Oríṣun àwòrán, Babajide Sanwo-Olu
Tinubu ni oun n lọ du ipo aarẹ lati lọ ṣoju awọn ọdọ ni o si ni nipas irẹpọ nikan ni ala Naijria fi le ṣẹ.
"Mo fẹ jẹ aarẹ fun yin ni, ẹ wá mi lọ sibẹ. Ẹ fi ara yin jin. Ko si awawi mọ, ikoro to gẹ, aisi irẹpọ ko dopin. Gbogbo taa si ni lati ṣe ni ki a jẹ Naijiria isọkan ni ilẹ Afirika.
Awọn ọdọ to mọ ohun ti wọn n ṣe
Gbagbagba lẹgb Asiwaju Bola Tinubu ni gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu wa nibi iwọde awọn ọdọ yii lọjọ Satide to n sọ fun wọn pe awọn ọdọ iha Guusu-Iwọ Oorun ti fi ipinu wọn han ninu pipolongo fun Tinubu gẹgẹ bi aarẹ.
Sanwo-Olu sọ ọrọ yii loju opo Twitter rẹ ninu ọpọlọpọ atẹjade to fi sita.
"Mo dara pọ mọ awọn ọdọ iha Guusu- Iwọ Oorun Naijiria nibi iwọde wọn... lati ṣe atilẹyin fun erongba Asiwaju Bola Tinubu lati di aarẹ Naijria".
Sanwo-Olu to kọwọ rin pẹlu igbakeji rẹ, Obafemi Hamzat atawọn adari ẹgbẹ oṣelu APC mii nilẹ Yoruba ni awọn ti ri akitiyan ati agbara ti awọn ọdọ "wa" ni lati ṣiṣẹ fun aṣeyọri erongba Asiwaju Bola Tinubu to ni ifarajin lati fara ṣiṣẹ fun awọn eeyan orilẹede Naijiria.
"Adari wa, Asiwaju Bola Tinubu ri iwuri gidi ninu atilyin to ti gba latọjọ yii lọd awọn ọdọ o si ti pinu lati gba eku ida idari Naijiria pẹlu oreọfẹ Ọlọrun ati ifẹ awọn eniyan fun Naijiria to dara to si lọrọ to tun wa ni isọkan.

Oríṣun àwòrán, Babajide Sanwo-Olu Twitter















