Okùnrin ẹni ọdú 45 kó sí gbaga ọlọ́pàá lẹ́yìn tó jí ọmọ gbé nínú ṣọ́ọ̀ṣì

Police

Oríṣun àwòrán, Abimbola Oyeyemi

Okunrin ẹni ọdun marundinlogoji kan, Sakiru Famuyiwa, ti ko si gbaga ọlọpa ipinlẹ Ogun lori ẹsun pe o ji ọmọ meji gbe nile ijọsin.

Ileeṣẹ ọlọpaa ni agbegbe Ijeja, niluu Abeokuta ni okunrin ọhun ti ji awọn ọmọ ọhun gbe lasiko ti isin n lọ lọwọ.

Ọwọ tẹ afursasi naa lẹyin ti awọn eeyan agbegbe ibi ti iṣẹlẹ naa ti waye ke si awọn ọlọpaa to wa ni Ibara.

Iroyin ni asiko ti isin ayajọ ọjọ "Good Friday" n lọ lọwọ ni Sakiru, atawọn meji mii ti wọn ti na papa bora yọ kẹlẹ-kẹlẹ wọ inu ile ijọsin ijọ alaṣọ funfun kan ni Ijeja, ti wọn si ji awọn ọmọ kekere naa gbe.

Ọjọ ori awọn ọmọ naa ko ju ọdun meji si mẹta lọ.

Ninu atẹjade ti alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, DSP Abimbola Oyeyemi fi ṣọwọ si BBC Yoruba, o ni ọkan lara awọn ọmọ ijọ naa lo ke gbajare lasiko ti wọn n gbe awọn ọmọ naa lọ ti ọwọ to tẹ afurasi ọhun.

Àkọlé fídíò, Alfa Sule: Ọmọdé tí mò kọ́ ní lẹ́sìnì ló fún mi ní ìmísí àgbékalẹ̀ eré oníjó

Lẹyin naa ni ọga ọlọpaa Ibara, CSP Nasirudeen Oyedele ko awọn akọṣẹmọṣẹ ọlọpaa lọ sibẹ, ti wọn si gba afurasi ọhun lọwọ awọn eeyan to fẹ lu u pa.

Ẹwẹ, kọmiṣọna ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Lanre Bankole ti ni ki wọn gbe afurasi naa lọ si ẹka ileeṣẹ ọlọpaa to n ṣe iwadii ijinigbe fun iwadii to peye.

O tun paṣẹ pe ki wọn ṣawari awọn afurasi to ti na papa bora ki wọn foju wina ofin.

Àkọlé fídíò, Ìwà ipá nínú ìdílé máa ń bí ìgè àti àdùbí ni tó lè já sí ikú