Seyi Makinde: Gbogbo owó ìlú táwọn APC tó ṣe ijoba tẹ́lẹ̀ kó jẹ la ó gbà padà

Gomina Ìpínlẹ̀ Oyo Seyi Makinde ti kede pe ko ni si aye fún àwọn to n kowo Ìpínlẹ̀ Oyo jẹ.
Gomina n sọ eyi lori eto ori Redio Splash 105.5 FM kan ni Oyo nibi to ti ń sọ pe ijọba òun sì ni ifarajin lati rii pe wọn gba gbogbo owo titi de kobo to kere ju nínú owó Ìpínlẹ̀ Oyo to ni awọn ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú APC kan to wa ninu ijọba to kúrò lori oye kó jẹ.
"Iṣejọba mi ti rii pe a mu ayipada wa ninu awọn nkan amayedẹrun àtàwọn ẹ̀ka míì tó nílò amojuto torí a ti di awọn alafo àti adanu".
Ninu atẹjade kan tí akọ̀wé àgbà si ijọba Seyi Makinde, Taiwo Adisa fi sita, ó gbé ọrọ gomina fúnra rẹ jáde to sọ pé ìjọba òun ń lépa awọn oloye ńlá ńlá kan ninu ẹgbẹ́ òṣèlú APC Oyo ti wọn fi awọn orukọ Ileeṣẹ kan ji owo to to biliíọ̀nù méjìlá sì meedogun to jẹ owo Ìpínlẹ̀ Oyo.
O fi kun un pé ijọba yoo gba tọ wọn leyin awon yoo si gba owo ìlú pada.
Ó tẹnu mọ ọ pe ijoba oun gbé igbesẹ ńlá láti di gbogbo ọna ti ẹnikẹ́ni le gba ji owo, ó ní "bí a kò bá di àwọn ihò náà, a ó bá má de ibi tí a dé yìí".
Ó tún ṣàlàyé pé: "Lakọkọ, a ṣe ìwádìí awọn oṣiṣẹ àtàwọn ayédèrú oṣiṣẹ tí wọn sì yọ wọn ní isẹ.
"Wọn ti wá nibẹ kí àwa tó dé sugbọn àwa pinu gẹ́gẹ́ bí ijoba pé a ó ní fi àkókò ṣòfò rara.















