Ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Osun ti mú ọlọ́dẹ tó yìnbọn pa ìmàámù dípò ẹran ẹtu

A lo aworan yii fun akawe lasan ni, kii sẹ ti ọdẹ to yinbọn paayan nipinlẹ Osun.

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán, A lo aworan yii fun akawe lasan ni, kii sẹ ti ọdẹ to yinbọn paayan nipinlẹ Osun.

Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Osun ti mu arakunrin kan to jẹ ọdẹ apẹran, ti wọn lo pa baba agba ẹni ọdun mejidinlọgọrin nijọba ibilẹ Aiyedaade.

Wọn fi ẹsun kan Sulaimon Jimoh pe o pa imaamu abule Alaguntan, nilu Orile Owu, Ọgbẹni Adegun Yusuf lọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kẹrin, ọdun 2022.

Gẹgẹ bi iroyin ti Nigerian Tribune gbe jade, Ọgbẹni Jimoh sọ fun awọn ọlọpaa pe ẹran Ẹtu ni oun ri lasiko ti oun n ṣe ọdẹ ninu igbo.

Ti oun si yinbọn mọ lati ọ̀ọ́kán. Amọ iyalẹnu lo jẹ nigba ti oun sunmọ ẹranko ti oun pa lati gbe, ti oun si ba oku baba agba naa dipo ẹran Ẹtu.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Osun, Yemisi Opalola sọ pe ọmọ baba naa lo fi ẹjọ sun ni agọ ọlọpaa, ti ọwọ fi tẹ afurasi naa.

Gẹgẹ bo sẹ sọ, o ni abule Alaguntan ni arakunrin ọlọde naa ati oloogbe n gbe.

Opalola sọ pe ni kete ti iwadii ba pari ni wọn o gbe afurasi naa lọ si ile ẹjọ.

Àkọlé fídíò, Adewole Quyum: Ọdún10 ni mo ti ń kọ́ 'welder' mo ti ṣe ọ̀kadà tó ń lo 'generator'

Iru iṣẹlẹ yii ti waye ri nipinlẹ Ondo

Ninu oṣu Kejila, ọdun 2021, ni ọwọ ọlọpaa tẹ arakunrin ọlọdẹ kan, Ismaila Ojo, ti wọn lo pa ara abule Ita-Merin, nitosi ilu Ọrẹ.

Iroyin sọ pe Arakunrin Ismaila Ojo, yinbọb pa alamuleti rẹ to jẹ ẹni aadọrin ọdun, nibi ti onithun ti n ṣe igbọnsẹ ninu igbo to wa lẹyin ile wọn.

Àkọlé fídíò, Kò sí ńkan ti ọkùnrin ń ṣe tí obìnrin kò le ṣe- Afusat Adeniyi tó ń tún 'Pumping Machine'

Ṣugbọn ninu ọrọ to sọ, ọlọde naa, Ojo, sọ fun awọn ọlọpaa pe oun n dan ibọn oun wo ni ni bi aago mẹta oru ọjọ naa.

O ni ẹranko ni oun ri, ti oun si yinmọ mọ.

Àkọlé fídíò, Banji Akitoye: Yoruba Nation nìkan ni 'Only Solution' lásìkò yíì, A kò kórira ẹ̀yà tó kù

Amọ baba agba naa ni oun ba ninu agbara ẹjẹ, nigba ti oun fẹ ẹ gbe ẹran ti oun pa.

Lẹyin ọjọ diẹ ni baba naa ku si ileewosan.

Àkọlé fídíò, Oluyemisi Orisabiyi: Ẹ̀ẹ̀mẹta péré làwọn òṣìṣẹ́ KAI bẹ̀ mí wò, mo kọ̀wé sí wọn lái rí èsì