Portable: Ẹ̀yin tẹ́ẹ ní mo máa sá bí ẹsẹ̀ mi bá tẹ London, ojú yín ti jáa

Oríṣun àwòrán, Portable
Gbajugbaja ọdọ olorin ọmọ orilẹede Naijiria, Habeeb Okikiola ti ọpọlọpọ mọ si Portable ti fi aworan ati fidio ara r sita to fi sọ oko ọrọ pada si awọn to n bu ẹnu atẹ lu lilọ si ilu Oyinbo rẹ pe ko le ṣee ṣe.
Lọwọlọwọ, Portable ti balẹ si UK eyi to si jẹ igba akọkọ rẹ.
Bi ẹ ko ba gbagba, oun ni ọdọkunrin olorin atapatadide kan ti irawọ dede burẹkẹ to bẹrẹ si ni tan kaakiri agbara lẹyin orin rẹ to kọ "Zazu Zeh" ati ọpọlọpọ ọrọ̀ inu orin naa ti awọn eeyan agbaye gba tiẹ gidi.

Oríṣun àwòrán, Portable
Bo tilẹ jẹ pe ọpọ eniya lori ayelujara lo n bu ẹnu atẹ lu iru ihuwasi olorin yii pe ko ṣe bii eeyan gidi pẹlu igbo mimu, ọti mimu ti oju yoo ti lẹri ni ọpọlọpọ igba to ba jade lati sọrọ tabi kọrin ti wọn si tun n ni ẹni to baa gun ọṣẹ oogun to lo ṣe iṣẹ nla gan, awọn to jẹ tirẹ to si n gbadun ihuwasi ati iṣẹ rẹ ni keeta lasan ni awọn ti ko fẹran rẹ n ṣe ati pe ogo rẹ to bu jade lo n bi wọn ninu.
Awọn iwe iroyin abẹle kan royin ni ọjọ diẹ sẹyin pe oniṣowo nla kan Emeka Okonkwo ti awọn eeyan n pe ni E-Money lo sanwo ibẹwo Portable lọ si UK.
Bo ṣe wa nibẹ lọhun ni gbajumọ olorin yii ti bọ si oju opo Instagram rẹ pẹlu fidio to fi sita eyi ti ọrọ inu rẹ ati akọle ori rẹ jọ pe o n ta ọrọ ba awọn kan to jẹ ọta rẹ ni.
"Wọn ni mo maa sa bi wọn ba gbe mi lọ si ilu London, mo ti wa ni London bayii o, mo n jaye ori mi mo n ṣe 'Bizza' ni London, wọn ti sanwo baalu mi o".
Pásítọ̀ olówó kan ní UK ti ta Portable lọ́rẹ kàbìtì-kàbìtì, ẹ wo bó ṣe ń gbá yììn lọ́hùún
Portable ninu fidio mii to tun fi sita lo ti jẹ ko di mimọ faraye pe Pasitọ kan to n gbe ni UK amọ to jẹ ọmọ orilẹede Naijiria, Pasitọ Tobi Adegboyega tun ti fun oun ni ẹbun owo 1.8 miliọnu.
Pasitọ ọhun ni oludasilẹ ijọ Salvation Proclaimers Anointed Church to wa ni London, England to si gbalejo olorin Portable.
"Mo wọ London bayii, owo ti fẹ ṣe mi léṣe o, mo wa nibi pẹlu Pasitọ Tobi," Portable sọ eyi ninu fidio bo ṣe n gba yiin ninu ọla ati to n fi owo gọbọi rẹ ṣe faari".
Olorin "Zazu Zeh" naa fi atẹjade to fi dupẹ lọwọ E-Money ati Pasitọ Tobi sita to si n rọjo adura le alaanu rẹ yii lori.


















