Sunday igboho: Wole Soyinka sàbẹ̀wò si Igboho Òòsà ní Cotonou

Sunday Igboho

Oríṣun àwòrán, Sunday Igboho

Ọjọgbọn ati onkowe, Wole Soyinka ti sabẹwo si ajijagbara fun ilẹ Yoruba, Sunday Igboho ni orilẹede Benin Republic.

Ninu akọjade ti Igboho fi si oju opo Instagram rẹ lo ti ṣalaye bi inu ohun ṣe dun lati gbalejo Soyinka.

'Inu mi dun, ayọ mi si kun lati gbalejọ eniyan nla to jẹ baba fun mi lati ṣabẹwo si mi.''

''Mo gbadura pe agba wọn a dalẹ pẹlu ẹmi gigun.''

Lara awọn eniyan to fesi si ọrọ naa lori ẹrọ ayelujara ki Soyinka fun igbesẹ akin naa to gbe.

Àkọlé fídíò, Èmi nìkan ni ikú Alaafin dùn jù ní gbogbo ayé yìí torí èmi nìkàn ṣoṣo ni mo mọ̀ ǹkan ... - Baba Kekere

Ki ni ipa ti Soyinka ko ninu itusilẹ Sunday Igboho?

Iroyin sọ pe niṣe ni awọn eniyan bo Ọjọgbọn Wole Soyinka witiwiti ni ibode Seme ni Ọjọ Isinmi lasiko to fẹ wọ orilẹede Benin Republic.

Sunday Igboho ṣẹṣẹ jajabọ ni atimọle lẹyin ti ijọba Naijiria fi ẹsun iditẹgbajọba kan an.

Laipẹ yii ni Sunday Igboho fi da awọn ọmọ Yoruba loju pe oun bọ ni ile pada, ti ko si ni pẹ rara.

Àkọlé fídíò, Basorun Akinade Ayoola Yusuf: Ìsìnkú Aláàfin Oyo àti Ooni Ile Ife yàtọ̀ nílẹ̀ Oodua

Agbẹnusọ fun ẹgbẹ Ilana Ọmọ Oodua, Maxwell Adeleye to fi ṣọwọ si BBC Yoruba ninu atẹjade ranpẹ to fi ṣọwọ ipade abẹwo lasan ni laarin awọn akin mẹta to gbe Sunday Igboho jade lẹwọn.

Awọn mẹta to darukọ ọhun ni Ọjọgbọn Wole Soyinka, Wale Adeniran ati Ọjọgbn Banji Akintoye to si ni ipade atilẹkun mri ṣe ni wọn ṣe pẹlu Oloye Sunday Igboho ni ọjọ Kini oṣu Karun dun 2022 ni Cotonou, orilẹede Benin Republic.