US Tornado: Ó lé ní ọgọrùn èèyàn tí ìjì líle tí pàdánù ẹ̀mí wọ́n ní Amẹ́ríkà

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Aarẹ orileede Amẹrika Joe Biden ti sọ pe iji lile to ṣekọlu si awọn ipinlẹ mẹfa to si pa ọkẹ aimọye eeyan lo lagbara julọ ninu akọsilẹ ilẹ naa.
O kere tan eeyan ọgọrun lo ti ba iṣẹlẹ naa lọ ni Kentucky nikan nibi to ti pa odidi ilu ati awọn ileto rẹ.
Aarẹ sọ pe ijọba apapọ yoo ṣa gbogbo apa rẹ lati ri pe awọn mu iranwọ ba agbegbe to faragba iṣẹlẹ yi.
- Wo àwọn orílẹ̀èdè tó ṣeéṣe kí omi parẹ́ láìpẹ́.
- Ìjì líle mú ẹ̀mí èèyàn 1000 lọ, odidi ìlú kan bàjẹ́
- Arákùnrin kan r'ẹ́wọ̀n ọdún 24 he lórí ẹ̀sùn ìbálòpọ̀ pẹlú ọmọ ìkókó
- Ọlọ́pàá ti kó àwọn afurasí tí wọ́n bá òkú Demilade nínú 'cooler' nílé wọ́n ni Ekiti lọ sílé ẹjọ́
- Ìjì tó hú igi ńlá ní ìtẹ́ òkú l'Eko ba ibojì òkú 50 jẹ́, àwọn ẹbí sáré lọ w'òkú wọn
- Àtunbọ̀tán òjò òwúrọ̀ ọjọ́ ajé nílùú Eko
Iji lile taa n wi yi ṣe ikọlu si awọn ilu nla ni Amẹrika to si ba ọpọ ile ati ọfisi jẹ.
Ileeṣẹ to n mojuto bi oju ọjọ ṣe ri sọ pe awọn ti gba iroyin nipa iji lile to fẹ ẹ to mẹrindinlogoji to kọlu awọn ilu bi Illinois, Kentucky, Tennessee, Missouri, Arkansas ati Mississippi.
Ni Mayfield atẹgun lile kọlu ileeṣẹ kan ti eeyan to le ni ọgọrun ti n ṣiṣẹ to si ṣe pe eeyan ogoji nikan lo ye iṣẹlẹ ile wiwo yi.

Oríṣun àwòrán, Reuters

Oríṣun àwòrán, Reuters
Iṣẹ n lọ lọwọ lati ọdọ awọn adoola ẹmi lati ri pe wọn ko awọn eeyan yọ lọwọ ijamba yi.
Gomina Andy Beshear sọ pe nkan naa kọja afẹnusọ to si ni ọpọ ẹmi ni yoo lọ si ti awọn ile mii ba tun dawo.
Ipenija nla leleyijẹ fawọn adoola nitori ọkẹ aimọye eeyan ni ko lanfaani lati ri ina mọnamọna tabi omi to ṣe mu lasiko yi.














