Ọlọ́pàá ti kó àwọn afurasí tí wọ́n bá òkú Demilade nínú 'cooler' nílé wọ́n ni Ekiti lọ sílé ẹjọ́

Demilade ati awọn afurasi

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ ti ko awọn afurasi to pa ọmọ ọdun meje, Demilade Fadare nilu Ado Ekiti.

Ọjọ Iṣẹgun ni iroyin jade pe wọn ba oku Demilade ninu cooler, ninu ile awọn afurasi naa ni agbegbe Adehun.

Iroyin sọ pe ọjọ Aje, ọjọ kẹfa, oṣu Kejila, ni wọn ran ọmọ naa niṣẹ, amọ ko pada sile.

Gbogbo igbiyanju wọn lati ri lo ja si ofo, ko to o di pe wọn ri oku rẹ ti wọn ti ge ẹya ara rẹ ninu nkan amounjẹ gbona, ninu ile pasitọ kan lẹgbẹ ile wọn.

Kia si ni ọlọpaa mu awọn to ni ile naa.

Amọ iroyin sọ pe ọmọ pasitọ naa kan to jẹ alarun ọpọlọ lo pa ọmọdebinrin naa, ṣugbọn ti awọn obi rẹ ba a tọju oku naa.

Lẹyin iṣẹlẹ naa ni awọn ara adugbo dana sun ile naa.

Ile yii ni wọn ti ri oku ọmọ ọdun meje naa, amọ awọn ara adugbo ti dana sun
Àkọlé àwòrán, Ile yii ni wọn ti ri oku ọmọ ọdun meje naa, amọ awọn ara adugbo ti dana sun