Ọkùnrin kan pokùn so lẹ́yìn tó pàdánù N150,000 owó iléèṣẹ́ sórí tẹ́tẹ́

Ẹni kan to n ta tẹtẹ lori foonu rẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ọkunrin kan ti gbẹmi ara rẹ nilu Abuja, lẹyin to padanu ẹgbẹrun lọna aadọjọ Naira sori tẹtẹ.

Iroyin sọ pe ni agbegbe Pegi, nijọba ibilẹ Kuje ni Arakunrin Adegbite ti pa ara rẹ.

A gbọ pe ọga rẹ nibi to ti n ṣiṣẹ lo ko owo naa fun lati san fun awọn oṣiṣẹ akẹẹgbẹ rẹ, ṣugbọn o fi owo naa ta tẹtẹ nireti pe oun yoo jere rẹpẹtẹ, ko to o fi owo ṣe nkan ti wọn ran.

Amọ, o padanu gbogbo owo naa sinu tẹtẹ to ta.

Àkọlé fídíò, Sport Betting: Idí rèé tí àwọn ọ̀dọ́ kan fi n ta tẹ́tẹ́...

Ọrẹ oloogbe to ba iwe iroyin Punch sọ pe iyalẹnu lo jẹ fun oun lati gbọ pe Adegbite pa ara rẹ.

O ni lootọ, ọga rẹ lo ko owo naa fun, amọ o fi ta tẹtẹ ni ṣọọbu kan ti wsn ti n ta tẹtẹ lori bọọlu.

Àkọlé fídíò, Ìdí tí Tòmátò ẹ̀sà kò ṣe dára fún ìlera yín; wo àwọn kókó márùn-ún yìí

"Awọn ifẹsẹwọnsẹ to ta tẹtẹ le lori ko lọ bo sẹ lero."

"Ni owurọ ọjọ keji, awọn alajọgbele rẹ ko ri ko jade. Wọn ṣakiyesi pe o wa ninu ile.

Eyi si lo mu ki wọn o ja ilẹkun rẹ, ti wọn fi ba to ti pokunso lara faanu."

Àkọlé fídíò, Teslim Thunder Balogun: Àwọn oní-Tomato, aláta, oníṣu á máa kó ọjà wọn lọ́fẹ̀ẹ́ sínú ọkọ̀