ASP Olufemi Ajisafe: Ọlọ́pàá tó ti fẹ̀yìn tì ní ọlọ́pàá ẹgbẹ́ mi jú òun sẹ́wọ̀n torí òun kọ̀ láti fún un ní N100,000 owó rìbá

ASP Olufemi Ajisafe

Oríṣun àwòrán, Punch

Yoruba bọ, wọn ni ọna ọfun, ọna ọrun, ati pe iṣẹ ti ori ba ran onikaluku lo n ṣee.

Ọlọpaa kan to ti fẹyinti lẹnu iṣẹ bayii, ASP Olufemi Ajisafe lo sọ pe ti oun ko ba ni paarọ, airiṣẹ lo mu ki oun gbaṣẹ ọlọpaa.

ASP Ajisafe ṣalaye ọrọ yii fun iwe iroyin Punch ninu ifọrọwerọ to ṣe pẹlu iwe iroyin naa laipẹ yii.

Àkọlé fídíò, 'Ǹkan tí ẹ̀gbọ́n mi gangan ṣe fún mi ní Libya, mi ò kí ń lè sọ fún ìyá mi àmọ́ pllú omíjé kíkorò ...'

Ọgbẹni Ajisafe, ẹni ọdun marunlelọgọta sọ pe iṣẹ bọ lọwọ oun lo jẹ ki oun darapọ mọ iṣẹ ọlọpaa kii ṣe pe o ti ọkan oun wa.

Ajisafe ni ọrẹ oun to n ṣiṣẹ ọlọpaa lo gboun ni oun ba pade ni bank kan nibi to ti jẹ ọkan lara awọn ẹṣọ banki ọhun.

ASP Ajisafe ni ọrẹ oun yii lo gba oun ni imọran lati gbaṣẹ naa lọdun 1981.

''Ipinlẹ Ondo ni wọn kọkọ gbe mi lọ ki wọn to dami pada si ipinlẹ Eko.

Ọdun mọkandinlogun ni mo lo lẹnu iṣẹ ọlọpaa ki n to gboye insipẹkitọ.

Nitori ko si nkan mii ti mo le maa ṣe lo jẹ ki n gba iṣẹ ọlọpaa nigba naa, bi bẹẹ kọ, n ko ba ti gbaa.

Bo ya n ko ba ti kabaamọọ pe mo ṣiṣẹ ọlọpaa amọ ohun ti wọn fi oju mi ri buru jai.

Iṣẹ to dara ni iṣẹ ọlọpaa ti a ba ṣee gẹgẹ bi idanilẹkọọ ti a gba wi pe a gbọdọ sọ otitọ ati pe a ni lati yago fun iwa ajẹbanu.

Ṣugbọn nigba ti a bẹrẹ iṣẹ tan, a ri pe lati oke kan ni iwa ibajẹ ninu iṣẹ ọlọpaa ti bẹrẹ.

Awọn ọga ninu iṣẹ ọlọpaa lo maa n ran awọn ọmọlẹyin niṣẹ lati lọ gba owo wa.

Awọn kan ninu iṣẹ ọlọpaa gbimọ pọ ju mi si ẹwọn lori ẹṣẹ aimọdi, lẹyin ti mo kọ lati fun wọn ni N100,000 owo riba.

Wọn ni awọn awọn kan lo kaadi idanimọ mi lati jale.

Ohun to ṣẹlẹ ni pe kaadi idanimọ mi ti kọkọ sọnu eleyii ti mo si ṣe gbogbo ohun to yẹ ki n ṣe lori rẹ ki n to gba omiran.

Lẹyin bi ọdun mẹfa ti iṣẹlẹ yii ṣẹlẹ tan ni wọn lawọn mu awọn ole kan pẹlu kaadi idnimọ mi lọwọ rẹ.

Wọn kọ lati fi kaadi han mi ati pe nọmba to wa lori kaadi idanimọ ọhu yatọ si temi, orukọ wa nikan lo papọ.

Bi ọdun mẹta ni mo fi wa lẹwọn nigba ti ẹjọ yii n lọwọ eleyii ti wọn ko si fun mi ni owo oṣu kankan.

Ṣugbọn mo dupẹ lọwọ Ọlọrun pe ori ko mi yọ nigbẹyin gbẹyin,'' ASP Ajisafe lo sọ bẹẹ.