Ìjọba ìpínlẹ̀ Osun dóòlà ọmọ ọdún méje tí alágbàtọ́ rẹ̀ n fìyà jẹ

Oríṣun àwòrán, daily post
Ileeṣẹ to n mojuto ọrọ awọn obinrin ati ọmọde nipinlẹ Osun ti doola ọmọbinrin ọmọ ọdun meje kan lọwọ ibatan rẹ to n fiyajẹ.
Ọdọ ibatan yii ni ọmọdebinrin naa n gbe, to si jẹ alagbatọ rẹ.
Iroyin sọ pe ọjọ diẹ sẹyin, ọjọ keji oṣu Kejila, ọdun 2021 ni wọn doola ọmọ naa nilu Osogbo, pẹlu ajọṣepọ ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Osun.
Kọmisanna ileeṣẹ ijọba ọhun. Amofin Olabukola Olaboopo to ba awọn akọroyin sọrọ lori iṣẹlẹ naa sọ pe ipo ti wọn ba ọmọ ọhun ko dara rara.
- Ọkùnrin kan pokùn so lẹ́yìn tó pàdánù N150,000 owó iléèṣẹ́ sórí tẹ́tẹ́
- Èèyàn méjì tó ṣẹ̀ṣẹ̀ gba Jesu gún pasítọ̀ ìjọ RCCG pa nínú ṣọ́ọ́ṣì l'Eko
- Fadeyi Oloro wà ní ìdúbúlẹ̀ àìsàn, ẹ jọ́wọ́ ẹ rànwá lọ́wọ́ - Foluke Daramola
- Gbogbo àwọn tó lọ́wọ́ nínú ikú Sylvester Oromoni kò ní lọ láì jìyà lábẹ́ òfin - Buhari
- Ẹ̀jọ́ àtí ìwádìí ikú Timothy Adegoke ti kúró lọ́dọ̀ọ wa nípinlẹ̀ Osun- Agbẹnusọ Ọlọ́pàá Oṣun
Olaboopo ni ẹyinkule ile anti ọmọ naa, nibi to da bi akitan, ni awọn ti ba ọmọdebinrin naa.
O ni ẹẹkan lọsẹ ni wọn ma n fun ni ounjẹ, ti wọn si fi silẹ ko ma a dani kan gbe ni ẹyinkule ile.
Bakan naa lo sọ pe inu aarẹ ni ọmọ naa wa, ti ko si ni okun kankan ninu.
"O ti rù gidi, ti ko si le da duro funra rẹ, bẹẹni awọn egungun kan ti kan lara rẹ."
Wọn ti gbe ọmọ naa lọ sileewosan fun itọju bayii.
Agbẹnusọ ọlọpaa nipinlẹ Osun, Yemisi Oplalola naa sọ ninu atẹjade pe wọn ti mu anti ọmọ naa, ti wọn pe orukọ rẹ ni Olanrewaju Adenike fun ẹsun lilo ọmọ ni ilokulo.












