Ohun tí a mọ̀ rèé nípa ẹ̀sùn ìfipábánilòpọ̀ tí olóyún fi kan sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ lórí rédíò Gbenga Filani

Oríṣun àwòrán, Owuye
Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ondo ti fesi si ọrọ to gbode nipa gbajugbaja sọrọsọr ori redio nii Gbenga Filani ti eeyan kan fsun kan pe o fipa ba oun lo pọ.
Alukoro ileesẹ ọlọpaa arabinrin DSP Funmilayo Odunlami ṣalaye fun BBC pe awọn n ṣe iwadii lori ọrọ naa.
Odunlami ko sọ pato boya Filani wa ni akata awọn ọlọpaa amọ o ni awọn gbọ si iṣẹlẹ naa atipe wọn yoo maa fi to awọn akọroyin leti bi iwadii ṣe n tẹsiwaju.
- Yajo Yajo: Soun Ogbomosho ti jáde láyé!
- Oyìnbó ẹni ọdún 56 tí mo fẹ́ ní ìhùwàsí gidi ju ọ̀dọ́bìnrin ọmọ Nàìjíríà lọ - Ọmọ Nàìjíríà tó fẹ́ arúgbó
- Àwọn ajínigbé pa Pásítọ̀ kan, jí obìrin kan, ọmọ rẹ̀ mẹ́rin gbé lọ
- Pásítọ̀ onísọjí tó fí ipá bá olóyún oṣù mẹ́jọ sùn ní Ondo, ohun tí a mọ̀ rèé
- Fásitì fi ọwọ́ òsì júwe ilé fún olùkọ́ tó nawọ́ eré ìfẹ́ sí akẹ́kọ̀ọ́
- Ìpínlẹ̀ Bauchi àti Kaduna láti máà tẹ àwọn afipábánilopọ̀ lọ́dàá
Nigba ti BBC beere lọwọ rẹ nipa aworan kan to gbode eyi to ṣafihan eeyan kan to jọ Gbenga Fiulani ti wọn fẹwọn de lọwọ,Odunlami sọpe oun ko mọ nipa rẹ.
''Ṣẹ mọ pe orisirisi akọle lawọn akọroyin maa n kọ. Nipa ti aworan yẹn, mi o le sọ boya wn ṣẹṣẹ ya aworan naa ni tabi ko ti pẹ''
''Mi o si nibẹ nigba ti wọn mu amọ iwadii n tẹsiwaju lori ọrọ yi.''
Ohun ti awọn ileeṣẹ iroyin Naijiria n ja bọ
Ohun to ye wa nipa ọrọ yi ni pe laipẹ yi ni arabinrin kan to pe orukọ ara rẹ ni Bukola sọrọ ninu fọnran kan pe Gbenga Filani fi ipa ba oun lo pọ.
Ninu ohun to jọ ifọrọwanilẹnuwo pẹlu awọn akọroyin, a gbọ ti arabinrin yi ṣalaye bi Gbenga Filani ti ṣe fi ọgbọn ati ete fipa ba lo pọ toun ti pe o jẹ aboyun.
Arabinrin naa sọ pe eto ile ijọsin kan loun fẹ lo kopa ninu rẹ ki Filani to da oun duro to si ni ki oun kunlẹ.
''O fi ọwọ tẹ ikun mi to si ni ọmọ inu mi ti kọri si ẹgbẹ dipo isalẹ to yẹ ko kọju si.O wa sọ pe oun yoo ṣiṣẹ kan fun mi ti ọmọ yoo fi yi ori pada''
O tẹsiwaju pe Filani mu oun wọ inu iyara kan lọ nile ijọsin to si ni ki oun bọ sikẹti ati pata rẹ.
''O wa ni ni ki n sun. Mo wa sun.Ohun fun arar rẹ l mu mi takaaka to si tọ ororo si oju ara mi''
Abalọ ababọ alaye arabinrin yi fi han pe Filani fi ipa baa lo pọ to si ni ki oun ma ṣe sọ fun ẹnikankan.
BBC Yoruba gbiyanju lati ba Gbenga Filani sọrọ lori ago rẹ ṣugbọn ko gbe ago rẹ.













