Farmer/Herders Clash: Àwọn afurasí apààyàn pa Musa Monsuru 'Atiku' ní Igboora

Oríṣun àwòrán, AFP
Àwọn afurasí ọ́daran kan ti ṣekúpa ọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Musa Monsuru tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ mọ̀ sí Atiku ni ilu Igboora.
Gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ tí ẹnìkan tí kò fẹ́ kí a dárúkọ rẹ tó jẹ́ ara ìlú náà ṣe sọ fún BBC News Yorùbá, ó ní nínú oko eso kaṣú Atiku ni àwọn afurasí náà pa á sí.
Bo tilẹ jẹ pe awọn olugbe ibẹ ti wọn ni awọn n hu gbọ fi ẹsun kan pe darandaran ni awọn afurasi naa ninu awọn iroyin to n lọ kaakiri, ṣugbọn BBC ko le fidi eyi mulẹ.
Agbẹ ni arakunrin naa tó jẹ́ ọmọ ìlú Araromi, ní Igboora, ìjọba ìbílẹ̀ Ibarapa ní ìpínlẹ̀ Oyo.
Musa Monsuru gẹ́gẹ́ bí ẹni náà ti wí lọ sí oko láti lọ fín ogún pakopako sínú oko kaṣú rẹ̀ nítorí àwọn kòkòrò.
Ó ní nígbà tí àwọn ẹbí Atiku retí rẹ̀ títí wí pé ó yẹ kí o ti dé láti inú oko to lọ tí wọn kò ri ni wọ́n gbéra nílẹ̀ láti wa lọ sínú oko ṣùgbọ́n òkú rẹ̀ ni wọ́n nílẹ̀ nígbà tí wọ́n dé ibẹ̀.
Ó fi kun pé nígbà tí wọ́n dé inú oko, wọ́n ri pé wọ́n ti dú Atiku ni ọrùn tí wọ́n sì bá akèrègbè omi kan ní ẹ̀gbẹ́ òkú rẹ̀.
Ó sọ síwájú wí pé bí àwọn ko tilẹ̀ le sọ pàtó wí pé àwọn kan ló ṣiṣẹ́ láabi náà, àwọn nǹkan tí àwọn rí ní agbègbè òkú ọkùnrin jẹ́ kí àwọn furasí àwọn darandaran tó máa ń gba agbègbè náà kọjá àti wí pé ìgbà àkọ́kọ́ nìyí tí wọ́n yóò pá ènìyàn bí ẹran ní ìlú náà.
Ó fi kun pé àwọn ti fi ọ̀rọ̀ náà tó àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò Amotekun létí kí ìwádìí kíkún le wáyé lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.




















