Breast size: Wo àwọn nkan tó le fa ìdíwọ́ fún ìpèsè omi ọyàn

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Gẹ́gẹ́ bi àjọ eto ilera ni agbaye ṣe ma n sọ, o dara ki obinrin to ba ṣẹṣẹ bímọ, fun ọmọ naa ni omi ọyan nikan fun oṣù mẹ́fà akọkọ.
Àjọ WHO sọ pe fifun ọmọ ni ọyan jẹ ọkan lara ọna ti eeyan le gba jẹ ki ọmọ tuntun naa ni alaafia.
Ṣùgbọ́n sa, ọpọlọpọ obinrin míì ma n sọ pe o nira fun wọn làti fun ọmọ ni ọyan.
Eyi ko sẹ́yìn bi ọyan wọn ko ṣe ni omi daadaa eyi ti ọpọlọpọ Yoruba maa n ṣapejuwe pe ọyan wọn ko sẹ.
- Ọ̀nà àbáyọ mẹ́rin rèé, tó bá nira fún ọ láti fún ọmọ lọ́yàn
- Wo àwọn oúnjẹ́ tí yóò mú kí omi ọmú pọ̀ si fún ìyálọ́mọ́
- Ọmọ ìkókó yìí bẹ̀rẹ̀ ǹkan oṣù l'ọ́mọ oṣù mẹ́rin, ó tún kojú àìsàn jẹjẹrẹ ilé ọmọ
- Wo pàtàkì ayájọ́ ‘Má wọ kọ́mú’ tó kò lónìí
- Ìgbẹ́ ọmọdé ń dènà ààrun jẹjẹrẹ, àìsàn ìtọ̀ súgà
- Kí ni ìmọ̀ Sáyẹ́nsì sọ nípa àwọn ènìyàn tó ń bá ajá lòpọ̀? Ìwàdìí ìjìnlẹ̀ rèé
Eyi si ma n mu ki wọn o fun ọmọ tuntun ni ounjẹ inu agolo.
Gẹ́gẹ́ bi dokita ilera ọmọde nileewosan ikọsẹ iṣegun oyinbo LASUTH, Ọjọgbọn Chinyere Ezeaka, ṣe sọ, o ni ti obinrin ba ti wa ninu oyun fun oṣù marun-un, ni ọyan ti ma n bẹrẹ si ni omi.
Ṣe bi ọyan ṣe kere tabi tobi si n ko ipa kankan ninu ipese omi ọyan?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọjọgbọn Ezeaka sọ pe bi ọyan ṣe tobi tabi kere si ko ni ohunkohun lati ṣe pẹlu ipese omi.
"Fifa omi jade ni ipenija. Ṣùgbọ́n lati bori eyi, obinrin gbọdọ fi ẹnu ọmọ si ọyan laarin wakati akọkọ to bímọ.
" Wọn si gbọdọ máa fun ọmọ naa ni ọyan ni wakati meji si mẹta léraléra laarin ọjọ́ mẹta àkọ́kọ́.
Ọjọgbọn Ezeaka sọ pe eyi ni ọna kan gbòógì lati mu ki omi ọyan jade.
Àmọ́ o, awọn obinrin míì tun ma n ni ipenija lẹ́yìn ti wọn ba ṣe bẹẹ.
Kilo má n mu ko nira fun obìnrin lati fun ọmọ ni ọyan?

Onimọ ilera mii, Dokita Duke Onogagamue, sọ pe aarun HIV wa lara nkan to ma n fa a.
O ni wọn ma n gba àwọn obinrin kan to ba ni ailera bi HIV, ni ìmọ̀ràn pe ki wọn o má fun ọmọ ni ọyan.
Dokita Duke tun sọ pe obìnrin ti ko ba fun ọmọ rẹ ni ọyan ni wakati akọkọ, yoo ni ipenija lati fun ọmọ to ba ya.
Ọjọgbọn Ezeaka sọ pe àwọn nkankan le mu ki obìnrin ma le fun ọmọ rẹ ni ọyan ni wakati akọkọ.
Lara awọn nkan bẹẹ ni inira lasiko ìbímọ, isẹ abẹ lasiko ìbímọ, ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Jẹjẹrẹ ọyan naa le fa idiwọ fun fifun ọmọ ni ọyan.
O tun ṣalaye pe ti ori ọyan obinrin ko ba yọ sita daadaa, o le ṣe idiwọ lati fun ọmọ ni ọyan.
Ṣùgbọ́n ọna abayọ kiakia wa fun eyi, nipa fifi sirinji fa ori ọyan naa jade.
Dokita Duke fi kun pe ṣíṣe isẹ abẹ fun ọyan naa le fa idiwọ.
Àwọn nkan ti o le ṣe lati mu ki omi ọyan rẹ pọ sii:
Àwọn dokita mejeeji ti akọroyin BBC, Faith Osoko, ba sọ̀rọ̀ fẹnu kò pe o ṣe pataki ki iyalọmọ wa ni ilera ọpọlọ to peye.
Mimu ati jíjẹ awọn nkan olómi daadaa.
Bákan naa ni iyalọmọ ko gbọdọ ṣe wahala, ki ọyan rẹ le ni omi.


















