World Breastfeeding Week: Fífún ọmọ lọ̀yan kìí wá lásán, ó nílò ìdánilẹ́kọ̀ọ́

Iyalọmọ meji ti wọn n sọrọ lori fifun ọmọ lọyan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ẹ mase feti si awọn apọnpo nipa ifọmọ lọyan, gbogbo igba naa kọ lo rọrun lati fun ọmọ lọyan

Ọjọ Kinni osu Kẹjọ ọdọọdun ni ọsẹ fifun ọmọ lọyan maa n bẹrẹ, o si yẹ ka mọ pe fifun ọmọ lọyan ni ọpọ anfaani fun ọmọ ati iya.

Ajọ isọkan agbaye si ti kede pe ti gbogbo awujọ agbaye ba n fun ọmọ lọyan, eyi lee doola ẹmi to to ẹgbẹrun lọna ẹgbẹrin.

Ọpọ iyalọmọ lo maa n gbaradi lasiko ti wọn loyun lati fun ọmọ wọn lọyan, sugbọn o se ni laanu pe ọpọ wọn ni ko ni oye to nipa bo se yẹ ki wọn fun ọmọ ni ọyan, ko si mu amuyo.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

  • Fifun ọmọ lọyan le pupọ:
Arinrinoge kan n rẹrin lasiko to n fun ọmọ lọyan ati obinrin kan to joko, fẹyin ti ogiri to n wo suu lasiko to n fun ọmọ lọyan.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Fifun ọmọ lọyan: Ireti ati otitọ ohun to n sẹlẹ

Ọpọ ọmọ ni ebi maa n pa, ti yoo si maa sunkun lasiko to ba n mu ọyan, iya rẹ yoo ro pe ko fẹ gba ọyan ni laimọ pe ọyan naa ko se omi sẹnu ọmọ ọhun.

Igba tiru iyalọmọ bẹẹ ba si de ile iwosan, nitori ori ọyan rẹ to ti bẹ, ti wọn ba tẹ ọyan rẹ fun omi, ni ẹjẹ yoo maa jade dipo omi ọyan.

Iru iyalọmọ bẹẹ yoo si maa beere pe " Ki lo n sẹlẹ si mi, Se agọ ara mi fẹ kọ isẹ iyalọmọ ni? A se ọmọ mi jojolo n tiraka lati fa ọyan ni pẹlu agbara, titi ti ori ọyan fi n ta mi?"

Asiko yii si ni irufẹ iyalọmọ bayii yoo wa fi ika hanu pe ko ba san, ki oun ti mọ awọn ẹkọ kan nipa ti a se n fun ọmọ lọyan, ti yoo fi mu amuyo.

Awọn iyalọmọ yii yoo wa fi ika hanu pe ko ba dara ki awọn ti loye pe fifun ọmọ lọyan kii kan waye lasan, o ni ilana kan to yẹ ki awọn tọ, ko si dara ki awọn maa se 'eyi jẹ, eyi ko jẹ' nipa fifun ọmọ ni ọyan, bẹẹ si ni bi wọn ba se n fun ọmọ lọyan si, ni oye yii yoo ma ye wọn si, to si lee mu irora lọwọ nigba miran.

  • Eeyan yoo maa da wa lọpọ igba lasiko to ba n fun ọmọ lọyan:
Iyalọmọ kan to ti rẹ ree, to n fun ọmọ ni ooounjẹ́ inu agolo latinu igo.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Awọn ọmọ tuntun kii le ba ni sere bii agbalagba. Ti wọ̀n ko ju ki wọ̀n jẹ́un, ki wọ̀n sun tabi yagbẹ lọ.

Iyalọmọ kan ree to n salaye iru ipo to wa nigba to n fun ọmọ lọyan. Ẹ gbọ alaye rẹ.

"Nigba ti agọ ara mi mọ iyipada to de baa lasiko ti ọmọ mi bẹrẹ si ni mu ọyan, n se ni awọn omi ọyan yii maa n san si gbogbo ara mi, ti n kii si ni aaye lati sun, tabi sanra tabi wo ara mi ninu digi. Koda, n ko tun nifẹ lati maa jade lọ mọ si ibikibi nitori mo n bi ara mi leere pe ki ni awọn aladugbo yoo lero nipa mi, tabi ki ni awọn ọrẹ mi yoo sọ.

Ọpọ ibi ti mo nifẹ si lati maa lọ, ni n ko lee lọ mọ nitori ko rọrun fun mi lati maa fun ọmọ lọyan nita gbangba tabi loju awsn eeyan miran. Mo maa n ji lọganjọ oru lati fun ọmọ lọyan, ti maa si da wa pẹlu ọmọ mi nikan, ti maa si yapa kuro ni awujọ agbaye, bẹẹ ni mo n da nikan ronu nipa akoko sise iyalọmọ laisi ẹni ti maa kọju si fun iranlọwọ.

O dun mi pe n ko mọ tẹlẹ pe itọju ara mi gan se pataki, eyiun ti ko ba se pataki ju itọju ọmọ gan lọ nitori iya to ni ilera to peye, to si n sun daradara san ju iya to n ronu lọ.

Obinrin to n fun ọmọ lọyan

Oríṣun àwòrán, @UNICEF_Nigeria

  • Abamọ kii tete lọ:

Nigba ti wọn kọkọ fun ọmọ mi ni ounjẹ inu agolo, o sun fun ọpọ wakati, ti mo si n roo ninu ọkan mi pe igbakuugba ti mo ba fẹ sun, maa fun ọms naa ni ounjẹ inu agolo.

Amọ ko pẹ ti mo fi kabamọ ero mi yii, nitori ko pẹ pups ti ounjẹ inu agolo naa fi mu ki ahọn ọmọ mi funfun, to si n run eyi to mu ki n maa ro pe ounjẹ ti ko peye ni mo n fun ọmọ mi mu, dipo omi ọyan iya rẹ to ladun

Gbogbo igba ti mo ba si ranti eyi ni mo maa n da ara mi lẹbi, ti ẹbi naa kii si tete lọ, o si seese ki eyi maa se ọpọ iyalsmọ nitorei obi to ba mọ isẹ rẹ nisẹ yoo da ara rẹ lẹbi lọpọigba nitori itọju ọmọ.

Ọmọ to n mu miliki latinu igo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

  • Beere fun iranlọwọ:

Ironu nla ni eto ifọmọlọyan lee jẹ nigba miran, ti eeyan ko ba si beere fun iranlọwọ, o lee gba owo nla lọwọ ẹni.

Lọna ati ni imọ to peye nipa fifun ọmọ lọyan, o se pataki lati maa lọ fun idanilẹkọ lọdọ awọn eeyan to loye nipa rẹ.

O si dun mi pe n ko beere fun iranlọwọ, mo n da se gbogbo nkan ni pẹlu fifun ọmọ lọyan.

Ko si ọna abayọ miran yatọ si omi ọyan:

O yẹ ko ye wa pe labẹ bo ti wu ko ri, ko si ọna abayọ miran to yẹ ka mu lo lati tọju ọmọ wa ju fifun wọn ni omi ọyan lọ.

Amọ ti o ba yan lati mase fun ọmọ rẹ ni omi ọyan, ko tumọ si pe o kii se iya rere.