Ìwádìí tí bẹ̀rẹ̀ láti mọ iléeṣẹ́ tó n pèsè ọtí tó n ṣekúpa èèyàn - Ìjọba Ìpínlẹ̀ Ogun

Oríṣun àwòrán, Others
Ijọba ipinlẹ Ogun ti f'idi rẹ mulẹ wi pe lotitọ ni awọn eeyan kan mu ọti, ti ọti naa si pa gbogbo wọn, ati pe awọn ti bẹrẹ iṣẹ iwadii ni pẹrẹu lati mọ ileeṣẹ to n pese awọn ọti naa jade.
Ninu atẹjade ti Goke Gbadamọsi, to jẹ akọwe iroyin ileeṣẹ ijọba to n ri sọrọ eto ilera gbe jade lorukọ oludamọran pataki fun gomina lori ọrọ eto ilera, Dọkita Tomi Coker lo ti sọ pe awọn ko le ṣai gbojufo iṣẹlẹ naa.
Dọkita Coker jẹ ko di mimọ pe awọn mẹjọ lo ba iku ojiji pade lẹyin ti wọn mu ọti naa, ati pe awọn mọkanla lo ṣi wa ni baaku-baala titi di asiko t'oun fi n gbe atẹjade naa sita.
Nigba to n gba awọn araalu lamọran lati yago fun mimu awọn ọti ibilẹ lile, paapaa awọn eyi ti ajọ to n ṣayẹwo ounjẹ ati oogun lilo lorileede yii, National Agency for Food and Drug Administration and Control (NAFDAC), o ni ilera pipe lo yẹ ko jẹ awọn eeyan l'ogun, dipo ki wọn maa gbe nnkan ti ko ba aago ara lura.
Dọkita Coker ni ileeṣẹ eto ilera n'ipinlẹ naa ti bẹrẹ iṣẹ ofin toto lati mọ ibi ti wọn ti ṣe awọn ti to f'ẹmi awọn araalu ṣofo danu yii.
Siwaju sii lo tun f'idi rẹ mulẹ pe aaarin ọjọ kejidinlogun si ogunjọ, oṣu keje, ọdun 2023, lagbegbe ijọba ibilẹ Ariwa Ijẹbu ati Odogbolu, ipinlẹ naa.
O ni k'awọn araalu ṣọra fun minu awọn ọti, yala ẹlẹrindodo tabi
lile ti wọn ko ba mọ ibi to ti wa, ki wọn ma ba a da ẹmi ara wọn legbodo lojiji.















