A fẹ́ sin okù èèyàn 103 tó kú lásìkò Endsars, àmọ́ kò sí ẹnikẹ́ni láti Lekki Tollgate nínú wọn

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ijọba ipinlẹ Eko ti fidirẹmulẹ pe lootọ ni awọn fẹ ṣe eto isinku aṣepọ fun awọn to ku lasiko iwọde Endsars.
Ijọba sọ pe isinku naa wa fun awọn eeyan to ku lọdun 2020 lasiko iwọde naa nipinlẹ Eko.
Ṣaaju ni iroyin kan jade sori ayelujara, pẹlu iwe ti wọn fi buwọlu isinku apapọ naa, pe ijọba fẹ sin eeyan mẹtalelọgọrun (103).
Awọn eeyan kan sọ pe gbagede Lekki Toll Gate ni awọn eeyan naa ti ku lasiko ti awọn ọmọ ologun yinbọn mọ awọn oluwọde.
Ṣugbọn ninu atẹjade kan to fi sita ni ọjọ Aiku, ijọba ipinlẹ Eko sọ pe kii ṣe Lekki Toll Gate ni oku ti ijọba fẹ ẹ sin ti wa.
Ijọba sọ pe awọn ṣi n ṣe atẹnumọ rẹ pe ko si ẹnikẹni to kú ni Lekki Tollgate.
Ninu iwe ti ijọba fi fi ontẹ si isinku apapọ ọhun, lo ti jẹyọ pe miliọnu mọkanlelọgọta Naira ni wọn fẹ fi ṣe eto isinku naa.
Ṣugbọn ijọba sọ ninu atẹjade naa pe awọn oṣiṣẹ ajọ eleto ilera ayika “lo ṣa awọn oku naa lẹyin awọn rogbodiyan to waye lasiko iwọde EndSars ni awọn agbegbe bi Fagba, Ketu, Ikorodu, Orile, Ajegunle, Abule-Egba, Ikeja, Ojota, Ekoro, Ogba, Isolo ati Ajah”.
Akọwe fun ileeṣẹ eto ilera ipinlẹ Eko to fi atẹjade naa sita, Dokita Olusegun Ogboye sọ pe awọn to ku lasiko ti awọn ẹlẹwọn fọ ọgba ẹwọn Ikoyi naa wa nibẹ.
“Ko si eyikeyi ninu awọn oku naa to wa lati Lekki Tollgate, gẹgẹ bi awọn eeyan kan ṣe n sọ. Ẹ jẹ ko ye yin pe, a ko gbe oku kankan nibi iṣẹlẹ to waye ni Lekki Tollgate.”
Kilo wa ninu iwe isinku to lu jade?
Iwe isinku naa jade lẹyin bi ọdun mẹta ti iwọde EndSars waye.
O si han pe ọjọ kọkandinlogun, oṣu Keje, ọdun 2023 ni wọn fi ọwọ si iwe naa.
Iwe naa tun ṣe afihan ileeṣẹ ti yoo ṣe eto isinku naa, ati awọn owo ti wọn yoo yọ lara owo ti ijọba fẹ san fun ileeṣẹ naa.
Dokita Olusegun Ogboye ṣalaye ninu atẹjade naa pe ijọba pinnu lati sẹ isinku apapọ fun awọn eeyan naa, nitori pe awọn ẹbi wọn ko wa a gba wọn.
“Lẹyin rogbodiyan EndSars to waye, olori agbẹjọro ijọba kọwe si araalu pe ki awọn ti eeyan wọn ba ku tabi sọnu laarin ọjọ kọkandinlogun ati ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kẹwaa, ọdun 2020, lati ibi awọn wahala naa, pe ki wọn yọju si ileewosan ikọṣẹ iṣegun LASUTH, fun idanimọ.
“Ilana ti a la kalẹ ni pe awọn ẹbi to ba yọju yoo ṣe ayẹwo DNA lati gba oku wọn...ṣugbọn ko si ẹnikẹni to yọju lati sọ pe ẹbi oun ni eyikeyi ninu awọn oku naa.”
O ni awọn oku naa mu ki awọn ile igboku pamọ si kún ju bo ṣe yẹ.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Iwọde Endsars waye kaakiri orilẹ-ede Naijiria, eyi ti awọn eeyan paapaa awọn ọdọ fi kesi ijọba lati tu ẹka ọlọpaa SARS ka, ati lati fi ẹhonu tako bi awọn ọlọpaa ṣe n fi iya jẹ araalu lọna ti ko ba ofin mu.
Iwọde naa n lọ lai si wahala kankan, ko to o di pe awọn janduku ja a gba mọ awọn to n ṣe e lọwọ.
Eyi to gba ọna miran yọ lasiko ti awọn ọmọ ileeṣẹ ologun Naijiria yinbọn mọ awọn oluwọde to korajọ pọ si Lekki Tollgate, ni alẹ ogunjọ, oṣu Kẹwaa, ọdun 2020.
Ijọba ipinlẹ Eko gbe igbimọ kan kalẹ lati wadii ẹsun pe awọn ologun pa eeyan ni Lekki, amọ abọ iwadii wọn sọ pe ko si ẹnikẹni to ku nibi iṣẹlẹ naa.








