Ilé ẹ̀kọ́ OAU mú àlékún bá owó ilé ẹ̀kọ́, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ fárígá

Ilé ẹ̀kọ́ OAU

Oríṣun àwòrán, Others

Níṣe ni àwọn aláṣẹ àtàwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì Obafemi Awolowo ti Ilé Ife, ìpínlẹ̀ Osun ti ń forígbárí báyìí nítorí bí àwọn aláṣẹ ilé ẹ̀kọ́ náà ṣe mú àlékún bá owó tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ máa sàn fún sáà tuntun tí wọ́n fẹ́ bẹ̀rẹ̀.

Ilé ẹ̀kọ́ náà mú àlékún bá iye owó tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ máa ń san tó bá ṣẹ̀ṣẹ̀ wọlé fún sáà ẹ̀kọ́ di N101,200 láti N28,100, tí àwọn tó sì ń padà sẹ́nu ẹ̀kọ́ yóò san N89,200 láti N20,100 tí wọ́n ń san tẹ́lẹ̀.

Agbẹnusọ OAU, Abiodun Olarewaju nínú àtẹ̀jáde kan tó fi síta lọ́jọ́rú ṣàlàyé pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó wà ní ẹ̀ka Faculties of Arts, Law àti Humanities yóò máa san N89,200 fún àwọn tó bá ń padà sẹ́nu ẹ̀kọ́ .

Ó ní àwọn tó bá ṣẹ̀ṣẹ̀ wọlé sílé ẹ̀kọ́ náà ní ẹ̀ka yìí yóò san N151,200 ní ọdún kan.

Olarewaju ní iye owó tuntun yìí ni ìgbìmọ̀ aláṣẹ ilé ẹ̀kọ́ buwọ́lù lẹ́yìn tí wọ́n ṣe ìpàdé lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun.

Àtẹ̀jáde náà ṣàlàyé pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní ẹ̀ka ìmọ̀ ẹ̀rọ àti sáyẹ́ǹsì yóò máa san N163,200 fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó bá ṣẹ̀ṣẹ̀ wọlé, tí àwọn tó sì ń padà sẹ́nu ẹ̀kọ́ yóò máa san N101,200.

Bákan náà ni àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní ẹ̀ka College of Health Sciences àti Pharmacy yóò san N190,200 fún àwọn tó bá ṣẹ̀ṣẹ̀ wọlé tí àwọn tó ń padà sẹ́nu ẹ̀kọ́ yóò sì san N128,200.

Wọ́n ní gbogbo owó ló jẹ́ ti ọdún kan péré.

Àwa ò lè san iye tÍ àwọn aláṣẹ wa sọ yìí - SUG

Ẹ̀wẹ̀, ẹgbẹ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ iké ẹ̀kọ́ ọ̀hún ti bu ẹnu àtẹ́ lu ìgbésẹ̀ àwọn aláṣẹ wọn láti mú àlékún bá owọ ilé ẹ̀kọ́.

Àtẹ̀jáde kan tí ẹgbẹ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilé ẹ̀kọ́ náà fi síta ní àwọn kò gba iye tí àwọn aláṣẹ náà ni àwọn yóò san nítorí wọn kò fi tó àwọn létí kí wọ́n tó mú àlékún bá owó náà.

Ààrẹ àti akọ̀wé SUG OAU, Abbas Ojo àti Akinboni Opeyemi nínú àtẹ̀jáde náà ní àwọn kò ní gba nǹkan tí àwọn aláṣẹ náà ṣe wọlé nítorí ìjọba àpapọ̀ ti sọ wí pé àwọn kò lọ́wọ́ nínú bí àwọn ilé ẹ̀kọ́ ṣe ń mú àlékún bá owó ilé ẹ̀kọ́.

Wọ́n ní gbogbo ìgbésẹ̀ ni àwọn máa gbé láti ri dájú pé àwọn aláṣẹ náà yí ìpinnu wọn padà àti pé kí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ṣe pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ tí àwọn máa fi rí ọ̀rọ̀ náà yanjú.

Bí epó ṣe gbówó lórí, ìjọba àpapọ̀ fi owó kún ile ẹ̀kọ́ gírámà rẹ̀, UNILAG gbé owó lé owó ẹ̀kọ́ pẹ̀lú ìdá irínwó

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Ẹ o ranti pe Ijọba apapọ ti kede pe awọn ti fowokun owo ile ẹkọ girama, Federal Government Collage, ti ọpọ tun mọ si Federal Unity Collage lati ẹgbẹrun marindinlaadọta si ẹgbẹrun lọna ọgọrun un naira.

Eyi lo wa ninu atẹjade ti ọfisi ọga agba fun ẹka ile ẹkọ girama to wa labẹ ẹka ijọba apapọ to n ri si eto ẹkọ gbe jade pẹlu nọmba idanimọ ADF/120/DSSE/I, to jade ni ọjọ kẹdọgbọn oṣu karun un, to si n dari gbogbo awọn oludari ile ẹkọ labẹ ijọba apapọ lati tẹle asẹ naa.

Gẹgẹ bi atẹjade naa se sọ, o ni "Afikun owo fun ile ẹkọ Federal Unity College fun saa akọkọ fun awọn akẹkọọ tuntun ti Ọga agba fun ẹka awọn ile ẹkọ Girima lorilẹede Naijira, Haija Binta AbdulKadir, buwọlu ni pe awọn akẹkọọ tuntun yoo san ẹgbẹrun lọna ọgọrun un naira yatọ si ẹgbẹrun marindinlaadọta ti wọn n san tẹlẹ.

"Afikun yii ni yoo bẹrẹ ni gbogbo awọn ẹka wa ati awọn nnkaqn ti a n pese fun awọn akẹkọọ bi owo ile ẹkọ, owo ile gbe akẹkọọ, asọ, iwe, kaadi idanimọ, ere idaraya ati awọn nnkan miiran."

UNILAG gbe owo le ẹkọ pẹlu ida irinwo

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Fasiti ipinlẹ Eko, ti kede laipẹ yii pe awọn ti fowo kun owo ile ẹkọ fun awọn akẹkọọ pẹlu ada irinwo

Ọga agba fun fasiti naa, Ọjọgbọn Folasade Ogunsola lo kede igbesẹ naa lasiko to n se ipade pọ pẹlu awọn aṣoju awọn osisẹ ti ko ki n se olukọ lọjọbọ, Ogunjọ, oṣu keje, ọdun 2023 ni gbọngan fasiti naa

Gẹgẹ bi Ọjọgbọn Ogunsola se sọ, o ni afikun owo ẹkọ yii yoo wa soke si l;ati ẹgbẹrun lọna ogun si ẹgbẹ lọna ọgọrun naira, to si tun da le lori ẹkọ ti akẹkọọ ba fẹ ka.

"Awọn akẹkọọ ti wọn ko nilo yara ayẹwo yoo san N100,750, ti awọn to nilo yara ayẹwo fun ẹkọ wọn yoo san N140,250

"Awọn akẹkọọ to fẹ ka nipa eto iṣegun yoo san N190, 250

Igbesẹ yii yoo nira fun awọn akẹkọọ ati idile wọn

Ẹgbẹ awọn osisẹ agba ẹka fasiti ipinlẹ Eko (SSANU) ti fi atẹjade sita lẹyin ipade na, ti wọn kọminu lori igbesẹ fasiti naa lati gbe owo le owo ẹkọ yoo wuwo lori ọpọlọpọ awọn akẹkọ ati idile wọn.

Asọju SSANU, Comrade Rasaki Yusuf wa rọ fasiti naa lati tun igbesẹ naa wo paapa fun awọn osisẹ ti wọn n gbe ni fasiti naa.

Ko pin dandan ki akẹkọọ san owo ẹkọ ni ẹkanna.

Ọgba fasiti UNILAG, ni awọn ti pese aye fun awọn akẹkọọ lati san owo ẹkọ ni diẹdiẹ, ti awọn ko si yii ipinnu awọn pada ni awọn akẹkọọ kan tabi miiran.

"Akẹkọọ le san awọn owo wọnyi ni diẹdiẹ sugbọn o gbọdọ san tan ni o ku oṣu kan ti idanwo yoo waye.