Davido pín ₦237m fáwọn ọmọ aláìníìyá yíká Nàìjíríà

Davido

Oríṣun àwòrán, INSTAGRAM

Gbajúgbajà olórin tàkasúfèé nnì, David Adeleke tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Davido ti pín #237 million sí àwọn ilé ọmọ aláìní ìyá 424 káàkiri orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.

Davido sọ èyí nínú àtẹ̀jáde kan tó fi léde lórí bí owó náà ṣe jẹ́ pínpín sí àwọn ilé ọmọ aláìní ìyá náà ní ìpínlẹ̀ kọ̀ọ̀kan.

Nínú oṣù Kọkànlá ọdún 2021 ni nǹkan náà bẹ̀rẹ̀ bí eré nígbà tí Davido sọ fún àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ láti dá mílíọ̀nù kan náírà jọ fún òun láti fi gba ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ Rolls Royce tí òun ṣẹ̀ṣẹ̀ rà.

Àmọ́ ọ̀rọ̀ náà kúrò ní kékeré nígbà tí àwọn ènìyàn dá igba mílíọ̀nù náírà fún Davido láàárín ọjọ́ mẹ́ta.

Inú mi máa ń dùn láti pín ẹ̀bùn yíká ilé ọmọ aláìní ìyá, ó bẹ̀rẹ̀ lásìkò ọjọ́ ìbí mi lọ́dún díẹ̀ sẹ́yìn"

Èyí ló mú Davido pinnu láti pín owó náà fún àwọn ọmọ aláìní ìyá káàkiri orílẹ̀ èdè Nàìjíríà dípò kí òun fi gba ọkọ̀ náà.

Lẹ́yìn náà ló gbé ìgbìmọ̀ ẹlẹ́ni márùn-ún kan dìde èyí tí Titi Adebayo jẹ́ alága rẹ̀ láti pín owó náà.

Davido nínú àtẹ̀jáde tó fi sórí Twitter rẹ̀ ní inú òun dùn láti pín igba mílíọ̀nù náírà káàkiri ilé àwọn ọmọ aláìní ìyá, nǹkan tó bẹ̀rẹ̀ lásìkò ìgbà ọjọ́ ìbí òun ní ọdún díẹ̀ sẹ́yìn.

Ó ní nǹkan tí ó ti máa ń wú òun láti ṣe ni tí òun sì dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn ènìyàn tó jẹ́ kí ó wá sí ìmúṣẹ.

Bákan náà ló dúpẹ́ lọ́wọ́ gbogbo àwọn tó dá sí owó náà àti pé ìrànlọ́wọ́ wọn ń mú àyípadà bá ìgbé ayé àwọn ènìyàn kan.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

Ta ni Davido?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Davido jẹ́ gbajúmọ̀ olórin tàkasúfèé tó jẹ́ ààyò ọ̀pọ̀ ọmọ Nàìjíríà.

David Adedeji Adeleke ni orúkọ rẹ̀ gan àmọ́ Davido ni ìnagijẹ tí ọ̀pọ̀ ènìyàn mọ̀-ọ́n sí.

Ní ọjọ́ Kọkànlélógún oṣù Kọkànlá ọdún 2021 ni wọ́n bí Davido tó sì ti pé ọmọ ọgbọ̀n ọdún báyìí.

Inú ẹbí Adeleke ti ìpínlẹ̀ Osun, orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ni wọ́n bí Davido sí tó sì lọ sí ilé ẹ̀kọ́ British International School, Eko.

Nígbà tó pé ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún ló padà sí orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà tí wọ́n bí i sí láti lọ sí ilé ẹ̀kọ́ gíga Oakwood University, Alabama níbi tó ti kẹ́kọ̀ọ́ Business Administration.

Davido kò parí ní ilé ẹ̀kọ́ náà tó fi gba London lọ láti lọ ṣiṣẹ́ lórí ohùn rẹ̀ nítorí ìfẹ́ tó ní sí orin kíkọ.

Lẹ́yìn tó padà sí Nàìjíríà ló tún lọ sí ilé ẹ̀kọ́ gíga Babcock University níbi tó ti kẹ́kọ̀ọ́ nípa orin kíkọ tó sì parí lọ́dún 2015.

Ní ọdún 2011 ló kọ́kọ́ gbé àwo orin tó pè ní Ọmọ Baba Olówó jáde.

Lẹ́yìn náà ló kọ àwọn orin bíi Skelewu, Gobe, Tchelete, Ayé àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ èyí tí ọ̀pọ̀ fẹ́ràn.

Davido ti gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ àmì ẹ̀yẹ to fi mọ́ àmì ẹ̀yẹ Headies.