Baba Wande, Iyabo Ojo àtàwọn gbajúmọ̀ míì kérora jálá epo tó di ₦617

Oríṣun àwòrán, Iyabo Ojo/Bola Tinubu/Baba Wande
Agba oṣere tiata Yoruba, Kareem Adepoju, ti ọpọ mọ si Baba Wande ti ke si Aarẹ Bola Tinubu lati wa ojutu si bi owo epo ṣe gbowo lori, eyi to n mu inira ba ọpọ ọmọ Naijiria.
Yatọ si Baba Wande, Iyabo Ojo naa tun fi ohun ranṣẹ si Tinubu lori ọrọ naa.
Awọn ọrọ wọnyi lo n jade lẹyin ti bẹntiro dede fo lati ₦500 si ₦617.
Iya n jẹ mẹkunu – Baba Wande
Nigba to n rawọ ẹbẹ si Aarẹ Tinubu, Baba Wande sọ pe idunnu oun ati ọpọ ọmọ Yoruba lo jẹ pe Tinubu gori oye, amọ ara n ni awọn eeyan.
Baba Wande sọ pe ọpọ awọn to ni mọto ni ko le gbe ọkọ wọn jade mọ, nigba ti ọpọ awọn talaka n sun ninu ebi latari ọwọngogo ounjẹ.
O ni “Baba wa Bola Ahmed Tinubu, ẹ jọwọ, ẹ ba wa tun oke ṣe o, iya n jẹ mẹkunnu.”
“Ọrọ epo yii wahala ni o, ọpọ eeyan ni ko le gun ọkọ mọ, ti wọn gbe ọkọ kalẹ silẹ.”
“Nnkan ko ṣee ra lọja nitori epo gbowo lori, ounjẹ ko ṣee ra lọja mọ nitori o gbowo lori, ẹ ba wa ṣi ọna ki wọn le ko ounjẹ wọle.”
Gbogbo nnkan lo gbowo lori – Iyabo Ojo
Ninu atẹjade kan loju opo Instagram rẹ ni Iyabo Ojo ti sọ pe ọwọngogo epo, ounjẹ atawọn nnkan mii.
Iyabo sọ pe “Gbogbo nnkan lo ti wọn bayii, nigba ti awọn to n ri owo diẹ n kerora, ki ni ki awọn talaka ṣe?”

Oríṣun àwòrán, Iyabo Ojo
“Dollar ti di ₦833, Pọun ti di ₦1,045 nigba ti epo bẹntito jẹ ₦617....”
Yatọ si awọn oṣere meji yii, awọn oṣere mii bi Bukunmi Oluwasina naa sọ pe o to gẹ.
Ti ẹ ko ba gbagbe, Iyabo Ojo wa lara awọn gbajumọ to tako iyansipo Bola Tinubu gẹgẹ bii Aarẹ, eyii to mu ko di ọta ọpọ awọn ololufẹ Tinubu.
Amọ lara awọn oṣere to ṣe atilẹyin ojukaye fun Tinubu ni Toyin Abrahama, Olaiya Igwe, Jide Kosoko, Said Balogun, Damola Olatunji, ati bẹẹ bẹẹ lọ.












