Adebutu takú pé ẹbu ìwé ẹ̀rí WAEC ni Abiodun ń lò, WAEC kọ̀ láti fi ẹ̀dà ìwé ẹ̀rí ránṣẹ́ sí ‘Tribunal’ l‘Ogun

Oríṣun àwòrán, COLLAGE
Ìgbìmọ̀ tó ń gbọ́ ẹ̀hónú ìbò gómìnà ìpínlẹ̀ Ogun ń tẹ̀síwájú láti gbọ́ awuyewuye tó wáyé nínú ìbò gómìnà Dapo Abiodun wọlé gẹ́gẹ́ bí gómìnà.
Ní ọjọ́bọ̀ ni òṣìṣẹ́ West African Examination Council (WAEC), Olufemi Olaleye yọjú sí ilé ẹjọ́ gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí Abiodun àmọ́ kò mú èsì ìdánwò WAEC gómìnà náà dání.
Ṣáájú ni ìgbìmọ̀ tó ń gbọ́ ẹ̀hónú ìbò náà ti kàn sí WAEC láti pèsè ẹ̀dà èsì ìdánwò èyí tí gómìnà Abiodun ṣe ní ọdún 1978.
Èsì ìdánwò yìí ni gómìnà Abiodun fà kalẹ̀ fún àjò INEC pé òun yege nínú ìdánwò òun.
Ìgbìmọ̀ tó ń gbọ́ ẹ̀hónú ìbò náà kàn sí àjọ WAEC láti pèsè ẹ̀dá ìwé ẹ̀rí mo yege gómìnà Abiodun lẹ́yìn tí olùdíje sípò gómìnà Ìpínlẹ̀ náà lẹ́gbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party, PDP, Ladi Adebutu fẹ̀sùn kan Abiodun pé ayédèrú ni ìwé ẹ̀rí èsì ìdánwò WAEC tó ń lò.
Adebutu ní òun ti kọ̀wé ránṣẹ́ sí WAEC láti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ayédèrú ni èsì ìdánwò tí gómìnà Abiodun ń lò
Adebutu ní ayédèrú èsì ìdánwò WAEC ní Abiodun fi kalẹ̀ fún WAEC ní ọjọ́ Kẹẹ̀dọ́gbọ̀n oṣù Keje ọdún 2022.
Ó ní òun ti kọ̀wé ránṣẹ́ sí WAEC láti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ayédèrú ni èsì ìdánwò tí gómìnà Abiodun ń lò.
Ẹ̀wẹ̀, Olaleye sọ fún ilé ẹjọ́ wí pé òun kò mú èsì ìdánwò náà dání wá sílé ẹjọ́ nítorí WAEC kìí fi ẹ̀dà èsì ìdánwò tí wọ́n bá ti gbà sọ́wọ́.
Ó ní tí wọ́n bá fẹ́ fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé èsì ìdánwò kan jẹ́ ayédèrú, ó ní wọn yóò fi èsì náà ṣọwọ́ sí WAEC fún àyẹ̀wò.
Ó ṣàlàyé pé ìgbà yìí ni àwọn yóò lè sọ wí pé èsì ìdánwò tí wọ́n fi ránṣẹ́ sí àwọn jẹ́ ojúlówó tàbí ayédèrú.















