Wo ọ̀nà mẹ́sàn-án tí ìjọba ìpínlẹ̀ àti àpapọ̀ yóò fi mú àdínkù bá ìyà aráàlú torí ọ̀wọ́n owó epo

Owo ati eroja onihoro

Igbimọ to n risi ifẹsẹmusẹ ọrọ aje ni Naijiria se ipade kan lọjọbọ lati wa ojutu si iya to n jẹ araalu tori ele to gun ori lita epo pẹtrol.

Bẹẹ ba gbagbe, ọjọ Isẹgun, ọjọ kejidinlogun osu Keje ọdun 2023, ni ọ̀gá àgbà àjọ elépo rọ̀bì ní Nàìjíríà, NNPCL, Mallam Mele Kyari kede pe lita epo pẹtrolu kan ti fo fẹrẹ si ẹgbẹta ati abọ naira.

Ariwo sọ lori ikede yii, ti gbogbo owo ounjẹ, owo ọkọ ati awọn ohun eelo si gbowo lori gege, eyi to mu kawọn araalu maa pariwo pe igbe aye ko dẹrun fun awọn rara.

Idi si ree ti igbimọ eleto ọrọ aje fi se ipade ni Ọjọbọ lati wa ọna ti aye yoo fi dẹrun fawọn ọmọ Naijiria.

Igbakeji aarẹ, Kashim Shettima lo dari ipade naa, ti awọn gomina gbogbo ipinlẹ mẹrindinlogoji to wa ni Naijiria si wa nibẹ.

Bakan naa ni awọn tọrọ kan lati Banki Agbaye atawọn ajọ to jẹ ti ijọba ni Naijiria ko gbẹyin nibi ipada naa.

Igbesẹ meje ti ijọba ipinlẹ ati apapọ fẹ gbe lati mu aye dẹrun fun araalu tori ọwọn owo epo pẹtiro

  • Ijọba apapọ yoo bẹrẹ si pin awọn ohun jijẹ onihoro fawọn araalu bẹrẹ lati ọjọ Aje lọ
  • Ijọba apapọ yoo tun pin ajilẹ fawọn araalu lati ipasẹ banki apapọ ilẹ wa , ki wọn le fi sisẹ ọgbin, ki ounjẹ le sun wa bọ lowo pọọku
  • Ijọba apapọ yoo fọn awọn ọkọ bọọsi bọgini ti yoo maa lo gaasi sigboro lati mu ẹdinwo ba owo ọkọ ero loju popo
  • Ijọba apapọ yoo mu ele ba owo osu awọn osisẹ apapọ laipẹ lẹyin ijiroro lori ọrọ ohun to yẹ ko jẹ dede owo oṣu oṣiṣẹ to kere julọ
  • Ijọba apapọ pasẹ fun ipinlẹ kọọkan lati ṣe eto pinpin owo fawọn mẹkunnu eyi ti yoo waye nipa lilo akọsilẹ ijọba ipinlẹ, ti yoo si da lori bi onikaluku ipinlẹ ṣe jẹ ọtọọtọ
  • Ijọba ipinlẹ yoo tun maa pin ẹbun owo fun awọn oṣiṣẹ ijọba fun oṣu mẹfa.
  • Awọn ijọba ibilẹ gbọdọ ri daju pe wọn san gbogbo gbese owo oṣu awọn oṣiṣẹ ti wọn n jẹ lowo
  • Ijọba yoo tun bẹrẹ si ni ro awọn olokoowo kekeke lagbara pẹlu ele ti ko papọju
  • Ijọba tun seleri pe eto yoo bẹrẹ lọgan lọna ati ṣe ayipada si ipese ina ọba.
Àkọlé fídíò, “Tí FUNAB kò bá fàyè gbà wá láti lo Niqob, a ó lọ sí UI tàbí LASU”

Kí ni àbájáde ìpàdé ìgbìmọ̀ aláṣẹ lórí ètò ìrànwọ́ “Palliative” fáwọn ọmọ Nàìjíríà?

Tita epo bẹntiroo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Lẹyin ti ijọba aarẹ Bola Tinubu ti yọ owo iranwọ ori epo bẹntiroo ti oloyinbo n pe ni Subsidy kuro, ti ọwọngogo si ti gori owo epo to bẹẹ to ti to N617 fun lita epo kan ni igboro ti dojuru ni Naijiria.

Ẹwẹ igbimọ alaṣe orilẹede Naijiria sare ṣe ipade pajawiri kan lonii Ogunjọ oṣu Keje nipa ọna ti iranlọwọ le fi wa fun awọn ọmọ Naijiria.

Ni Ọjọbọ ni wọn ṣe ipade naa ni ọkan ninu awọn gbọngan to wa ninu ile aarẹ ni Abuja.

Igbakeji aarẹ Kashim Shettima lo dari ipade naa ti awọn gomina gbogbo ipinlẹ mẹrindinlogoji to wa ni Naijiria si wa nibẹ to fi mọ awọn tọrọ kan lati Banki Agbaye atawọn ajọ to jẹ ti ijọba ni Naijiria.

Bakan naa ni igbimọ alaṣẹ Naijiria tun bojuwo ọna ti wọn fẹ gba jẹ ki iranlọwọ latọdọ ijọba kan awọn araalu lara.

Ki ni ipade naa wa bi ti yoo ran awọn ọmọ Naijiria lọwọ?

Lasiko ti ipade naa n lọ lọwọ, wọn rọ awọn oṣiṣẹ ijọba lati mu adinku ba iye owo ti wọn n na fun iṣejọba nibikibi ti wọn ba ti n ṣiṣẹ. Eyi n waye bi wọn ṣe ni ijọba apapọ fẹ ṣe eto owo iranwọ oloṣu mẹfa fun awọn oṣiṣẹ ijọba.

Ṣaaju ni aarẹ Bola Ahmed Tinubu ti pinu pe ijọba oun yoo pese owo iranwọ ẹgbẹrun mẹjọ naira fun ọmọ Naijiria ẹgbẹrun mejila to wa lati idile to talaka julọ jakejado orilẹeede Naijria to si ni oun yoo ṣe eyi fun oṣu mẹfa lati mu idẹra ba awọn eeyan latari owo ori iranwọ epo ti wọn yọ kuro.

Amọ ọjọ diẹ lẹyin ti ikede yii jade ni ijọba apapọ tun yaa sare ni awọn yoo ṣe atunyẹwo igbesẹ naa tori oko ọrọ ti awọn ọmọ Naijiria fi fesi si ọrọ ẹgbẹrun mẹjọ naira akọkọ ọhun ko kere rara.