"Ìjọba yìí kàn ń fara ni wá ni, mo sì ṣe wàhálà lórí rẹ̀, ìnira yìí pọ̀ jù"
Awọn ọmọ Naijiria ti n figbe bọnu pe ori n ta awọn pupọ tori ele to gun owo lita epo pẹtiroolu kan.
Bẹẹ ba gbagbe, lọjọ Isẹgun, ọjọ kejidinlogun osu Keje ọdun 2023 ni ileesẹ elepo rọbi ni Naijiria, NNPCL kede pe ele ti gun owo lita epo ptirool kan.
Owo lita epo pẹtiroolu lo fo fẹrẹ lati ọgọsan Naira si ẹẹdẹgbẹta naira o le diẹ lọjọ kọkandinlọgbọn osu karun ọdun 2023.
Igbesẹ naa lo waye lẹyin ti aarẹ Bola Tinubu kede lọjọ ibura rẹ pe ko si owo iranwọ lori epo pẹtiroolu mọ.
Ariwo sọ lori ikede yii, ti gbogbo owo ounjẹ, owo ọkọ ati awọn ohun eelo si gbowo lori gege, eyi to mu kawọn araalu maa pariwo pe igbe aye ko dẹrun fun awọn rara.

Bakan naa, ijọba Bola Tinubu tun yọwọ iranwọ kuro lori pasi-paarọ owo Naira ilẹ wa si tilẹ tilẹ okeere eyi to mu ki Naira di yẹpẹrẹ lọja agbaye.
Amọ lẹyin osu kan abọ, ni ajọ elepo rọbi tun kede pe ele miran tun ti gun owo lita epo pẹtiroolu naa.
Alaye ti ọga agba ajọ NNPCL, Mele Kyari, se lori isẹlẹ naa ni pe owo ilẹ wa to n saisan lọja pasi-paarọ Naira si tawọn owo ilẹ okeere lo se akoba fun owo epo.
Ni ọjọ Isẹgun, ọjọ Kejidinlogun osu Keje ọdun 2023 ni Kyari kede bẹẹ ti lita epo pẹtiroolu si fo lati ẹẹdẹgbẹta Naira o le diẹ si ẹgbẹta naira ati aabọ.
Ikede yii si lo mu ki awọn ọmọ Naijiria tun maa fi apa janu pe ara n ni awọn, ti igbe aye si le koko fun awọn.
"Ara n ni wa gan, a joko, a n ronu ni, ki ijọba yara tete se daadaa to ba fẹ se ni"
Eyi lo mu ki BBC Yoruba bọ sigboro lati lati fi ọrọ bawọn araalu lẹnu wo lori ero wn nipa ele to gun lita epo naa.
Lasiko ti wọn n ba wa sọrọ, ọpọ wọn lo mu igbe bọnu pe ebi n pa awọn, aye le koko fun awọn, ti ara si n ni awọn lọpọlọpọ.
"Ara n ni wa gan, a joko, a n ronu ni, ki ijọba yara tete se daadaa to ba fẹ se ni.
Ijọba yii kan n fi ara ni wa ni, a dẹ se wahala lori ijọba yii pupọ, ijiya yii ti pọ ju."
Bi awọn ọlọkọ si se n kabamọ pe awọn ero ko wa wọ ọkọ lati igba ti ele ti gun owo lita epo kan, naa ni awọn ero ọkọ ni owo ọkọ ti wn ju, o kọja agbara awọn.
Gbogbo wọn wa n rawọ ẹbẹ si ijọba pe ko tete wa ojutu si ọrọ naa, ki ọrọ naa to bọwọ sori.






