Wo adúláwọ̀ tí yóò fakọyọ ní ìdíje ìfe ẹ̀yẹ àgbáyé fáwọn obìnrin

Aworan

Idije Ife Ẹyẹ Agbaye fun awọn obinrin ti ọdun 2023 yoo bẹrẹ ni Ogunjọ, Osu Keje, ọdun 2023.

Ikọ agbabọọlu Australia ati New Zealand in yoo ba side idije naa nitori awọn ni wọn n gbalejo awọn oludije.

Ni saa yii, ilẹ Afrika yoo ni awọn ikọ agbabọọlu orilẹede mẹrin lati ṣoju fun wọn ni asiko idije naa.

Eyi ko ṣẹyin bi ajọ bọọlu lagbaye, Fifa se se afikun iye awọn ikọ ti yoo maa kopa ninuidije ife ẹyẹ agbaye lati ikọ mẹrinlelogun si ikọ mejilelọgbọn.

Orilẹede South Africa tgo gbade ni idije AFCON fun awọn obinrin pẹlu orilẹede Naijiria lo ṣaaju.

Nigbati ikọ agbabọọlu Morocco ati Zambia ti wọn ṣẹṣẹ n kopa fun igba akọkọ naa ko gbẹyyin bibẹ.

Bio tilẹ jẹpẹ awọn ikọ agbabọọlu Afrika ko kọja ipele kẹta to kangun si aṣekagbari, ogunjọ, Osu Kẹjọ, ni idije naa yoo pari.

Saaju idije naa ni BBC se akojọpọ awọn agbabọọlu obinrin mẹrin ti o seese ki wọn fakọyọ ninu idije naa.

Aworan

Asisat Oshoala – Naijiria

Ko si obinrin to n gba bọọlu ni ilẹ Adulawọ to lamilaaka to Asisat Oshoala – idi si niyii.

Lati ọdun 2014 to ti bọ si gbagede bọọlu ni agbaye ni o ti n se gudugudu meje yaya , mẹfa. To si wa ninu ọkan gboogi ninu awọn agbabọọlu to wu ni lori ni ilẹ Afrika.

Ẹẹmẹta ni Oshoala ti gba ife ẹyẹ Wafcon, to si gba bọọlu wọnu awọn ni ọdun 2015 ati ọdun 2019 lasiko Ife ẹyẹ agbaye awọn obinrin.

Ti o ba gba bọọlu wọnu awọn ni saa yii, yoo jẹ ọmọ ilẹ alawọ dudu akọkọ ti yoo gba bọọlu wọnu awọn ni Ifẹ ẹyẹ agbaye lẹẹmẹta, ti o si ṣeeṣe ko gba Ami ẹyẹ obinrin agbabọọlu to lamilaaka julọ.

Bio tilẹ jẹpe orunkun to fi ṣeṣe ni ọdun to kọja ko jẹ ko kopa ninu Wafcon, ti ko si tun kopa ninu idije May’s Champions League nitori apa rẹ to fi sẹse, ti Barca to n gba bọọlu fun si fi idi Wolfsburg janlẹ.

Ireti awọn ọmọ Naijiria ni pe yoo wa ni alaafia lẹkunrẹrẹ lasiko idije naa.

Aworan

Barbra Banda- Zambia

Bio tilẹ jẹpe oun naa ko kopa ninu idije Wafcon ti ọdun to kọja, arabinrin Banda to jẹ ẹni ọdun mẹ̀talelogun naa jẹ agbabọọlu to lamilaaka.

Ọdun 2021 ni arabinrin naa jọ awọn eniyan loju ni agbaye pẹlu bi o ṣe gba bọlu wọnu awọn ni idije Olympics- ki o to dipe wọn ja kuro ninu idije naa.

Amọ igbiyanju Banda ni o ni ifaṣẹyin ni ọdun to kọja nigba ti wọn gbegile ikopa rẹ ninu idije Wafcon lori ẹsun to niiṣẹ iṣẹda rẹ gẹgẹ bi obinrin, eleri ti wọn pe ni ‘’gender eligibity row.’’

Amọ Banda to jẹ balogun ikọ rẹ lo duro ni Morocco lati ṣe moriya fun ikọ rẹ ti wọn pari ni ipo kẹta si iyalẹnu gbogbo agbaye.

Bio tilẹ jẹpe igba akọkọ niyii ti Zambia yoo kopa ninu idije ife ẹyẹ agbaye, ikọpa rẹ pẹlu arabinrin Racheal Kundananji yoo mu nkan to dara ṣẹlẹ fun Zambia.

Aworan

Refiloe Jane -South Africa

Jane lo dabi ẹni pe ko si ẹni to mọ ni o ṣe koko si ikọ agbabọọlu South-Africa nitori bi o sẹ lamilaaka.

Jane ni wọn sapejuwe pe o duro ire ninu ikọ rẹ ti kii se jẹ ki bọọlu kọja rẹ lọ si awọn.

O duro dede ni ipo adele to n sọ bọọlu, to si mọ bọọlu gba daradara lati ibẹrẹ de opin.

Ọdun 2012 ni o bẹrẹ si ni kopa ninu ereboolu bẹrẹ lati olympics, lati igba naa lo si ti n gba bọọlu fun South-Afrca lati igba naa.

Ni ọdun to kọja lo bẹrẹ si ni ṣiṣẹ igbakeji balogun ikọ naa pẹlu Janine van Wyk-, ti wọn si gbe ifẹ ẹyẹ naa wale.

Ni saa yii, o seese ko jẹ oun nikan ni yoo tukọ ikọ agbabọọlu South-Africa naa nitori Van Wyk ti farapa.

Bio tilẹ jẹpe o le maa gba bọọlu wọnu awọn lọpọ abi ki awọn iwe iroyin gbe orukọ rẹ, amọ yoo jẹ ọkan gboogi lati goke fun ẹgbẹ agbabọọlu South Africa.

Aworan

Ghizlane Chebbak- Morocco

Bio tilẹ jẹpe South-Africa and Naijiria ni aruwo wọn gbode kan ni idije Wafcon to waye ni ọdun to kọja, ikọ Morocco ya agbaye lẹnu pẹlu bi wọn de ipele to kẹyin ninu idije naa.

Ọkan gboogi ninu awọn ikọ Morocco to fakọyọ ni Ghixlane Chebbak.

Chebback to jẹ ọmọbinrin agbabọọlu ọkunrin Larbi Chebbak, to gba ifẹ ẹyẹ ilẹ Afrika ni ọdun 1976.

Arabinrin Ghizlane Chebbak naa lo tukọ ẹgbẹbọọlu Morocco obinrin naa fun igba akọkọ lẹyin ogun ọdun ti idije naa ti bẹrẹ.

Eyi si mu ki wọn pegede fun idije ife ẹyẹ agbaye fun igba akọkọ.

Bio tilẹ jẹpe aarin gbungun lo n gba bọọlu fun, ko si ẹni to tii gba bọọlu wọnu awọn to Chebback to si pegede gẹgẹ bi adari.