Guinness World records fún C. Ronaldo ní àmì ẹ̀yẹ agbábọ́ọ̀lù tó gbá bọ́ọ̀lù jùlọ fún orílẹ̀èdè rẹ̀

Oríṣun àwòrán, instagram/portugal
Balogun ikọ agbabọọlu orilẹede Portugal, Cristiano Ronaldo gba goolu kan ṣoṣo to mu Portugal jawe olubori lalẹ ọjọ Iṣẹgun, to si tun di agbabọọlu akọkọ lagbaye ti yoo gba ifẹsẹwọnsẹ igba fun ik agbabọọlu orilẹede kan.
Goolu ti Ronaldo gba wọle ni igba ti ifẹsẹwọnsẹ wọn pẹlu Iceland wọ iṣẹju kọkandinlaadọrun ninu ifẹsẹwọnsẹ lati mọ awọn orilẹede ti yoo kopa ni idije ife ẹyẹ Euro 2024.
Goolu naa ni ikẹtalelọgọfa ti Ronaldo yoo gba wọle fun orilẹede rẹ, eyi to si tun jẹ goolu to pẹ julọ ti agbabọọlu kankan lagbaye yoo gba sinu awọn fun ik agbabọọlu orilẹede rẹ.
Ni oṣu kẹta ọdun 2023 ni Ronaldo gba ipo naa lọwọ Bader Al-Mutawa agbabọọlu orilẹede Kuwait to ti gba ifẹsẹwọnsẹ aadọwa le mẹfa (196) funorilẹede rẹ.
Ajọ to n ṣe koriya fun awọn ohun manigbagbe lagbaye, Guiness World Records, GWR gbe patako ami ẹyẹ rẹ lọwọ awọn aṣoju ileeṣẹ GWR ki ifẹsẹwọnsẹ naa to bẹrẹ.
Ọdun 2023 ni yoo pe ogun ọdun ti C. Ronaldo, gẹgẹ bi ọpọ awọn ololufẹ rẹ ṣe maa n pe e, ti n gba bọọlu fun Portugal.

Ronaldo ti gba bọọlu jẹun lawọn ẹgbẹ agbabọọlu bii Sporting Lisbon, Manchester United, Real Madrid ati Juventus ki o to gba ilu Saudi Arabia lọ nibi to ti n gba bọọlu jẹun ni ẹgbẹ agbabọọlu Al-Nassr.
Igba marun un ọtọtọ lo ti gba ami ẹyẹ agbabọọlu to lamilaaka julọ lagbaye, Ballon d’Or.
Oun si ni balogun to ko ikọ Portugal sodi gba ife ẹyẹ European Nations League akọkọ.












