Abẹ̀ṣẹ́kùbíòjò Israel Adesanya ti fàgbà han Alex Pereira látí gba àmì ẹ̀yẹ UFC middleweight padà

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Afẹṣẹkubiojo, Israel Adesanya ti fakọyo ninu ifagagbaga laarin oun ati Alex Pereira lẹyin to lu ni alubami.

Idije lati gba ami ẹyẹ UFC middleweight naa lo waye ni FTX Arena ni Maiami, Florida owurọ Ọjọ Aiku.

Lasiko ti wọn n fẹṣẹkubiojo fun saa keji ni Adesanya naa ni alubami bii ti aṣọ ofi, to si gba ami ẹyẹ naa pada lọwọ Pereira.

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Ìgba akọkọ ni yii ti Israel Adesanya yoo rẹyin Pereira

Igba akọkọ ni yii ti Adesanya yoo naa Pereira to naa ni Oṣu Kọkanla, ọdun 2022 to si gba ami ẹyẹ naa lọwọ rẹ.

Ṣaaju ni Pereira to wa lati orilẹede Brazil ti na Adesanya lẹẹmeji lasiko ti ija pa wọn pọ ni Maddison Sqare Garden ni New York.

Ni ẹyin o rẹyin, Adesanya fi agba han Pereira to si gba ami ẹyẹ MMA rẹ pada ni igba 24-2 (13-2 UFC).

Amọ igba akọkọ ni yii fun Pereira lati fidirẹmi ninu idije UFC (4-1 UFC).