Akọ́nimọ̀ọ́gbá wo ní yóò tán ìṣòrọ Chelsea báyìí?

Oríṣun àwòrán, Others
Ni saa yi, ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea ti lo akọnimọọgba mẹrin ọtọọtọ fun awọn ifẹsẹwọnsẹ wọn sugbọn pabo ni o da pe gbogbo rẹ n bọ si.
Laipẹ yii ni wọn kede akọnimọọgba wọn tẹlẹ, to tun agbabọọlu fun ikọ naa nigba kan ri Frank Lampark gẹgẹ adele akọnimọọgba titi ti daa yii yoo fun pari lẹtin ti wọn fi ọwọ osi juwe ile fun Graham Potter.
Pẹlu bi wọn se Lampard naa, ọwọm iya si ba wọn ninu pẹlu ifẹsẹwọnsẹ wọn pẹlu ikọ Wolves loni.
Bi wọn se ti wa kede pe awọn n wa akọnimọgba tuntun ti da wọn pada si ipo olori ti wọn pada, ọpọlọpọ awọn akọnimọọgba lo ti fi ifẹ han lati tukọ ikọ naa.
Yatọ si pe awọn kan fi ifẹ han lati tukọ ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea, ikọ naa ti dẹnu kọ awọn akọnimọọgba kọkan lati wa isẹ naa, ki wọn si se ayeyọri nibẹ.
Wo awọn akọnimọọgba to sese ko tukọ ikọ Chelsea ni saa to n bọ.
Julian Nagelsmann
Awọn ikọ to ti tukọ ri: Hoffenheim (2016-19), RB Leipzig (2019-21), Bayern Munich (2021-23)
Iye ifẹsẹwọnsẹ to ti tukọ : 243
Iye ami ẹyẹ to ti gba: 1 x Bundesliga
Kete ti wọn fi ọwọ osi juwe ile fun Potter, ọpọ lo gbagbọ pe Julian Nagelsmann, olukọni ikọ Bayern Munich tẹlẹ ni yoo gba isẹ akọnimọọgba fun ikọ Chelsea.
Igba akọkọ larin ọdun meje to ti bẹrẹ isẹ akọnimọọgba ti Nagelsmann yoo wa lai si isẹ re.
Nagelsmann ni Bayern fi ọwọ osi juwe ile fun ti wọn si kede Akọnimọọgba fun ikọ Chelsea tẹlẹ Thomas Tuchel gẹgẹ adari tuntun
Mauricio Pochettino
Awọn ikọ to ti tukọ ri: Espanyol (2009-12), Southampton (2013-14), Tottenham (2014-19), PSG (2021-22)
Iye ifẹsẹwọnsẹ to ti tukọ: 461
Iye ami ẹyẹ to ti gba: 1 x Ligue 1, 1 x Coupe de France
Pochettino se daada pẹlu ikọ Espanyol, Southampton, ati ikọ Totteenham sugbọn orilẹede Francẹ pẹlu ikọ PSG lo ti gba ami ẹyẹ akọkọ.
Lati igba ti Potter ti lọ si iroyin kan ti n gbe kiri pe o sese ki ikọ Chelsea gba Poxhettino gẹgẹ olukọni tuntun.
Luis Enrique
Awọn ikọ to ti tukọ ri:: Roma (2011-12), Celta Vigo (2013-14), Barcelona (2014-17), Spain (2018-19, 2019-22)
Iye ifẹsẹwọnsẹ to ti tukọ: 190
Iye ami ẹyẹ to ti gba ri: 1 x Champions League, 2 x La Liga, 3 x Copa del Rey
Luis Enrique gba ife ẹyẹ mẹta lọdun kan fun ikọ Barcelona.
O sese ki Chelsea nifẹ lati yan Enrique gẹgẹ olukọni wọn tuntun
Zinedine Zidane
Awọn ikọ to ti tukọ ri: Real Madrid (2016-18, 2019-21)
Iye ifẹsẹwọnsẹ to ti tukọ: 183
Iye ami ẹyẹ to ti gba ri: 3 x Champions League, 2 x La Liga
Bakan ni olukọni fun ikọ Real Madrid tẹlẹ yii wa lara awọn to sese ko di olukọni fun ikọ Chelsea ni saa to n bọ yi..















