Ẹwo àwọn akọ́nimọ̀ọ́gbá 13 tí wọ́n tí fí ọwọ́ òsì júwe ilé fún ní sáà Premier League yìí

Aworan Ẹgbẹ Agbabọọlu

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Olukọni mẹtala ni wọn ti juwe ile fun ni idije Premier League ti Ilẹ Gẹẹsi to n lọ lọwọ, to si ku ayo mẹsan to pari.

Ikọ ẹgbẹ agbabọọlu to ba ṣe ipo akọkọ lori tabili ni yo gba ife ẹyẹ olubori ninu idije naa.

Lara ohun ti wọn fi le awọn akọnimọọgba ti wọn fi ọwọ osi juwe ile fun ni pe ẹgbẹ agbabọọlu wọn ko fakọyọ tabi kunjuwọn ninu idije to n lọ lọwọ naa.

Eyi ti o sẹsẹ sẹlẹ ni ti akọnimọọgba ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea, Graham Potter ti wọn juwe ile fun lẹyin ti ẹgbẹ agbabọọlu Aston Villa fi pasan iya jẹ ni Stanford Bridge, pẹlu ayo meji.

Osu Kẹsan an ọdun to kọja lẹgbẹ agbabọolu Chelsea gba akọnimogba Graham Potter, to si lo ọjọ mẹfalenigba(206) ninu ikọ naa.

Ile isẹ BBC se akojọpọ gbogbo awọn akọnimogba mẹtala ti wọn ti fi ọwọ osi juwe ile fun naa

Ẹni akọkọ ti wọn juwe ile fun ni saa bọolu yi ninu idije EPL ni Scott Parker to jẹ olukọni ẹgbẹ agba bọọlu Bournemouth, Thomas Tuchel ti Chelsea, Graham Potter ti Brighton, Bruno Lage ti Wolves, Steven Gerrard ti Aston Villa, Ralph Hasenhuttl ti Southampton, Frank Lampard ti Everton, Jesse March ti Leeds United, Nathan Jones Southampton, Patrick Viera Crystal Palace,Antonio Conte Totteham Hotspur,Brenda Rogers Leicester City,Graham PotterChelsea.

Aworan Egbe agba boolu

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Akọnimọọgba Scot Parker ni ẹni akọkọ ti wọn juwe ile fun ninu idije EPL, lẹyin ti ẹgbẹ agbabọọlu Liverpool na ẹgbẹ agbabọọlu to n ṣe olukọni fun ni amin ayo mẹsan si odo (9-0) ,ni papa isere Anfield.

Ẹẹmẹrin ni Parker ko ikọ agba bọọlu Burnemouth sodi ninu idije EPL ,o bori lẹkan soso, nigba ti o na ẹgbẹ agba bọọlu Aston Villa pẹlu ami ayo meji, ki ẹgbẹ agbabọọlu Man City, Arsenal, Liverpool to fi bẹmbẹ iya na Bournemouth pelu apapọ goolu mẹrindinlogun.

Thomas Tuchel, Akọnimọọgba akọkọ to se kanri ti wọn gba sẹ lọwọ rẹ ni Tuchel lẹyin ti o gba ife ẹyẹ UEFA Champions League fun ikọ agbabọọlu Chelsea,ko iko ẹgbẹ agba bọọlu Chelsea sodi lẹẹmeje ni saa yii, o bori lẹmerin o si padanu ayo mẹta ki wọn to fọwọ osi juwe ile fun lọjọ keje osu kẹsan ọdun 2022.

Steven GerrardWọn gbasẹ lọwọ Steven Gerrard lẹyin osu mọkanla to di akọni mogba ẹgbẹ agba bọọlu Aston Villa.

Gerrard ko ẹgbẹ agba bọọlu Aston Villa sodi lẹmejila ni saa EPL ọdun yii,o bori lemeji to si bọrẹlọwọ ninu ifẹsẹwọnsẹ mẹwa,wọn gba isẹ lọwọ rẹ lẹyin ti ẹgbẹ agbabọọlu Fulham fagba han ikọ Aston Villa pẹlu amin ayo mẹta.

AWORAN AKONIMOGBA

Oríṣun àwòrán, Screengrab

Antonio Conte,lo fi ṣẹ silẹ lẹyin ti o sọrọ tako ikọ agba bọọlu Toteham ati awọn agba bọọlu rẹ lẹyin ti wọn gba ọmin ayo mẹta mẹta pẹlu ikọ agbabọọlu Southampton.

Brenda Rogers ati Graham Potter ni wọn juwe ile fun lọjọ kan na,Brenda Rogers lo ti ko ikọ agba bọọlu Liverpool sodi ri,ẹgbẹ agbabọọlu Celtic lo wa to fi gba iṣe olukọ Leicester,o gba ife ẹyẹ FA pẹlu ikọ agba bọọlu Leicester.

Graham Potter ni Chelsea fun ni adehun ọdun marun nigba ti o tẹwo gba isẹ akọni ma gba Chelsea nigba ti wọn san millionu mejile logun fun ikọ agba bọọlu Brighton.

AWORAN AKONIMOGBA

Oríṣun àwòrán, SCREENGRAB

Chelsea nile wọn, Bruno Saltor ni Chelsea kede ko gba ipo rẹ gẹgẹ bi olukoni fidi hẹ.

Pẹlu bi o ti ku idije mewa ti saa bọolu EPL ọdun yi yo wa so pin, ireti wa fun awọn ẹgbẹ agba bọọlu kọkan wi pe wọn o ni borẹlẹ be ni awọn miran bi ẹgbẹ agba bọọlu Chelsea ti n gbiyanju lati du ipo kẹrin ki wọn le kopa ninu idije Champions League ọdun to n bọ.

Ki idije EPL saa yii to wa sọpin o ṣẹsẹ ki awọn akọni ma gba miran padanu isẹ wọn ti wọn ko ba jawe olubori ninu ifẹsẹ wonsẹ mẹsan to sẹku,ibere ti o n bẹbẹ fun idanhun ni talokan ti yo padanu ise rẹ lara awọn akọni ma gba?