“Mo ṣì wà láyé!” Ẹ wo bí Póòpù Francis ṣe dárí ìsìn Imọ̀ Ọ̀pẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ero ọpọ eniyan ni pe niwọn igba ti Poopu gbogbo ijọ Katoliki lagbaye, Pope Francis ti wa nile iwosan ni Ọjọru ọsẹ yii pẹlu iṣoro to ni ṣe pẹlu eemi rẹ, ara rẹ le ma ya lọ titi lati le dari isin kankan paapaa awọn eyi to ṣe pataki ninu iwe kajokasu awon ẹlẹsin Kristẹni.
Amọ, Francis ti ṣeleri pe oun yoo ba wọn pe nibẹ to si fi akoko ranpẹ juwọ si awon eeyan bii ẹgbẹrun lọna ọgbọn bi o ṣe n gun kẹkẹ onidansaki rẹ kọja ni gbọngan ti ayẹyẹ ọjọ isinmi ọpẹ ti waye.
Ibudo naa ni wọn ṣe lọṣọ pẹlu ọpọ ododo ati ewe mii to le ni ẹgbẹrun marunlelogbon.
Irisi Poopu ẹni ọdun mẹrindinlaadọrun naa jo pe ko fibẹẹ rẹrin gẹgẹ bo se n tẹle ọwọọwọ awọn to n wọde ni St Peter’s Square lara awọn ti awọn alufa Cardinal to wọ asọ pupa ti gbe imọ ọpe nla nla ati oniruuru eka igi Olifi dani.
Ki ni itumọ ọjọ isimi Ọpe?
Ọjọ isinmi Ọpe ti awọn ọmọleyin Kristi maa n sami re lọdọọdun jẹ ọsẹ kan saaju ọjọ Ajinde Jesu Kristi.
Ọjọ yii ninu bibeli jẹ ọjọ ti Jesu gun ketekete wọ ilu Jerusalemu saaju asiko ti wọn kan an mọ agbelebu.
Ọjọ ọdun Ajinde eyi ti ti ọdun yii bọ si ọjọ kesan osu kerin je ọjọ ti wọn maa n se ayeye bi Jesu ṣe jinde kuro ninu oku.
Poopu ijo Katoliki to maa n dari iru awon isin yii terin terin nilẹ Yuroopu ni agba ti de si lara bayii to si nilo itọju nileewosan.
Adari awon ijọ Katoliki yii ti wọn le ni bilionu kan lagbaye wa nileewosan ni ọjọ die seyin amọ o ṣeleri pe oun yoo ba wọn pe ninu ijọsin ọse yii to se pataki julọ laarin awon Kristeni.
''Àra Pope Francis tí ń balẹ̀ lẹ́yìn tó bẹ̀rẹ̀ ìtọ́jú ní iléèwòsàn''

Oríṣun àwòrán, Reuters
Vatican ti fi idi rẹ mulẹ pe ara Pope Francis ti n balẹ ni ileewosan to ti n gba itọju.
Eyi ko ṣẹyin bi wọn ṣe gbe lọ si ileewosan fun aisan eemi amọ ti wọn ni kii ṣe Coronavirus.
Agbẹnusọ fun Vatican, Matteo Bruni lo fi idi rẹ mulẹ pe Pope sun daradara ni alẹ eleyii to mu rọrun fun ni aarọ nigba ti o ji ti ara rẹ si balẹ.
Amọ o ni ohun ko lee sọ igba ti Pope yoo kuro ni ileewosan.
Aṣoju Vatican naa ni Pope jẹun, o sun o si gbadura.
Bakan naa ni wọn fikun un pe ireti wọn ni pe Pope yoo le ṣe ayẹyẹ Ọjọ Isinmi Ọpẹ.
Saaju ni wọn ti sọpe Pope naa n koju aisan eemi ti ko ja geere amọ ko niiṣe pẹlu arun Corona virus.
Pope dèrò ilé ìwòsàn torí kò le mí dáadáa àmọ́ kìí ṣe àrùn Kòró

Oríṣun àwòrán, AFP
Poopu ijọ Aguda, Pope Francis, ni wọn ti gbe lọ si ile iwosan Gemeli to wa nilẹ Rome nitori aisan to nii se pẹlu aile mi daadaa.
Poopu, ẹni ọdun mẹrindinlaadọrun lo ni isoro to ni se pẹlu eemi rẹ sugbon aisan naa yatọ si arun Covid-19.
Ọkan lara awọn to sunmọ Poopu ni awọn osiṣẹ ati awọn to pese aabo fun nikan ni yoo duro ti nile iwosan to wa.
Akoko ti Poopu se aisan yii jẹ ọkan ninu awọn akoko ti o yẹ ki o farahan ninu ọpọ isin to nii se pẹlu aawẹ lẹnti, to tun sunmọ ayajọ ọdun ajinde.
Aarọ ọjọru ni Poopu dari isin ni gbọngan St Peter pẹlu ọyaya bo tilẹ jẹ wi pe o fajuro nigbati wọn gbe sinu ọkọ ayọkẹlẹ rẹ.
"Ẹ gbadura ilera alaafia fun Poopu" Joe Biden
Ọpọ eeyan lo ti n gbadura fun Poopu ki ara rẹ le ya ni kiakia.
Lara awọn aladura naa ni Aarẹ Joe Biden ti Orilẹede Amẹrika to ni Poopu Francis ni iwa to farapẹ ti Jesu Kristi.
Pope Francis ti ṣaaju ni aisan to nii se pẹlu orunkun, ti ko si le da rin fun ọpọ igba.
Sugbon pẹlu gbogbo aisan yii, Pope ti rinrin ajo lọ si Orilẹede South Sudan ati Congo, ninu osu keji ọdun yii.
Poopu ti saaju kede wi pe ti aisan ba da oun lọwọkọ lati sisẹ, o seese ki oun kọwe fipo silẹ, gẹgẹ bi Poopu Benedict, ẹni ti o gba ipo lọwọ rẹ ti se.
Kí ló ń ṣẹlẹ̀ ní France tí àwọn aráàlú fi ń dáná sún ilé, ṣe ìfẹ̀hónúhàn?

Oríṣun àwòrán, screengrab
Awọn araalu to to milọnu kan lo jade lati se ifẹhonuhan ti awọn to le ni ọkẹ marun miran si n se iwọde ni Paris, to jẹ olu ilu France, ni Ọjọbọ ọsẹ yii gẹgẹ bi akọsilẹ ile iṣẹ to risi ọrọ abẹle se kede.
Lati pẹtu si aawọ, awọn osiṣẹ Ileeṣẹ ọlọpaa ti bẹrẹ lati ma yinbon tajutaju lati pana iwọde naa, ti wọn si mu eeyan ọgọrin si atimole nitori wọn kopa ninu ifẹhonu han na.
Ifẹhonuhan na lo waye nitori igbeṣẹ ijọba lati fi ọdun meji kun ọdun ti awọn osiṣe yoo lo lẹnu isẹ lati ọdun ejilelọgọta si ẹrinlelọgọta.
Awọn adari osiṣẹ lorilẹede France ti pe ki iwodi naa tẹsiwaju lọjọ Isẹgun, ọjọ to sẹsẹ ki Ọba ile Gẹẹsi, King Charles se abẹwo si orilẹede France ti ilu Bordeaux si wa lara awọn ilu ti yo se abẹwo si.
Botilẹ jẹ wi pe awọn osiṣẹ panapana ti balẹ si ibudo ti iwode naa waye lati pa ina to n jo ninu gbọngan igbalejo ilu Bordeaux naa.
Minisita fun ọrọ abẹle ni ṣaaju ki Ọba ile Gẹẹsi to wa lọjọ Isẹgun ọsẹ to n bo eto abo ilu na yo ti wa ni ṣẹpẹ.
Olotu ijọba Orilẹede France Élisabeth Borne loju opo ayelujara Twitter rẹ ni
”Ifẹhonuhan ati iwọde jẹ ẹto araalu, ṣugbon bi wọn se n ba awọn dukia ijọba ati aladani jẹ nkan lo buru ju,
"Mo dupe lọwọ awọn osisẹ Ileeṣẹ Ọlọpaa ati awọn osiṣẹ adola ẹmi fun iṣẹ takuntakun ti wọn n se.”

Oríṣun àwòrán, Reuters
Lara awọn to n se iwọde nigba ti wọn ba ile iṣẹ Akọroyin Reuters sọrọ wọn ni
”Ifẹhonuhan nikan ni yo jẹ ki ijọba mo pe a ko nifẹ si awọn aba ofin wọn, gbogbo igbiyanju wa saaju ni ko jamo nkankan ṣugbon pẹlu ifẹhonuhan ti a se yii, wọn ti mo wi pe inu wa ko dun si igbesẹ ijọba’.
Iwọde na ni yo jẹ ifẹhonuhan kẹsan lati ibẹrẹ ọdun yii lorilẹede France, ti awọn osisẹ si tu n pe fun itẹsiwaju ifẹhonuhan ni ọjọ Isẹgun ọsẹ to n bọ.
















