Kí ẹgbẹ́ APC má wulẹ̀ lọ ilé ẹjọ́ kankan mọ́ o - Àwọn ará Osun pariwo torí Adeleke

Àkọlé fídíò, Adeleke vs Oyetola: Kí ẹgbẹ́ APC má wulẹ̀ lọ ilé ẹjọ́ kankan mọ́ o - Àwọn ará Osun pariwo

BBC Yoruba lọ si igboro ilu Osogbo lẹyin abajade igbẹjọ laarin Gomina Ademola Adeleke ati Adegboyega Oyetola.

Awọn ara ilu Osun ni Ede ati ni Osogbo sọ esi wọn nipa ohun ti wọn gbọ pe o ṣẹlẹ nile ẹjọ kotẹmilọrun l'Abuja.

Ẹ wo ìhà tí wọ́n kọ sí ìdájọ́ ile ẹjọ naa laarin Oyetola ati Adeleke.

Ademola Adeleke

Ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn kéde Ademola pé ó borí ṣùgbọ́n ...

Ọkan lara agbẹjọro Gomina tẹlẹ nipinlẹ Osun, Kunle Adegoke sọ fún BBC Yoruba pe ileẹjọ ti kede pe Gomina Ademola Adeleke lo bori eto idibo to waye lọdun to kọja nipinlẹ Osun.

Ṣugbọn Kunle ni awọn yoo morile ileẹjọ giga ilẹ Naijiria lati tako ẹjọ ti ileẹjọ kotẹmilọrun gbe kalẹ.

Ninu oṣu kini ni ileẹjọ to n gbọ ẹjọ lori awuyewuye eto idibo kede pe Gomina tẹlẹ nipinlẹ Osun, Gboyega Oyetola lo bori ibo.

Adegoke ni idajọ ileẹjọ kotẹmilọrun ni ko tẹle ilana eto idibo orilẹede Naijiria tuntun.

Ẹwẹ, ni Abuja, ilé ẹjọ́ tí ní ẹ̀sun tí wón fi kan Ademola Adeleke lórí pé ó sé ayédèrú ìwé ẹ̀rí , kò fẹsẹ̀ múlẹ̀ rárá.

Ilé ẹjọ́ tun fi ẹ̀sùn kan ìgbìmọ̀ tó ń gbọ awuyewuye lórí ètò ìdìbò, ìyẹn Tribunal lórí ìdájọ́ wọn.

Ademola Adeleke ló léwájú ìgbẹ́jọ́ l'Abuja!

Oyetola ati Adeleke

Ile ẹjọ kotẹmilọrun to wa ni ilu Abuja ti lọ fun isinmi ranpẹ to si jẹ wipe gbogbo ẹjọ ti wọn n da lo n gbe Ademola Adeleke lẹyin.

Adájọ́ tún tẹ̀síwájú pé gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí tó wà níwájú òun,nǹkan kan náà ní àwon ẹ̀rí náà.

Lara awọn ọrọ mii to jẹ jade ni wipe adájọ́ ti fagilé ẹ̀sùn lórí ẹ̀rọ BVAS, tí wọ́n lo lásìkò ètò ìdìbò gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun, pé kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀.

Kí àwọn afẹ̀sùnkàn méjèèjì (Oyetola ati APC) san owó ìtanràn N500,000

Adajọ ti paa laṣẹ pe ki àwọn afẹ̀sùnkàn méjèèjì Iyẹn Gboyega Oyeatola ati ẹgbẹ Oselu rẹ, APC san owó ìtanràn N500,000 fun Gomina Ademola Adeleke.

Bakan naa, ilé ẹjọ́ fagilé ẹ̀sùn pé Ademola Adélékè sé màgò-mágó ìwé ẹ̀rí tó lò láti fi dìbò.

Ilé ẹjọ́ tun sọ pé gómìnà Ademola Adeleke lẹtọ láti díje fún ipò gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun.

Gbogbo ẹjọ́ sì ń gbé Adeleke Ademola báyìí, adájọ́ tún ni kí wọ́n ṣàn owó ìtanràn ₦500,000,ẹẹ̀dẹ́gbẹ̀ta ẹgbẹ̀rún náírà Five hundred thousand niara fún Ademola Adeleke

Ile ẹjọ Kotẹmilọrun

Kò yí padà! Ìgbẹ́jọ́ ti bẹ̀rẹ̀ l'Abuja láàrín Adeleke àti Oyetola

Ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn kún fọ́fọ́ bayii, tí kò gba ènìyàn.

Àwọn àgbẹjọ́rò náà kò gbẹ́yìn nílé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn adájọ́ náà ti wà níkalẹ̀ nílé ẹjọ́ náà.

Awọn eeyan Oyetola

Ilé ẹjọ́ ti kún fọ́fọ́ bayii , tí kò gba ènìyàn mọ́.

Akọroyin BBC Yoruba to wa ni olu ilu orilẹede yii jabọ pe eto gbogbo ti fẹ bẹrẹ. ni ile ẹjọ.

Bakan naa ni akọroyin wa to wa nikalẹ ni ipinlẹ Osun ti gbera lọ si ilu Ede lati maa jabọ bi gbogbo nnkan ṣe ri.

Awọn igun Adeleke

Akọ̀wé ilé ẹjọ́ ti ka ẹ̀sùn tó wà níwájú ilé ẹjọ́ nípa awuyewuye lórí àbájáde èsì ìbò gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun.

O kàá síta pé ẹjọ́ náà dá lórí ìbò èyí tí ó gbé Ademola Adeleke wọlé gẹ́gẹ́ bi gómìnà ìpínlẹ̀ Òsùn ní ọjọ́ kẹrìndílógún oṣù keje , Ọdún 2022.

Ile ẹjọ Kotẹmilọrun

Loni ọjọ Ẹti ni ile ẹjọ kotẹmilọrun yoo gbe idajọ kalẹ lori idije sipo gomina ni ipinlẹ Ọṣun.

Ile ẹjọ kọtẹmilọrun lorilẹede Naijiria, eyi to fikalẹ si ilu Abuja yoo sọ boya gomina Adeleke ti ẹgbẹ oṣelu PDP tabi gomina ana, Gboyega Oyetọla ni gomina ti ilu dibo yan nipinlẹ naa.

Gomina Adeleke to dije labẹ aṣia ẹgbẹ oṣelu PDP lasiko idibo si ipo gomina ni ipinlẹ Ọṣun lọdun 2022 yẹ aga mọ Gboyega Oyetọla to jẹ gomina ipinlẹ naa laarin ọdun 2018 si 2022 nidi.

Tani yóò lulẹ̀ nínú Adeleke àti Oyetola l’Ọ́ṣun? Òní ni iléẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn yóò dájọ̀

Oyetọla ati Adeleke

Oríṣun àwòrán, other

Bawo ni ọrọ ṣe bẹrẹ?

Idibo si ipo gomina nipinlẹ Ọṣun waye lọjọ kẹrindinlogun oṣu keje ọdun 2022. Lọjọ Aiku, ọjọ kẹtadinlogun oṣu keje ọdun 2022 ni ajọ INEC kede Ademọla Adeleke to dije labẹ aṣia ẹgbẹ oṣelu PDP gẹgẹ bi gomina ati olubori ibo naa.

Adeleke moke ni ijọba ibilẹ mẹtadinlogun ninu ijọba ibilẹ Ọgbọn to wa ni ipinlẹ naa.

Gboyega Oyetọla to jẹ oludije APC moke ni ijọba ibilẹ mẹtala.

Lapapọ, Adeleke ko ibo ẹgbẹrun mẹtalenirinwo ati ọọdunrin o le aadọrin ati ẹyọkan (403,371), Oyetọla si ko ibo ẹgbẹrun lọna ọọdun o le marundinlaadọrin ati mẹtadinlọgbọn (375, 027)

Adeleke nibi eto ijẹjẹ rẹ

Oríṣun àwòrán, ademola adeleke/twitter

Pẹlu esi yii, Ademọla Adeleke yẹ aga mọ Gboyega Oyetọla, oludije ti APC to jẹ gomina lasiko naa nidi.

Ẹgbẹ oṣelu marundinlogun ati Oludije wọn lo kopa ninu eto idibo naa lara awọn ti Kẹhinde Munirudeen Atanda pẹlu ibo ẹgbẹrun mẹwaa ati mẹrinlelọgọrun (10,104), Akin Ogunbiyi ti ẹgbẹ oṣelu Accord wa pẹlu ibo ẹgbẹrun mẹrin o le ẹẹdẹgbẹta ati mẹrinla(4,514), igbakeji olori ileegbimọ aṣojuṣofin nigbakan ri, Lasun Yusuf ti ẹgbẹ oṣelu LP to ni ibo ẹgbẹrun meji ati ẹẹdẹgbẹrin o le mọkandinlọgbọn (2, 729) ati Goke Omigbọdun ti ẹgbẹ oṣelu SDP pẹlu ibo ẹẹdẹgbẹta o le marundinlogun(515).

Ile ẹjọ to gbọ awuyewuye idibo kede Oyetọla gẹgẹ bi gomina dipo Adeleke

Lẹyin ikede esi idibo ni Oyetọla gba ile ẹjọ to n gbọ awuyewuye esi idibo gomina nipinlẹ Ọṣun lọ lati tako esi ibo ti ajọ INEC kede.

Lọjọ karun oṣu kẹjọ ọdun 2022 ni Oyetola gba ile ẹjọ lọ nilu Osogbo lati wọgile esi to kede Adeleke gẹgẹ bi olubori ibo naa. O ni ọpọ kotọ lo waye lasiko ibo ọhun ati pe Adeleke ko lẹtọ lati dije nitori “ayederu iwe ẹri lo fi dije”.

Adegboyega Oyetọla, gomina ana ni ipinlẹ Ọṣun

Oríṣun àwòrán, adegboyega oyetola/twitter

Bakan naa lo rọ ile ẹjọ naa pe ko kede oun gẹgẹ bi ẹni gan an ti ilu dibo yan ni ipinlẹ Ọṣun.

Adeleke naa ko igbimọ agbẹjọro mejilelaadọta jọ lati gbẹjọ rẹ ro, Oyetọla ṣa aadọta agbẹjọro jọ lati gbọ ẹjọ tirẹ.

Lẹyin ọpọ atotonu ati awijare, igbimọ adajọ mẹta ile ẹjọ naa gbe idajọ rẹ kalẹ lọjọ igbimọ ọhun.

Labẹ idari onidajọ, Tetse Kume pari igbẹjọ lọjọ kẹtala oṣu kini ọdun 2023 ki o to fi idajọ si ọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu kini kan naa.

Ninu idajọ rẹ, ile ẹjọ to gbọ awuyewuye esi ibo gomina nipinlẹ Ọṣun naa wọgile esi ibo to gbe Adeleke wọle gẹgẹ bii gomina.

Ile ẹjọ naa ni INEC ko tẹle iwe ofin Naijiria ati iwe ofin eto idibo Naijiria.