Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá fèsì bí Simon Ekpa, ọmọ ẹgbẹ́ IPOB ṣe ké sáwọn Igbo, láti fìdí mọ́lé l‘Eko

Aworan Oja Balogun ati Simon Epka

Oríṣun àwòrán, Simon Ekpa

Simon Ekpa, adele olori ẹgbẹ to n pe fun ominira Biafra, ti fẹsun kan ijọba ipinlẹ Eko pe awọn lo n se agbatẹru bi awọn janduku kan se kọlu awọn ọja ti awọn ẹya Igbo ti n ta ọja l‘Eko.

Simon Ekpa lo kede bẹẹ loju opo ayelujara Twitter rẹ , to si kede igbesẹ konile o gbele fun awọn ẹya Igbo to wa nipinlẹ Eko.

O ni ikọlu tawọn tọọgi n se ni Eko naa n se ọpọlọpọ akoba fun eto ọrọ aje ati pe igbesẹ ti wa nilẹ lati jẹ ki awọn igbo ko ọja kuro wọn kuro nipinlẹ Eko.

"A se akoba fun ọrọ aje ipinlẹ Eko lati gbẹsan nnkan ti wọn se fun ẹya Igbo"

Ekpa ni ipinlẹ Eko ko mọ iyi ati apọnle ti ẹya igbo n se fun ipinlẹ naa ati nnkan ti wọn se fun idagbasoke ọrọ aje nibẹ.

"A o fi agbara igbo han nipinlẹ Eko lai lo ibọn."

"O se koko pe ki ofin konile o gbele laarin ẹya Igbo fi ẹsẹ mulẹ nipinlẹ Eko.

"Ijamba ti ijọba Eko n se fun awọn ẹya ibo ti pọju, ti a si se akoba fun ọrọ aje ipinlẹ Eko lati fi gba ẹsan nnkan ti wọn se fun wa.

"Mo n kesi gbogbo ẹya ibo pe a setan lati pese abo to peye fun wọn lati gbe osowo wọn kuro nipinlẹ Eko oda ilẹ Ibo ti wọn ti wa."

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post, 1

Igbesẹ Simon Ekpa yoo mu adikun ba sukẹrẹ fakẹrẹ ọkọ nipinlẹ Eko -Ileeṣẹ Ọlọpaa

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko, Benjamin Hundeyin ti wa fesi si ọrọ ti Simon Epka gbe sita naa.

Hundeyin, lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ ni ileeṣẹ ọlọpaa ko ni anfani lati sọ fun ẹnikẹni lati joko sile tabi jade sita.

Hundeyin ni ipese eto aabo to peye fawọn eeyan nipinlẹ Eko lo jẹ ileeẹẹ ọlọpaa logun.

Bẹẹ lo ni awọn ko ni anfani lati sọ fun ẹnikẹni lati se oun ti ọkan wọn fẹ, ti wọn ko ba ti tapa sofin.

Agbẹnusọ fun ileesẹ ọlọpaa fikun pe "Igbesẹ Simon Ekpa naa yoo mu adikun ba sukẹrẹ-fakẹrẹ ọkọ nipinlẹ Eko.

"Anfani wa fun ẹnikẹni lati duro sile tabi jade lọ se okoowo rẹ, a si ti setan lati pese abo fun wọn.

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post, 2

''Irọ́ ní pé àwọn ṣoja pá àwọn ògo wẹẹrẹ ní àríwá Naijiria''

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Adari ikọ ọmọogun ilẹ Naijiria, Ọgagun Faruk Yahaya ti fi ọwọ osi da iwadii to ni awọn ikọ ọmọogun Naijiria n pa awọn ọmọde ni iha ariwa orilẹede Naijiria.

Oṣu Kejila, ọdun to kọja ni ileeṣẹ iroyin Reuters gbe iroyin jade pe awọn ikọ ọmọogun Naijiria to n tako ikọ agbesunmọmi Boko Haram ṣẹ oyun fun awọn ọdọbinrin ti awọn ikọ Boko Haram jigbe.

Iroyin naa lo mu ki ajọ iṣọkan agbaye kesi ijọba orilẹede Niajiria lati ṣewadii awọn ẹsun naa ni kiakia.

Ninu ọrọ rẹ, adari ikọ ọmọogun ilẹ ni Naijiria ni ikọ ọmọogun Naijiria pẹlu awọn ikọ ọmọogun to dara julọ ni agbaye.

Awọn ọmọogun Naijiria mọ iṣẹ wọn ni iṣẹ, ti wọn si kawe gba oye bi o ṣe yẹ.

Awọn miran tilẹ ro pe ori igi la wa ni Niajiria amọ o yẹ ki o ye wọn pe awọn ikọ ọmọogun naa ti lọ gba imọ ni ilẹ okeere to fi mọ US ati UK, ti wọn si di ipo giga mu.

O ṣeni laanu pe a ko jamọ nkankan loju awọn ara ilẹ wa, ko si ohun ti a ṣe to dara loju wọn, eyi buru jai.

Bakan naa ni adari ikọ ọmọogun ile naa paṣẹ pe wọn gbọdọ ṣewadii ileeṣẹ iroyin Reuters naa ati idi ti wọn fi gbe iroyin ẹlẹjẹ nipa wọn.

Ọgagun Faruk Yahaya ni ko si otitọ̀ ninu iroyin naa ati pe awọn agbegbe ti wọn darukọ pe iṣẹlẹ naa ti waye kii ṣe ibi ti eniyan kan dede lọ, yoo nilo iwe aṣẹ lati kọja ni awọn agbegbe wọnyii.

Ìdí tí mo fi fi ẹjọ́ Obi, Datti sun DSS - Keyamo

Festus Keyamo, SAN.

Oríṣun àwòrán, festus keyamo

Minisita keji fun ọrọ oṣiṣẹ ati ijafafa iṣẹ lorilẹede Naijiria, Festus Keyamo, SAN ti fi ẹsun kan oludije fun ipo aarẹ lẹgbẹ oṣelu LP, Peter Obi ati igbakeji rẹ, Datti Baba-Ahmed pe wọn n gbiyanju lati ru awọn ololufẹ wọn soke lati da wahala silẹ lorilẹede Naijiria.

Nitori eyi, Keyamọ ti wa gba ileeṣẹ agbofinro DSS lọ bayii pẹlu iwe ifisun kan pe ki DSS o tete wa nnkan ṣe si ọrọ naa ko to di wi pe o burẹkẹ di ohun ti apa ko ni ka mọ.

Nigba to n farahan lori eto ileeṣẹ mohunmaworan abẹle kan lorilẹede Naijiria, ‘Channels television’ Keyamo sọ wi pe oun fẹ ki DSS pe awọn mejeeji ni lori bi wọn ṣe n sọ kiri pe awọn ko ni gba kikede ti wọn kede Bọla Tinubu gẹgẹ bi aarẹ ti ilu dibo yan lorilẹede Naijiria.

Bi o tilẹ jẹ pe esi idibo sipo aarẹ ti ajọ INEC fi sita fihan pe ipo kẹta ni LP duro si, Obi ati igbakeji rẹ ṣi n pariwo pe awọn lo bori idibo yii, ti wọn si n fọnrere rẹ pe oniruru iwa kotọ lo waye ṣaaju, lasiko ati lẹyin idibo naa bii iwa ifipakọluni, ati idunmọhuru mọni.

Ninu ifọrọwanilẹnuwo pẹlu igbakeji Peter Obi, Datti Ahmed ni ibo ẹgbẹ awọn le ni miliọnu mẹjọ ati pe oun mọ nnkan ti oun n sọ to si wa labẹ ofin.

Bola Tinubu

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Awọn igun Tinubu ti ke sawọn to lulẹ nibi idibo naa lati gba ile ẹjọ lọ gẹ bi ofin ṣe laa kalẹ, eleyi ti awọn alatako ti foju wo pẹlu ifura.

Keyamọ ni nnkan ti awọn oludije ẹgbẹ oṣelu LP naa n ṣe ni lati ru awọn eeyan lọkan soke lati doju wọn kọ ẹka iṣedajọ.