Ẹbí, ọ̀rẹ́ sọ̀rọ̀ nípa ìgbà ìkẹyìn Oladipo Diya

Oríṣun àwòrán, Facebook
Àwọn ẹbí, ará, ọ̀rẹ́ àti ojúlùmọ̀ ló ti ń ṣelédè lẹ́yìn ọ̀gágun Diya tó dolóògbé.
Àwọn ẹbí àtàwọn ọ̀rẹ́ tí ikú olóògbé náà bá lójijì ṣàlàyé àwọn ilàkàkà àti bí ọ̀gágun Diya ṣe lo ìgbẹ̀yìn ayé rẹ̀ kí ọlọ́jọ́ tó dé.
Ọ̀rẹ́ olóògbé kan sọ fún àwọn akọ̀ròyìn pé láti bí ọjọ́ mélòó kan ni Diya ti ń ṣe àárẹ̀ ṣùgbọ́n tí àárẹ̀ rẹ̀ wá burú si lẹ́nu ọjọ́ mẹ́ta yìí nígbà tó di wí pé kò le sọ̀rọ̀ mọ́.
Ó ní òru ọjọ́ Àbámẹ́ta sí òwúrọ̀ ọjọ́ Àìkú ni àárẹ̀ náà tún lékún síi, tí wọ́n sì sáré gbe dìgbàdìgbà lọ sí ilé ìwòsàn kan tó wà ní agbègbè ilé rẹ̀ ní Ikeja.
Ó fi kun pé ilé ìwòsàn náà ni Diya dákẹ́ sí.
“Lára àwọn òṣìṣẹ́ inú ilé ló bá Diya, tí ara rẹ̀ kò ṣe daadaa mọ́ nínú yàrá ní ilé ìgbé rẹ̀ tó wà ní 31, Adekunle Fajuyi, Ikeja GRA, nilu Eko, tí a sì sáré gbe lọ sí ilé ìwòsàn."
Láti ọdún díẹ̀ sẹ́yìn ni Diya kò ti máa lọ sóde àyàfi ti mọ̀lẹ́bí nìkan – Agbenusọ Diya
Agbẹnusọ fun Diya, Olawale Adekoya ní láti bí i ọdún díẹ̀ sẹ́yìn ni ọ̀gágun Diya kò ti máa kópa ní ayẹyẹ púpọ̀ mọ́ àyàfi èyí tó bá jẹ́ ti àwọn ẹbí rẹ̀ nìkan.
Olawale ní gẹ́gẹ́ bí ìṣe, ó ní ìsìn tí àwọn máa ń ṣe nínú ilé rẹ̀ èyí tí Diya máa ń kópa nínú rẹ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀.
“Diya kìí jẹun púpọ̀ mọ́ láti bí ọdún díẹ̀ sẹ́yìn, tí kìí sì lọ sí òde àríyá tí kìí bá ṣe ti mọ̀lẹ́bí mọ́ nítorí ọjọ́ orí rẹ̀.”
“Ní òru ni ọ̀kan nínú àwọn òṣìṣẹ́ ilé ri pé ara rẹ̀ kò balẹ̀ mọ́, tí wọ́n sì gbé wọn lọ sí ile ìwòsàn níbi tí wọ́n ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ọlọ́jọ́ ti dé.”
“Kò sí nínú ìnira kankan, ṣiṣẹ́ abẹ tàbí wà nínú ìpè pàjáwìrì tí ọlọ́jọ́ fi dé kódà à ń gbèrò láti ṣe ọjọ́ ìbí fún-un ní ọ̀sẹ̀ tó ń bọ̀ ni ọlọ́jọ́ dé yìí.”
“Ó wà lára àwọn tí wọ́n kọ́kọ́ kẹ́kọ̀ọ́ jáde ní Nigerian Defence Academy, bẹ́ẹ̀ náà ní Odogbolu Grammar School àti ọ̀gágun àkọ́kọ́ fún National War College, Eko.
Olawale fi kun pé Diya kọ ìwé kan tó pè ní “Destiny Anchored On Faith” èyí tó jẹ́ nípa ìtàn ìgbésí ayé rẹ̀ àti àwọn ohun tí ojú rẹ̀ rí nígbà ogun abẹ́lé.
Ènìyàn tó kó gbogbo ẹbí mara ni ẹ̀gbọ́n mi - abúrò Diya
Wole Diya tó jẹ́ àbúrò olóògbé Dipo Diya, tó tún fìgbà kan rí jẹ́ ọmọ ilé aṣòfin orílẹ̀ èdè yìí ní ẹni tó kó ẹbí mọ́ra ni olóògbé Diya jẹ́.
Ó ní òun ló dúró gẹ́gẹ́ bí bàbá fún gbogbo àwọn láti ìgbà tí bàbá àwọn ti kú láti ogójì ọdún sẹ́yìn tó sì ri dájú pé gbogbo àwọn ló rán lọ sílé ẹ̀kọ́.
“Òun ló wà nídìí bí gbogbo wa ṣe lọ sílé ẹ̀kọ́ tó sì jẹ́ wí pé ohun tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ wa dì lónìí, òun ló wà nídìí rẹ̀.”
Àwọn nǹkan mẹ́wàá tí o kò mọ̀ nípa Dipo Diya tó dolóògbé nìyí

Oríṣun àwòrán, Facebook
Ńṣe ni ikú ọ̀gágun Dipo Diya tó jẹ́ igbákejì olórí orílẹ̀ èdè yìí tẹ́lẹ̀ rí bá ọ̀pọ̀lọpọ̀ lójijì bí àwọn rẹ̀ ṣe kéde ikú rẹ̀ ní òwúrọ̀ ọjọ́ Àìkú.
Láti ìgbà tí wọ́n ti kéde ikú rẹ̀ ọ̀hún ni àwọn ènìyàn ti ń kan sáárá sí àgbà ológun náà tó fi ilẹ̀ ṣe aṣọ bora.
Ọ̀pọ̀ nǹkan ni àwọn ènìyàn kò mọ̀ nípa ọ̀gágun Diya pàápàá àwọn ọmọ òde òní.
Ìdí nìyí tí BBC News Yorùbá fi ṣe àkójọ àwọn mẹ́wàá tó yẹ kí o mọ̀ nípa olóògbé Dipo Diya.
Àwọn nǹkan mẹ́wàá ọ̀hún nìyí
- Ní ọjọ́ kẹta oṣù Kẹrin, ọdún 1944 ni wọ́n bí Oladipo Donalson Diya ní Odogbolu, ìpínlẹ̀ Ogun.
- Ọ̀dọ́ ló fi darapọ̀ mọ́ ilé ẹ̀kọ́ ológun ìyẹn Nigerian Defence Academy, Kaduna tó sì wà lára àwọn ológun tó abẹ́lé orílẹ̀ èdè yìí láàárín ọjọ́ Kẹfà oṣù Keje ọdún 1967 sí ọjọ́ Kẹẹ̀dógún oṣù Kìíní ọdún 1970.
- Olóògbé Diya kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìmọ̀ òfin ní ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì Ahmadu Bello University, Zaria tó sì tún lọ sí Nigerian Law School níbi tí tó ti gboyè aṣojú ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ ní Nàìjíríà ìyẹn oyè Solicitor and Advocate of Supreme Court of Nigeria.
- Kó tó di wí pé Diya gboyè gẹ́gẹ́ igbákejì Abacha, ó ti ṣe olórí àwọn ọmọ ogun Nàìjíríà, tó sì tún ti fìgbà kan ṣe gómìnà ológun fún ìpínlẹ̀ Ogun láàárín oṣù Kìíní ọdún 1984 sí oṣù Kẹjọ ọdún 1985.
- Ní ọdún 1993, ni wọ́n yàn-án gẹ́gẹ́ bí igbákejì ìjọba ológun Abacha kí wan tó tún fun ní igbákejì Provisional Ruling Council lọ́dún 1994.
- Ní ọjọ́ Kọkànlélógún oṣù Kejìlá ọdún 1997, ìjọba Abacha gba àwọn àgbà ológun kan bíi ọ̀gágun Tunji Olanrewaju, Abdulkarim Adisa àtàwọn mẹ́sàn-án mìíràn tí Diya náà wà lára wọn fẹ́sùn wí pé wọ́n ń gbèrò láti dìtẹ̀gbàjọba lọ́wọ́ Abacha.
- Ọ̀sẹ̀ kan kí wọ́n tó gbá wọn mọ́lé, Diya móríbọ́ lọ́wọ́ ikú nígbà tí àdó olóró bú gbàmù ní pápákọ̀ òfurufú ìlú Abuja nígbà tó ń lọ ṣojú Abacha níbi òkú ìyá ọ̀gágun Lawrence Onoja ní ìpínlẹ̀ Benue.
- Diya pẹ̀lú ìfọwọ́sowọ́pọ̀ Bamaiyi àtàwọn àgbà ológun mìíràn ń bèèrè nǹkan mẹ́rin lọ́wọ́ Abacha lẹ́yìn tí wọ́n ń ṣe àkíyèsí pé ó fẹ́ sọ ara rẹ̀ di ààrẹ títí láé. Àwọn nǹkan mẹ́rin ọ̀hún ni:
- Wọ́n ṣe ìwádìí Diya níwájú ìgbìmọ̀ àwọn ológun tí wọ́n sì dájọ́ ikú fun àmọ́ lẹ́yìn ikú Abacha, Abdulsalami Abubakar tó gba ipò lẹ́yìn jáwé oríjì fún-un, tí wọ́n sì tu sílẹ̀.
- Lẹ́yìn tí wọ́n tu sílẹ̀, wọ́n gba ipò ọmọ ogun tó wà lọ́wọ́ rẹ̀, le kúrò lẹ́nu iṣẹ́ ológun, tó sì tún di èèwọ̀ fún-un láti máa lo ipò rẹ̀ nínú ológun síwájú orúkọ rẹ̀.
Ikú Diya dùn mí nítorí akínkanjú tó jà fitafita fún Naijiria ni - Bola Tinubu

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Gomina ipinlẹ Eko nigba kan ri, to tun jẹ aarẹ tuntun ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan, Bola Tinubu ti fi iwe ikẹdun ransẹ si idile Ọgagun Oladipo Diya, ẹniti o di ologbe ni Ọjọ Kẹrindinlọgbọn, oṣu kẹta, ọdun 2023.
Ninu iwe ikẹdun rẹ ni Tinubu ti yin Diya fun ipa pataki to ko fun orilẹede Nijiria gẹgẹ bi ologun ati si orilẹede yii lapapọ.
Tinubu ni “Iroyin iku ọgagun Diya bami ninu jẹ laarọ yi ti mo gbọ,mo n ki awọn iyawo ati ọmọ wọn ku ara feraku”.
“Ọgagun Diya gbe igbe aye to dara ṣaaju gẹgẹ bi gomina ologun fun ipinlẹ Ogun ati ninu awọn ipo ti wọn dimu ninu iṣẹ ologun titi ti wọn fi di igbakeji olori orilẹede yii labe ologbe Sani Abacha”.
Aarẹ tuntun teṣiwaju wi pe ”a ko le gbagbe akitiyan rẹ nigba ifẹhonuhan June 12 ati ilakaka rẹ ati ifarasin fun orilẹede yii”.
Tinubu ninu iwe ikẹdun rẹ ki gomina ipinlẹ Ogun Dapo Abiodun ku ara fẹ ra ku, o si gbadura ki Olorun duro ti idile naa.
Dapo Abiodun kọrin arò lẹ́yìn ikú Dipo Diya

Oríṣun àwòrán, Facebook
Gómìnà ìpínlẹ̀ Ogun, Dapo Abiodun ti kọrin arò lẹ́yìn ọ̀gágun Oladipo Diya tó dolóògbé.
Abiodun nínú àtẹ̀jáde kan látọwọ́ olùrànlọ́wọ́ pàtàkì fétò ìròyìn, Kunle Somorin ní ìpínlẹ̀ Ogun àti orílẹ̀ èdè Nàìjíríà lápapọ̀ ti pàdánù akínkanjú ológun tó fi gbogbo ìgbé ayé rẹ̀ sin Nàìjíríà.
Bákan náà ló gbà á ládùrá kí Ọlọ́run tẹ́ olóògbé sí afẹ́fẹ́ rere kó sì fún àwọn ẹbí rẹ̀ ní ọkàn láti gba àdánù wọn.
Olórí òṣìṣẹ́ ìjọba Abacha, Oladipo Diya dágbére fáyé
Ọgagun Oladipupo Oyeyinka Diya ẹni ti o ti fi gba kan ri jẹ igbakeji olori orilẹ ede yii Ọgagun Sani Abacha ti jade laye lẹni ọdun mejidinlaadọrun-un.
Ninu atẹjade ti Amofin Oyesinmilola Diya fi lede lorukọ gbogbo ẹbi lowurọ oni lo ti kede iku Ọgagun Diya.
Gẹgẹ bi atejade naa ṣe sọ, Diya jade laye ni owurọ kutukutu ọjọ kẹrindinlọgbọn osu kẹta, ọdun 2023, to ku ọjọ mẹjo si ọjọ ti kọ ba se ayẹyẹ ọjọ ibi ọdun mọkandinlaadọrun-un.
Tani Ọgagun Oladipupo Oyeyinka Diya?

Oríṣun àwòrán, Facebook
Diya ni wọn bi ni ọjọ kẹta osu Kẹrin ọdun 1944, ti o si di gomina ologun fun ipinlẹ Ogun lẹyin ti Buhari ati Idiagbon gba ijọba ni ọjọ kọkanlelọgbọn osu kejila ọdun 1983.
Diya darapọ mo iṣẹ ologun ni Kaduna ti o si wa lara awọn ologun to ja ninu ija ogun abẹle orilẹ ede yii.
Ogagun Diya tẹsiwaju ninu ẹkọ lọ si ile ẹkọ awọn Ologun ni orilẹede Amẹrika ati ile ẹkọ ti wọn ti n kọ nipa eto ati ọgbọn inu ni Kuru.
Nitori ifẹ to ni si imọ ẹkọ, Diya tun tẹsiwaju lati lọ si ile ẹkọ ti wọn ti n kọ nipa ofin ni fasiti Ahmadu Bello ti ilu Zaria ti o si di agbẹjọro agba fun ile ẹjọ ti wọn ti n gbọ ẹjọ kotẹmilorun Orilẹede yii.
Diya di olori ikọ ologun GOC ọwọ ẹka mejilelọgorun-un ko to di igbakeji olori orilẹ ede labẹ iṣejọba Ologbe Sani Abacha.
Wọn fẹsun iditẹgbajọba kan-an, ti wọn si dajọ iku fun ni ọjọ kejindinlọgbon oṣu kẹrin ọdun 1998.
















