Ìgbẹ́jọ́ èsì ìbò kò ní dá ìbúra Tinubu gẹ́gẹ́ bíi Ààrẹ dúró - Ìjọba àpapọ̀

Oríṣun àwòrán, officialasiwajubat
Ijọba apapọ Naijiria ti fi da awọn ọmọ orilẹede yii loju pe pẹlu bi awọn ẹgbẹ oṣelu alatako ṣe pe aarẹ ti ilu sẹsẹ dibo yan, Bola Tinubu lẹjọ, ko ni se idaduro fun ibura rẹ, gẹgẹ bi aarẹ tuntun.
Akọwe agba fun ijọba apapọ, Boss Mustapha, lo kede bẹẹ nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ niluu Abuja.
Mustapha ni awọn ti gbe gbogbo igbesẹ to yẹ lati gbe agbara le Tinubu lọwọ to ba di ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu karun ọdun 2023.
Mustapha ni ipe awọn ẹgbẹ oṣelu alatako pe ki wọn wọgile eto idibo ti ajọ INEC kede, ko ni nnkan se pẹlu ijọba apapọ rara.
"Igbimọ ti aarẹ gbe kalẹ lati fa akoso le ijọba tuntun lọwọ ti fẹrẹ pari isẹ"
O tẹsiwaju pe, gbogbo igbimọ ti Aarẹ Muhammadu Buhari yan lo ti fẹ pari isẹ wọn lori bi agbara yoo se bọ sọwọ ijọba tuntun eyi ti Bola Tinubu fẹ lewaju gẹgẹ bi aarẹ orilẹede Naijiria.
Lọjọ kẹsan oṣu keji ọdun 2023 ni Aarẹ Muhammadu Buhari buwọlu yiyan awọn igbimọ ti yoo mojuto ati se agbatẹru bi agbara yoo se bọ sọwọ ijọba tuntun.
Lara awọn eekanlu to wa ninu igbimọ naa ni akọwe agba fun ijọba apapọ, Minisita fun eto idajọ ati awọn agbaagba miiran.
Ki ni awọn ẹgbẹ oṣelu alatako n beere fun?
Ẹgbẹ oṣelu Labour Party ati PDP ni wọn ti morile ileẹjọ lati tako esi ibo to gbe oludije sipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC, Bola Ahmed Tinubu wọle gẹgẹ bi aarẹ tuntun .
Awọn ẹgbẹ oṣelu naa fẹsun kan ajọ INEC ke wọn kọ lati gbe esi ibo sori ayelujara gẹgẹ wọn se se ileri saaju ibo aarẹ to kọja.
Ajọ INEC ni kudiẹkudiẹ de ba ẹrọ BVAS lasiko ti ibo n waye lo fa ti awọn ko fi gbe esi ibo naa sori ayelujara.
Ìdí rèé tí Tinubu fi wọgile àjọyọ̀ ọjọ́ ìbí rẹ̀, tó sì pè fún àkànṣe àdúrà

Oríṣun àwòrán, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu/Facebook
Bola Ahmed Tinubu, aarẹ tuntun tilu ṣẹṣẹ dibo yan ti kede pe ki akanse adura waye lati ṣe ayajọ ọjọ ibi rẹ dipo ipade apero to maa n waye lọjọ ibi rẹ.
Ọjọru ọsẹ yii ni Bola Tinubu yoo se ajọyọ ọjọ ibi ọdun kọkanlelaadọrin rẹ, o si ti ma n ṣe ipade apero lati sayajọ ọjọ ibi rẹ naa lọdọọdun.
Atẹjade ti Tunde Rahman fi lede lorukọ Bola Tinubu, ni adura ni yoo waye ni ilu Eko ati awọn agbegbe miran lorilẹede yi.
Rahman ni akanse adura naa yoo waye ni awọn Mọsalasi to wa ni ẹkun mararun nipinlẹ Eko ati ti apapọ to wa ni Alausa, Ikeja.
Lara awọn eeyan ti yoo peju sibi akanse adura naa ni Aarẹ Muhammadu Buhari, iyawo rẹ, Aisha Buhari, Bola Tinubu ati iyawo rẹ, Oluremi Tinubu.
Bakan naa ni igbakeji Aarẹ Kashim Shettima, iyawo rẹ, Nana Shettima, gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu, awọn gomina miran lati awọn ipinlẹ Orilẹede yii ati awọn asoju-sofin pẹlu awọn ọmọ ile igbimọ asofin jakejado orileede yii.
Ayẹyẹ ọjọ ibi Bola Tinubu lọdun yii bọ si igba ti awọn Musulumi jake jado agbaye n gba awẹ Ramadan.
Tinubu wa rọ awọn ọmọ Naijiria lati gbadura fun itọsọna Ọlọrun fun bi oun ti palẹmọ lati bẹrẹ isẹ gẹgẹ bi aarẹ tuntun fun orilẹede yii laipẹ.
A fẹ́ kí INEC sèwádìí àwọn gómìnà àti igbákeji wọn fún ìwà jàgídíjìgan lásìkò ìdìbò - SERAP

Oríṣun àwòrán, Others
Ajọ to n ja fun ẹtọ ọmọniyan, SERAP ti kesi alaga ajọ INEC lati ṣewadii iwa jagidijagan to waye lasiko idibo kaakiri lorilẹede Naijiria.
Ninu lẹta ti Serap kọ si alaga ajọ INEC, Ọjọgbọn Mahmood Yakubu lati gbe igbimọ kalẹ ni kiakia lati ṣewadii ni finifini awọn to wa nidi iwa ipa naa.
Serap ni ki INEC ṣewadii ẹsun magomago naa ti wọn fi kan awọn oṣiṣẹ wọn lasiko idibo naa.
Bakan naa lo ni iwadii ọhun yoo ṣafihan awọn to ṣe agbatẹru awọn to fa rogbodiyan lasiko idibo naa lai fi ti ẹgbẹ oṣelu kankan ṣe.
‘’Iwe ofin to de ajọ INEC ẹSẹ 52 FUN inec ni anfaani lati gbe igbimọ iwadii kalẹ lati ṣewadii iwa magomago lasiko idibo naa.
‘’Lara awọn ẹsun ti wọn fẹ ki wọn ṣewadii ni gbigba riba lọwọ awọn gomina ipinlẹ ati awọn igbakeji wọn.’’
Gẹgẹ bi ọrọ ajọ Serap, ki INEC ṣiṣẹ pọ pẹlu ajọ ICPC ati awọn ajọ agbofinro miran lati le fi ọwọ ofin mu ẹnikẹni to ba ṣe magomago lasiko idibo naa.
‘’Wọn gbọdọ wa wọn ri, ki wọn fi panpẹ ọba mu wọn, ki wọn ṣe iwadii wọn, ki wọn si fi idi otitọ mulẹ.’’
‘’Gbogbo awọn to ṣe magomago tabi iwa jagidijagan lasiko idibo gbogboogbo ni Naijiria gbọdọ foju wina ofin.’’
Gẹgẹ bi awọn ajọ onwoye idibo bii Centre for Democracy and Development ṣe fi lede pe ọpọlọpọ iwa ipa lo waye ni awọn ibudo idibo kan ni awọn ipinlẹ ni Naijiria, ti wọn ko si gba ki awọn miran tilẹ dibo rara.
Àìgbọràn ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ló fa ìjákulẹ̀ rẹ̀, Ìhà Gúúsù orílẹ̀èdè yìí nípò Aarẹ tọ́ sì - Fayose

Oríṣun àwòrán, AyodeleFayose/Facebook
Gomina ipinlẹ Ekiti nigba kan ri Ayodele Fayose ni ki awọn ọmọ orilẹede yi ye da ẹbi ru ajọ to se kokari eto idibo INEC mọ fun awọn rogbodiyan ati laasigbo to tẹle abajade esi idibo ọdun yii.
Ninu ifọrọwerọ to se pẹlu ile ise amohunmaworan Arise Tv, Fayose sọ taa lo jẹbi.
"Awọn oloṣelu orilẹede yii lo jẹbi iwa jagidijagan to ṣẹlẹ ninu eto idibo yii nitori ajọ INEC sa ipa rẹ lati rii wi pe eto idibo ọdun yii mu yanyan".
Fayose ni awọn oloṣelu to fẹ gba ipo oṣelu tipatipa lo da kun laasigbo to waye nitori ajọ INEC kọ ni ile iṣẹ ọlọpa ati ologun ti yoo koju awọn oni jagidijagan.
Gomina ipinlẹ Ekiti nigba kan ri ni gbogbo ọmọ orilẹede yii lo jẹbi nitori bi adari wa ti ri naa ni awọn ọmọlẹyin na rii.
O ni: "Ọpọ awọn janduku ri eto idibo gẹgẹ bi ọna ati ri owo eyi to faa ti awọn iwa ipa se pọ sii ninu awọn eto idibo wa".
Fayose ni lati ọdun 1979 ti oun ti gbọnju mọ nipa oselu Orilẹede yii ko tii si iyatọ kan kan.
Ki lo de too wa ni PDP too tun garuku ti Tinubu?
"Nitori ilana eto idibo to gbe e wọle, Aarẹ tuntun ti ilu dibo yan ninu ẹgbẹ oselu APC Bola Tinubu kun oju osunwọn".
Ọpọ eeyan lo ti n fi ero wọn han lati igba ti eto idibo ti bẹrẹ lori bi Fayose ko ṣe da si ọrọ ẹgbẹ oṣelu tirẹ amọ ti wọn pada rii ti ko fi pamọ pe Bola Tinubu ni oludije aayo oun.
Fayose ni nigba ti Wike ati ẹgbẹ G5 ti PDP sọ wi pe o yẹ ki ipo Aarẹ pada si apa Guusu Orilẹede yii awọn kan fapajanu ṣugbon esi eto idibo yii ti fihan pe ẹgbẹ G5 ko parọ.
Gomina tẹlẹri naa ni, inu ẹgbẹ oṣelu PDP ni Peter Obi to ni ibo milliọnu mẹfa o le ati Musa Kwankwaso to ni ibo milliọnu kan o le ti jade kuro, ti wọn ba fi apapọ ibo ti wọn ni kun ti Atiku dajudaju ẹgbẹ oselu PDP lo yẹ ki o jawe olubori.
Fayose ṣalaye pe niwọn igba to jẹ pe iha Guusu ni agbara kan, ki lo wa ku.
Ṣugbon awọn to wa ni isakoso ẹgbẹ oselu PDP lọwọlọwọ ko ṣiṣẹ fun idagbasoke ẹgbẹ oṣelu naa nitori ọpọ wọn lo ti ṣiṣẹ tako ẹgbẹ ninu eto idibo ọdun 2019.
Fayose ni ọna abayọ si ilana eto oṣelu tuntun ni Orilẹede yii ni ki awopalẹ wa latori aladari ati awọn ọmọlẹyin wọn, aiṣe bẹẹ ipaniyan nigba eto idibo yoo tẹsiwaju titi ayipada rere yoo fi wa.

















