Wo àpapọ̀ àwọn tó ti wọ́ Tinubu lọ ilẹ ẹjọ́ lọrí èsì ìbò Ààrẹ àti ẹ̀rí tí wọ́n kó wá

Bola Tinubu

Oríṣun àwòrán, @officialABAT

Eto idibo sipo Aarẹ orilẹede yii ti waye, ti ajọ INEC si kede Bola Ahmed Tinubu, gomina ipinlẹ Eko nigba kan ri gẹgẹ bi olubori lẹyin to bori pẹlu ibo to le ni milliọnu mẹjọ.

Atiku Abubakar ti ẹgbẹ oṣelu PDP ni ibo to to milliọnu mẹfa le diẹ, ti Peter Obi, ẹniti o ti figba kan ri jẹ gomina ipinlẹ Anambra ni ibo to le ni milliọnu mẹfa.

Ṣugbọn awọn awuyeye kọkan tẹle abajade esi idibo naa nibiti ẹgbe oṣelu mẹta ti wọ Bola Ahmed Tinubu lọ ile ẹjọ.

Awọn ẹgbẹ ọṣelu mẹtẹta naa ni ẹgbẹ oṣelu Labour, PDP, APM ati AA.

Ile isẹ BBC Yoruba ti jabọ ṣaaju pe Peter Obi ti pe ẹjọ tako esi ibo to gbe Tinubu wọle gẹgẹ bii Aarẹ Naijiria ti awọn araalu dibo yan.

Ẹjọ ọhun, to ni nọmba CA/PEPC/03/2023, ni Obi pe tako INEC, Tinubu, Kashim Shettima ati ẹgbẹ oṣelu APC.

Bakan naa ni ẹgbẹ oṣelu PDP pe INEC, Tinubu Bola Ahmed ati ẹgbẹ oṣelu APC lẹjọ.

Livy Ozoukwu to dari igbẹjo Peter Obi ni lara awọn ẹsun ti wọn fi kan Bola Tinubu ni wi pe wọn ti ni ko san owo itanran to to ẹgbẹrun lọna ọgọtalelẹnrinwo dọla fun ẹsun to nii ṣee pẹlu egbo igi oloro nilu Amerika pẹlu nomba 93C 4483 ti ile ẹjọ iha ariwa Illinois.

Obi tun ni oun lo ye ki ajọ INEC kede gẹgẹ bi Aarẹ nitori ibo oun lo pọju, to si rọ ajọ INEC lati fun oun ni iwe ẹri gẹgẹ bii ẹniti o jawe olubori.

AWORAN IWE IPẸJỌ

Oríṣun àwòrán, Others

Peter Obi tun ni eto idibo naa ko tẹle alasilẹ ofin to wa fun eto idibo gẹgẹ bo ti wa ninu ofin eto idibo orilẹ-ede yii ti ọdun 2022.

O rọ ile ẹjọ lati ri akojọpọ ibo ti Tinubu ni gẹgẹ bi eyi ti ko ja mọ nnkankan nitori Tinubu ati Shettima ko kun oju oṣuwọn lati dije dupo Aarẹ.

O rọ ile ẹjọ lati ṣeto idibo miiran laisi ẹgbẹ oselu APC tabi Tinubu, Shettima lara awọn ti yoo dije dupo Aarẹ.

Ẹgbẹ oselu AA (Action Alliance) ninu ipẹjo rẹ ni eto idibo Aarẹ ọdun yii ko kẹsẹjari nitori ko si orukọ oludije ẹgbẹ naa, Solomon Okannigbua lara awọn to dije dupo Aarẹ.

Ẹgbẹ oṣelu APM (Allied Peoples Movement ) ninu iwe ipẹjọ rẹ ni abajade esi idibo Aarẹ ọdun yii ko kajuẹ nitori o lodi si alakalẹ ofin.

Ofin orilẹede yii faye gba ki awọn oludije tabi ẹgbẹ oselu pe ẹjọ ti esi ibo naa ko ba tẹ wọn lọrun.

Ipẹjọ naa si gbọdọ waye laarin ọjọ mọkanlelogun ti idibo ọhun ba pari.