Dapo Abiodun fìdí Ladi Adebutu àti Biyi Otegbeye janlẹ̀, ó wọlé sáà kejì
Gomina ipinlẹ Ogun, Dapo Abiodun ti jawe olubori ninu ibo gomina to waye lọjọ Abamẹta.
Abiodun wọle fun saa keji lẹyin to ni iye ibo to pọju ninu idibo gomina naa gẹgẹ bii ajọ INEC ṣe kede.

Oríṣun àwòrán, @dabiodunMFR
Ninu ijọba ibilẹ ogun to wa nipinlẹ ọhun, APC ni mejila, nigba ti PDP ni mẹjọ.
Apapọ iye ibo to gbe Abiodun wọle jẹ 276,298.
Bi esi awọn ijọba ibilẹ ṣe wọle ree:
ODEDA LGA
APC: 11,089
PDP: 8,050
NNPP: 31
ADC: 3,65
EGBADO NORTH LGA
APC: 15,331
PDP: 11,627
NNPP: 64
ADC: 12,190
EGBADO SOUTH LG
APC: 15,047
PDP: 10,913
NNPP: 75
ADC: 6,435
EWEKORO LG
APC: 8,192
PDP: 7,449
NNPP: 60
ADC: 3,881
ABEOKUTA SOUTH LG
APC: 19,689
PDP: 24,175
NNPP: 99
ADC: 9,264
IJEBU NORTH LG
APC: 18,815
PDP: 15,904
NNPP: 22
ADC: 2,393
IKENNE LG
APC: 9,125
PDP: 12,472
NNPP: 09
ADC: 336
IJEBU NORTH-EAST LG
APC: 5,408
PDP: 7,086
NNPP: 27
ADC: 1,448
IJEBU-ODE LG
APC: 12,907
PDP: 10,714
NNPP: 36
ADC: 1,348
ABEOKUTA NORTH
APC: 14,294
PDP: 12,622
NNPP: 34
ADC: 9,143
IJEBU EAST LG
APC: 7,883
PDP: 11,242
NNPP: 45
ADC: 1,885
REMO NORTH LG
APC: 4,306
PDP: 8,177
NNPP: 06
ADC: 327
IPOKIA LG
APC: 21,338
PDP: 19,189
NNPP: 46
ADC: 1,897
ODOGBOLU LG
APC: 9,143
PDP: 12,963
NNPP: 10
ADC: 1,281
OGUN WATERSIDE LG
APC: 5,878
PDP: 7,716
NNPP: 56
ADC: 2,575
IMEKO AFON LG
APC: 9,591
PDP: 6,981
NNPP: 93
ADC: 6,124
ADO-ODO OTA LG
APC: 39,006
PDP: 31,022
NNPP: 194
ADC: 12,174
OBAFEMI OWODE LG
APC: 15,466
PDP: 11,004
NNPP: 275
ADC: 5,105
IFO
APC: 20,653
PDP: 16,052
NNPP: 154
ADC: 11,040
ṢAGAMU
APC: 13,128
PDP: 17,025
NNPP: 58
ADC: 2,257
Mọ̀ nípa Dapo Abiodun, Ladi Adebutu, Biyi Otegbeye; mẹ́ta nínú àwọn olùdíje ipò gómìnà nípínlẹ̀ Ogun

Oríṣun àwòrán, LadiAdebutu/ Dapo Abiodun, Biyi Otegbeye/twitter/other
Eto idibo gomina ni Naijiria ku ọjọ perete, gbogbo eto lo ti to, awọn araalu si ti ṣetan lati lọ dibo.
Lara awọn ipinlẹ ti yoo maa kopa ninu idibo gomina yii ni ipinlẹ Ogun wa.
Eyi ni agbeyẹwo itan ati iri mẹta gboogi ninu awọn oludije to n dije fun ipo gomina ni ipinlẹ Ogun lasiko idibo ti yoo waye lọjọ kọkanla oṣu kẹta ọdun 2023.
Gomina Adedapọ Abiọdun, MFR (Ẹgbẹ oṣelu APC)
Ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu keji ọdun 1960 ni wọn bi Ọmọọba Adedapọ Oluṣeun Abiọdun MFR ni ilu Ipẹru Rẹmọ, ni ijọba ibilẹ Ikẹnẹ ni ipinlẹ Ogun.
O lọsi ile ẹkọ girama Christ’s School Ado Ekiti lọdun 1972 ati ile ẹkọ girama St. Joseph’s College, nilu Ondo lọdun 1977 ati Ondo High School lọdun 1978.
Nitoripe olukọ ni awọn obi rẹ, eyi lo mu ki eto ẹkọ rẹ maa kaakiri gẹgẹ bi iṣẹ ṣe n gbe awọn obi rẹ kiri.
Lẹyin eyi lo wa lọ si ile ẹkọ giga fasiti Ifẹ ti o ti di Ọbafẹmi Awolọwọ University bayi nilu Ile Ifẹ ni ipinlẹ Ọṣun nibi to ti kẹkọọ gba oye imọ ijinlẹ ninu imọ ẹrọ Civil Engineering ki o to wa lọ si ileẹkọ giga fasiti Kennesaw State University nilu Atlanta ni ipinlẹ Georgia lorilẹede Amẹrika nibi ti o ti kẹkọ gboye ijinlẹ ninu iṣiro owo lọdun 1986.

Oríṣun àwòrán, Dapo Abiodun/twitter
Ọdun 1998 ni Dapọ Abiọdun kọkọ bẹrẹ irinajo rẹ sinu oṣelu nigba to wọle gẹgẹ bi sẹnetọ ni ẹkun idibo apapọ Ogun East Senatorial labẹ ẹgbẹ oṣelu United Nigeria Congress Party, UNCP lasiko ijọba ologun nigba naa ki bi nnkan ṣe n lọ lagbo iṣejọba nigba naa to mu ki wọn wọgile eto idibo ọhun.
Lẹyin eyi lo darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu PDP lọdun 1999, o dije lati di aṣia oludije ẹgbẹ oṣelu PDP fun ipo gomina ni ipinlẹ Ogun lọdun 2002 ṣugbn ko bọ sii fun un.
Lẹyin eyi lo darapọ mọ APC lati dije fun di aṣia oludije ẹgbẹ oṣelu naa fun ipo Sẹnetọ ẹkun ogun east ṣugbọn o lulẹ ki o to wa ri ipo gomina mu lọdun 2028 labẹ oṣelu APC kan naa.
Gomina Dapọ Abiọdun bori pẹlu ibo 241, 670 lati di gomina, Adekunle Akinlade ti Allied Peopls Movement, APM lo tẹ lee pẹlu ibo 222, 153.
Oloye Ladi Adebutu (Ẹgbẹ oṣelu PDP)

Oríṣun àwòrán, LadiAdebutu/ twitter
Ọgbẹni Ladi Adebutu ni oludije fun ipo gomina lẹgbẹ oṣelu PDP ni ipinlẹ Ogun
Ladi Adebutu kii ṣe ọjẹ wẹwẹ tabi majeṣin ninu ọrọ oṣelu nitori pe o ti le ni ọgbọn ọdun ti o ti n wẹ ninu agbami oṣelu.
Lọdun 1992 lo di ọmọ ile igbimọ aṣofin apapọ Naijiria labẹ ẹgbẹ Social Democratic Party, SDP lati ṣoju ẹkun apapọ Rẹmọ ni ile igbimọ aṣojuṣofin.
O dije fun ijoko ile aṣofian agba labẹ ẹgbẹ oṣelu UNCP lọdun 1998.
Bakan naa lo dije fun ipo aṣofin apapọ lọdun 2003, 2007 ati 2011 labẹ aṣia ẹgbẹ oṣelu PDP.
Lọdun 2015, o wọle gẹgẹbi aṣojuṣofin fun ẹkun apapọ Rẹmọ (ijọba ibilẹ Sagamu, Ikenne ati ariwa Rẹmọ)
Ni ọjọ karundinlọgbọn oṣu karun un ọdun 2022 ni wọn yan an gẹgẹ bi oludije fun ipo gomina nipinlẹ Ogun fun ẹgẹ oṣelu PDP.
Oniruuru oye lo ti jẹ diẹ ninu eyi ti a ti ri Lisa-Aje Egba, Lisa-Aje Ota Awori, Okanlomo ilu Iperu-Remo , Aruwajoye ti Ode Remo, Otun Ajagungbade ti ilu Remọ ati bẹẹbẹẹ lọ.
Ọgbẹni Biyi Ọtẹgbẹyẹ (Ẹgbẹ oṣelu ADC)

Oríṣun àwòrán, other
Amofin ni Ọgbẹni Ọtẹgbẹyẹ, oun si ni adari agba ileeṣẹ Regency Alliance Plc.
Ilẹ ẹkọ alakọbẹrẹ Christ Church School, nilu Ijẹbu Ode lo ti bẹrẹ ẹkọ rẹ ki o to lọ si ile ẹkọ girama Comprehensive High School, Aiyetoro ati ile ẹkọ girama CMS Grammar School Bariga.
O kẹkọ gboye imọ akọkọ nipa eto idojutofo lati ile ẹkọ fasiti ilu Eko lọdun 1984 ki o to lọ kẹkọ gboye ijinlẹ keji MBA lori imọ nipa akoso iṣuna ati iṣiro owo lọdun 1987.
Bakan naa lo tun kẹkọ gboye imọ ofinni fasiti ipinlẹ Eko, LASU lọdun 2001 ti wọn si fi orukọ rẹ silẹ gẹgẹ bi agbẹjọro nile ẹjọ to ga julọ ni Naijiria lọdun 2003.
Ọgbẹni Ọtẹgbẹyẹ̀ bẹrẹ iṣẹ rẹ lẹka idojutofo ni ileeṣẹ adojutofo United Nigeria insurance Company Limited (UNIC) lọdun 1986














