Ohun tó yẹ kóo mọ̀ nípa Sanwo-Olu, Jandor ati Rhodes-Vivour; Olùdíjé mẹ́ta tó ń du adé gómìnà l'Eko

Sanwo-Olu, GRV and Jandor

Oríṣun àwòrán, Twitter

    • Author, Olumide Owaduge
    • Role, Akọroyin BBC

Ni bayii ti eto idibo gomina ni Naijiria ku ọjọ perete, gbogbo eto lo ti to, awọn araalu si ti ṣetan lati lọ dibo.

Bi awọn gomina kan ṣe n du ipo naa fun saa keji, lawọn mii n tun ipo ọhun du lẹyin ti wọn ti kọkọ lulẹ ninu awọn igbiyanju wọn atẹyinwa.

Lara ipinlẹ ti eto idibo gomina naa yoo ti waye nilẹ Yoruba ni Eko, Ogun ati Oyo.

Nipinlẹ Eko, BBC ṣe akojọpọ awọn ohun to yẹ ki o mọ nipa awọn oludije mẹta akọkọ to n du ipo ọhun ti ọrọ si pọ lori wọn lẹnu awọn ololufẹ wọn.

Awọn oludije naa ni Babajide Sanwo-Olu, Abdul-Azeez Olajide Adediran ti ọpọ mọ si Jandor ati Gbadebo Rhodes-Vivour, GRV.

Babajide Sanwo-Olu, APC

Jide Sanwo-Olu

Oríṣun àwòrán, @jidesanwoolu

Babajide Sanwo-Olu ni gomina ipinlẹ Eko lati ọdun 2019, o si n du ipo naa fun igba keji.

Wọn bi Sanwo-Olu lọjọ karundinlọgbọn, oṣu Kẹfa, ọdun 1965, niluu Eko, eyii to mu ko jẹ ẹni ọdun mẹtadinlọgọta bayii.

O kẹkọọ nile ẹkọ Government Demonstration School, Gbaja, Surulere, ko to lọ si Ijebu-Ife Grammar School, nipinlẹ Ogun.

Lati ibẹ lọ, o kẹkọọ gboye ni fasiti ilu Eko, University of Lagos, o tun kẹkọọ lawọn ile ẹkọ mii bii John F. Kennedy School of Government, London Business School ati Lagos Business School.

Sanwo-Olu jẹ ọmọ ẹgbẹ Chartered Institute of Personnel Management, CIPM, ati Nigeria Institute of Training and Development, NITAD.

O ṣiṣẹ nile ifowopamọ Lead Merchant Bank laari ọdun 1994 si 1997 ko to lọ si UBA ati FCMB.

Jide Sanwo-Olu

Oríṣun àwòrán, @jidesanwoolu

Ọdun 2003 ni Sanwo-Olu bẹrẹ eto ọṣelu, asiko naa lo ṣiṣẹ gẹgẹ bii olubadamọran pataki si gomina Femi Pedro ko to di kọmiṣọna.

O ṣiṣẹ lawọn ẹka ijọba gẹgẹ bii oloṣelu labẹ gomina to ṣaaju rẹ, iyẹn Akinwunmi Ambode.

Lọdun 2018, o kede pe oun fẹ dije du ipo gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC, lati gbena woju gomina Ambode, o si bori ninu eto dibo naa.

Sanwo-Olu ṣe ọpọlọpọ aṣeyọri gẹgẹ oloṣelu labẹ itọni baba isalẹ rẹ, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu, ti oun naa ti ṣe gomina ipinlẹ Eko ri.

Jide Sanwo-Olu

Oríṣun àwòrán, @jidesanwoolu

Ibaṣẹpọ Sanwo-Olu ati Tinubu pọ to bẹẹ ti ọpọ eeyan fi n juwe rẹ bii ọmọ ọdọ agba oloṣelu naa ni gbogbo ibi to ti lọ ṣe ipolongo ibo Aarẹ.

Lara awọn aṣeyọri Sanwo-Olu nipinlẹ Eko ni ṣiṣi oju ọna BRT Oshodi-Abule Egba, ọna oju irin Blue Line Rail, atunṣe awọn ile ẹkọ, ile iwosan, ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Aṣiṣe Sanwo-Olu pọ gẹgẹ bii gomina ipinlẹ Eko amọ eyii to milẹ titi julọ ni ọwọ to fi mu iwọde EndSARS lọdun 2020 ati iṣekupani awọn oluwọde naa ni Lekki Toll Gate, iṣẹlẹ EndSARS naa ti mu ki ọpọ awọn ọdọ niluu Eko sọ pe awọn ko ni dibo fun un.

Abdul-Azeez Olajide Adediran, PDP

Jandor

Oríṣun àwòrán, @officialjandor

Orukọ inagujẹ ni Abdul-Azeez Olajide Adediran ni Jandor, o si jẹ oloṣelu, akọroyin ati oniṣowo.

Oun ni ọmọ karun un ninu awọn meje ti awọn obi rẹ bi ni Mushin.

Jandor ni alaga eto “Laghos4lagos” ati oludije sipo gomina labẹ aisa ẹgbẹ oṣelu PDP.

Ẹni to n dije pẹlu jandọr gẹgẹ bii igbakeji rẹ ni gbajumọ oṣere tiata Yoruba, Funke Akindele, ti ọpọ mọ si Jenifa.

Jandor

Oríṣun àwòrán, @officialjandor

Wọn bi Jandor sinu idile Alhaji Adeniran ati iya aafin Mrs Ruth Oluwafunmilayo Adeniran lọjọ karundinlọgbọn, oṣu Kọnkanla, ọdun 1977, lagbegbe Mushin, niluu Eko.

Jandor kekọọ jade nile ẹkọ gbogbonisẹ ilu Ibadan, Ibadan Poly, o tun kẹkọọ siwaju si nilẹ Amẹrika, iyẹn ni Howard University School of Business, Washington DC, ati fasiti Oxford, nilẹ Gẹẹsi.

O jẹ ọkan lara awọn ọmọ ẹgbẹ Nigerian Institute of Public Relations (NIPR); Advertising Practitioners Council of Nigeria (APCON); Nigeria Union of Journalist (NUJ); ati Broadcasting Organization of Nigeria (BON).

Oun ni ọga agba ileeṣẹ Core Media Group, ti awọn ileeṣẹ mii bii CoreTvNews wa labẹ rẹ.

Jandor

Oríṣun àwòrán, @officialjandor

Jandor naa tun ni alaga ileeṣẹ Datanet Project Services, ileeṣẹ The Floral Consult, oun lo ni ileeṣẹ Core-Bet, to jẹ ileeṣẹ tẹtẹ, ati ajọ kan ti kii ṣe ti ijọba, Jandor Foundation.

O ṣiṣẹ gẹgẹ bii akọroyin fun nnkan bii ọdun mejila ko to wọ inu eto oṣelu gẹgẹ bii ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC.

Amọ jandor kuro ninu ẹgbẹ oṣelu APC lọ so PDP nibi to ti n dije du ipo gomina.

Orukọ iyawo rẹ ni Maryam, wọn si bi ọmọ meji.

Gbadebo Rhodes-Vivour

GRV

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Gbadebo Rhodes-Vivour ti ọpọ mọ si GRV ni oludije sipo gomina ipinlẹ Eko labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Labour.

Wọn bi Rhodes-Vivour lọjọ kẹjọ, oṣu Kẹta, ọdun 1983 ni Lagos Island, nipinlẹ Eko.

Orukọ baba rẹ ni Olawale Rhodes-Vivour, nigba ti iya rẹ n jẹ Nkechi Rhodes-Vivour.

O kẹkọọ gboye ni fasiti ilu Eko, UNILAG, University of Nottingham nilẹ Gẹẹsi ati Massachusetts Institute of Technology, MIT, nilẹ Amẹrika.

Ajafẹtọm ọmọniyan ni GRV, o tun jẹ oniṣowo, onwoye ohun to n lọ lawujọ, ayaworan ile ati oloṣelu.

Oun lo ṣagbatẹru eto Nigerians Against GMOs(NAG), o tun n lewaju awọn to n pe fun ẹkọ nipa itan lawọn ile ẹkọ ni Naijiria.

O ṣiṣẹ pẹlu ileeṣẹ Consultants Collaborative Partnership (CCP) ati Patrick Waheed Consultants ko to da ileeṣẹ ara rẹ silẹ.

GRV

Oríṣun àwòrán, @GRVlagos

Oun lo da Spatial Tectonics silẹ, o si wa lara awọn oludari ileeṣẹ Alhuda Construction Nigeria ati Delta International Commercial City Ltd.

O wọ inu eto oṣelu lọdun 2007 lasiko to dije fun ipo alaga ijọba ibilẹ Ikeja labẹ asaia ẹgbẹ oṣelu KOWA.

Lọdun 2019, o dije du ipo aṣofin agba lati ṣoju ẹkun iwọ oorun ipinlẹ Eko nile igbimọ aṣofin agba labẹ aisa ẹgbẹ oṣelu PDP, amọ o lulẹ.

Lọjọ kẹwaa, oṣu Kẹjọ, ọdun 2022, o jawe olubori gẹgẹ bii ẹni ti yoo dije du ipo gomina labẹ aisa ẹgbẹ oṣelu Labour lẹyin to kọ ẹgbẹ oṣelu PDP silẹ.

Orukọ iyawo rẹ ni Ify Rhodes-Vivour, to jẹ ọmọ gomina ologun ipinlẹ Kogi ati Bornu nigba kan ri, Augustine Aniebo.

GRV

Oríṣun àwòrán, @GRVlagos

Okiki GRV bẹrẹ si n kan gidi lẹyin eto idibo Aarẹ to waye lọjọ karundinlọgbọn, oṣu keji ọdun yii, nibi ti Bola Tinubu ti lulẹ nipilẹ Eko.

Lẹyin eto idibo ọhun lawọn eeyan bẹrẹ si n jẹ ọrọ GRV lẹnu loju opo Twitter pe Sanwo-Olu gbọgọ lulẹ gẹgẹ bi baba isalẹ rẹ, Tinubu ṣe lulẹ nipinlẹ Eko.

Amọ ṣa, bo tilẹ jẹ pe ọpọ eeyan lo n ṣatilẹyin fun GRV loju opo Twitter, ọpọ awọn mii lo n tako latari pem iran ẹya Igbo lo ti wa.

Awọn kan tilẹ ti n wu awọn ẹri kan jade pe kii ṣe ojulowo ọmọ Yoruba, latari itan iran rẹ, orukọ rẹ ati pe ede Yoruba ko dan mọran lẹnu rẹ.

Lara awọn ọdọ to n gbe ọrọ GRV lori lori ayelujara ni Debo Adebowale, ti ọpọ mọ si Mr Macaroni.