Wo ohun tí a mọ nípa olóògbé Fadeyi Oloro

Oríṣun àwòrán, Others
Gbajugbaja oṣere tiata Ojo Arowosafe, ti ọpọ mọ si Fadeyi Oloro ni o jade laye lẹni ọdun mẹrindinlaadọrun lẹyin to aisa ọlọjọ pipẹ finra
Osere naa jade laye lọjọ Isẹgun, ti awọn ọrẹ ati mọlẹbi si ti fi idi isẹlẹ naa mulẹ.
Ṣugbọn awọn nkankan wa ti ọpọ eeyan ko mọ nipa osere tiata naa, ti a si ti ṣe akọjọpọ rẹ:
"Gbogbo ohun ti mo mọ ninu ere tiata, mo kọ ara mi ni"
Fadeyi Oloro lo jẹ oṣere kan to jẹ Akọni ninu ere sinima ile Yoruba.
Pupọ awọn eeyan to maa n kopa nine ere bayii ni wọn nilo olukọ lati tọ wọn sọna bi wọn yoo ṣe kopa ninu ere sugbọn eyi ko ri bẹẹ lọdọ Arowosafe, nitori pupọ awọn nnkan to mọ to si lo lọ jẹ ohun to da fun ara rẹ.
Ninu ifọrọwerọ kan to ṣe, o ni Ọlọrun lo fun oun ni ẹbun fun gbogbo nnkan ti oun n ṣe ati pe ati kekere ni oun ti bẹrẹ lati maa ṣee.
Ko mọ iya to bi i lọmọ
Iya Fadeyi Oloro jade laye lasiko to wa ni ọmọ ikoko, ti ko si da iya naa mọ rara ṣugbọn o ni oun gbe pẹlu baba oun.
Pẹlu omije ni Fadeyi fi ṣalaye irinajo igbesi aye rẹ lai ni iya laye.
Pasitọ ni Fadeyi Oloro
Pẹlu gbogbo ipa to maa n ko ninu ere sinima, onigbagbọ ododo ni Fadeyi Oloro, to si tun jẹ Pasitọ ile ijọsin.
O ni ipa ti oun ko ninu ere sinima ko tun mọ si pe oun jẹ ẹni buruku.
O ni ọlọyaya eniyan ni oun ti oun si ko gbogbo eniyan mọra.
Fadeyi sọ ọpọlọpọ ọrọ nigba ti ile iṣẹ BBC Yoruba kan si i fun ifọrọwanilẹnuwo.
"Ko gbọdọ ku"
Fadeyi Oloro ni erongba lati ṣe ere sinima rẹ tuntun, eyi to pe akọle rẹ ni "Ko gbọdọ ku".
Ninu ifọrọwerọ to se pẹlu ileeṣẹ BBC News Yoruba, o ni ọpọ eeyan lo ti pe oun lati kopa ninu ere sinima ṣugbọn oun ja wọn kulẹ nitori oun ni pe oun gbọdọ gbe sinima toun jade ki oun to kopa ninu omiran.
O ni sinima naa ti pari ṣugbọn o nilo owo lati gbe e jade.
O bẹ awọn ọmọ Naijiria fun iranlọwọ
Lasiko ti aisan naa gbe pẹli sii lara, Fadeyi Oloro rawọ ẹbẹ si awọn ọmọ Naijiria lati ṣe iranlọwọ fun un ti Pasitọ ọmọ Naijiria kan to n fi ilẹ Gẹẹsi ṣebugbe, Tobi Adegboyega, si ṣeranwọ owo miliọnu mẹta naira fun un agba oṣere tiata naa.
Adegboyega, to jẹ pasitọ ijọ Salvation Proclaimers Anointed Church to wa niluu London gbe igbesẹ naa lasiko ifọrọwerọ kan pẹlu Fadeyi Oloro loju opo ikansiraẹni agbohunsafẹfẹ, Daddy Freeze.
Eyi ko ṣẹyin aisan ọlọjọ pipẹ to ti n ba agba oṣere naa finran fun nnkan bii ọdun mẹta, ati bi wọn ṣe le kuro ninu ile to n gbe.
Lasiko ifọrọwerọ ọhun to waye loju opo Instagram Daddy Freeze ni Fadeyi Oloro ti rawọ ẹbẹ fun iranlọwọ ki pasitọ Adegboyega to darapọ mọ wọn.
Gẹgẹ bii ohun ti Adegboyega sọ, o ni o ti pẹ ti oun ti mọ Fadeyi Oloro, o si jẹ ọkan lara awọn oṣere ti oun ranti daadaa lasiko ti oun n dagba.
Gbajúgbajà òṣèré tíátà, Fadeyi Oloro jáde láyé lẹ̀yìn àìsàn tó bá a fínra

Oríṣun àwòrán, Others
Tigbo tiju pa lọlọọọ! Ajanaku sun bi oke, Fadeyi olori ti re'bi agba n re!
Ariwo sọ lori ayelujara lalẹ ati oru mọjumọ oni, gẹgẹ bi gbajugbaja oṣere tiata, Ojo Arowosafe, ti ọpọ mọ si Fadeyi Oloro ṣe jade laye lẹyin aisan ọlọjọ pipẹ.
Aisan naa ṣee fun bii ọdun mẹta eyi to sọ ọ di ero ile wosan.
Fadeyi Oloro lo jade laye lọjọ Isẹgun lẹyin ti kidirin rẹ juwọ silẹ.
Iroyin sọ pe ọmọ rẹ fi aridaju eyi han fun awọn oniroyin bẹẹ si ni awọn akẹgbẹ rẹ naa ti bẹrẹ si ni fi sita lori ayelujara.
Ko to ku, Fadeyi Oloro rawọ ẹbẹ si awọn ọmọ orilẹede Naijiria pe ki wọn ran oun lọwọ lori ọro ti yoo fi ṣe itọju ara rẹ ni ile wosan.
Isẹlẹ yii waye lẹyin ọsẹ mẹta ti Pasitọ kan lati London, Tunde Adeboyega fun un ni miliọnu mẹta lẹyin ti o ṣalabapade fidio rẹ lori ayelujara.
Saaju ko to ku, Fadeyi Oloro, ẹni to n mi gunle-gunle lati sọrọ sita ninu fidio kan, lo foju han pe o nira fun-un lati sọrọ ja soke.
O tẹsiwaju pe "Nigba ti aisan buruku naa de, n ko mọ nnkan to sẹlẹ, o kan dede ki mi ni, mo dẹ sare si, mo wo gbogbo agọ ara mi sugbọn gbogbo rẹ lo ye Ọlọrun.
"Mo ti kọ ọpọ awọn itan silẹ lati fi ṣe sinima sugbọn n ko le ṣe.
"Kekere ni ẹ pe aisan yii ni, to fi di pe wọn bẹrẹ si ni maa ta dukia lemi lori sugbọn gbogbo rẹ lo ye Ọlọrun.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post
















