Orúkọ àwọn Sẹnétọ̀ tí wọ́n dìbò yàn ti jádè o! Àwọn tí INEC fi síta rèé àti ẹgbẹ́ òṣèlú tó pọ̀jù

Ajọ eleto idibo

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Ajọ eleto idibo Naijiria (INEC) ti gbe atẹjade orukọ awọn sẹnetọ to yoo ṣiṣẹ gẹgẹ bi aṣofin fun ọdun 2023 jade.

Eyi waye lẹyin idibo to waye lorilẹede Naijiria ni Ọjọ Abamẹta Ọjọ Kẹẹdọgbọn Oṣu Keji Ọdun 2023.

Ninu gbogbo ipo gọrun o le mẹsan to wa, mẹjọ ṣi wa lofo nitori iku kan lara wọn to waye ati pe tori afikun idibo ti yoo waye ni awọn ẹkun idibo meje.

ẹgbẹ oṣelu APC ni ẹgbẹ to gba ipo to pọju pẹlu ipo mẹrinlelaadọta nigba ti ẹgbẹ oṣelu PDP gba ipo mẹtalelọgbọn ti LP si gba meje toku.

Alaga ajọ eleto idibo naa, Mahmud Yakubu nigba to n ṣe ipade pẹlu awọn alaga ajọ naa ni ibIlẹ eyi to waye ni ilu Abuja sọ pe ẹgbẹ oṣelu mẹjọ pere lo pese gbogbo awọn aṣofin to wọle lasiko idibo naa.

Awọn ẹgbẹ ọhun ni: All Progressives Congress (APC), Peoples Democratic Party (PDP), All Progressives Grand Alliance (APGA), Social Democratic Party (SDP), Labour Party (LP), New Nigeria Peoples Party (NNPP) African Democratic Party (ADC) Young People Party (YPP).

Alakalẹ ti INEC ṣe nipa awọn to jawe olubori ni ipinlẹ kọọkan ree

Orukọ awọn Sẹnetọ

Oríṣun àwòrán, INEC

Orukọ awọn Sẹnetọ

Oríṣun àwòrán, INEC

Orukọ awọn Sẹnetọ

Oríṣun àwòrán, INEC

Orukọ awọn Sẹnetọ

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Ki lo wa niwaju wọn?

Ọkan lara awọn to gba iwe ẹri

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Sẹneeti ni ile igbimọ aṣofin agba ni Naijiria. Apapọ awọn aṣofin ni Naijiria ni wọn saba maa n pe ni National Assemby (NASS), ohun ẹka aṣofin to ga julọ to si ni agbara lati ṣe ofin ni Naijiria.

Awọn ipinlẹ mẹrinlelọgbọn to wa ni Naijiria ni aṣoju mẹta mẹta to fi mọ olu ilu orilẹede yii, Abuja to ni ibujoko kan nile igbimọ aṣofin agba.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Awọn aṣofin ti wọn dibo yan yii ni yoo jẹ ọmọ ile igbimọ aṣofin Kẹwa lẹyin ti wọn ba ṣe iburawọle fun wọn ni Oṣu Kẹfa.

Pẹlu ipo mẹrinlelaadọta ti ẹgbẹ oṣelu APC to wa lori alefa ti gba, amọ wn ko rii ṣe bẹẹ nile igbimọ aṣoju-ṣofin.

Bẹẹ si ni ẹgbẹ Oṣelu kan nilo lati ni to eeyan Ọgọsan lati sọ ara wọn di ẹgbẹ to pọju.

Ọgbẹni Yakubu ni wọn yoo ṣe afikun idibo ni awọn ijọba ibilẹ mẹrindinlaadọta lati jẹ ki iye awọn aṣofin to yẹ ko wa nile igbimọ aṣofin pe perepere bo tilẹ jẹ pe ko ti dajọ sii.

Bakan naa ni wọn fun awọn Sẹnetọ naa ni iwe ẹri mo yege lonii nilu Abuja nigba ti awọn ti ile igbimọ aṣoju-ṣofin yoo tẹwọ gba iwe ẹri ti wọn ni ọjọ Kẹjọ Oṣu Kẹta.

Lọjọ kan naa ti idibo aarẹ waye ni ti ile aṣofin naa waye. Bola Tinubu ti ẹgbẹ oṣelu APC lo bori ibo aarẹ nigba ti Atiku Abubakar ti ẹgbẹ oẹlu PDP gba ipo keji ti Peter Obi ti ẹgbẹ Oṣelu LP si gba ipo Kẹta. Rabiu Kwankwaso ti ẹgbẹ oṣelu NNPP gba ipo Kẹrin ninu idibo naa.

INEC ti kede Tinubu ati igbakeji rẹ, Kashim Shettima ti wọn si ti gba iwe ẹri mo yege bo tilẹ jẹ pe awọn ẹgbẹ oṣelu alatako ti leri lati gba ile ẹjọ lọ tako esi idibo to gbe Tinubu wọlẹ.