Àwọn ohun tó ti ṣẹlẹ̀ láti ìgbà tí wọ́n kéde Bola Tinubu gẹ́gẹ́ bíi ààrẹ

Oríṣun àwòrán, inec/twitter
Ọpọlọpọ awuyewuye lo ti n waye lẹyin idibo sipo aarẹ to waye lorilẹede Naijiria lọjọ karundinlọgbọn oṣu keji ọdun 2023.
Awọn ẹgbẹ alatako n fi apa janu pe awọn ko faramọ esi ibo naa ti wọn si ti gba ile ẹjọ lọ lati tako o.
Bọla Ahmed Tinubu to bori idibo naa ti gba iwe ẹri aṣeyege rẹ, to si ti ṣèlérí lati ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn ti ko dibo fun un, lọjọ kọkandinlọgbọn oṣu karun un si ni wọn yoo ṣe ibura fun un.
Tinubu gba iwe ẹri, o seleri lati gbe Naijiria dìde

Oríṣun àwòrán, TWITTER/@OFFICIALBAT
Ninu ọrọ àkọsọ rẹ, Tinubu ṣe ileri fun Awọn ọmọ Naijiria pe iṣejọba oun yoo mu alaafia, iṣọkan ati igbayegbadun wa fun mutumuwa, ati pe nigba tawon ọmọ Naijiria ba ri ohun ti iṣejọba oun ba gbe ṣe yoo jẹ ohun ayọ fun wọn lati jẹ ọmọ orilẹede Naijiria.
O ni oun ko ni ṣegbe fun ẹnikẹni, oun yoo si rii daju pe gbogbo ọmọ Naijiria janfani talẹnti wọn.
Bakanna lọ na ọwọ ifẹ sí awọn oludije yooku oa asiko oṣelu ti tan, asiko ati pawọpọ gbe Naijiria goke lo kan bayii.
“asiko itaporogan oṣelu ti pari bayii, asiko oṣelu alaafia ati iṣejọ gbogbogboo.
“ Lasiko idibo yii, ẹ le jẹ alatako mi ṣugbọn ẹ kii ṣe ọta mi. lọkan mi, ọmọ iya ni wa.”

Oríṣun àwòrán, tinubu/ twitter
Awọn adari orilẹede agbaye ki Tinubu ku oriire
Bi awọn alatako ṣe n fi apa janu, awọn olori orileede lagbaye ti n ki Tinubu ku oriire
Ileeṣẹ ọrọ okeere ni Amerika sọ pe akoko ọtun ni idibo naa gbe kalẹ fun idagbasoke ijọba tiwantiwa ati oṣelu Naijiria.
Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọrọ okeere ilẹ Amerika, Ned Price sọ ninu atẹjade kan pe ohun ti awọn kan at’awọn ẹgbẹ oṣelu kan n sọ pẹlu awọn ipenija to waye lasiko idibo naa n mu ki ọpọ maa pariwo pe magomago wa l’asiko idibo naa.
O wa ke si awọn alaṣẹ ajọ INEC lati tubọ jawe sobi lasiko idibo sipo gomina ati ile aṣofin ipinlẹ ti yoo waye lọjọ kọkanla oṣu kẹta, nitori gẹgẹ bi o ṣe sọ, awọn ọmọ Naijiria nreti ki iṣẹ wọn tubọ ta lẹnu sii.

Oríṣun àwòrán, screenshot
Bakan naa ni aarẹ orilẹede Ukraine, Voldymyr Zelensky ti ki Tinubu ku oriire pẹlu ireti pe ajọṣepọ Ukraine pẹlu Naijiria yoo tubọ gbopọn sii paapaa lori awọn ipenija agbaye bii ọwọngogo ounjẹ.
Aarẹ Ghana, Nana Akufo Addo ti ki Bila Tinubu ku oriire fun aṣeyọri ẹgbẹ oṣelu APC to n ṣe ijọba to si ni ni eyi yoo tubọ mu ki eto iṣejọba to giriki, ibọwọ fun ofinati ijafafa eto ọrọ aje Naijiria o gbopọn sii.
O ni oun n reti itẹsiwaju ajọṣepọ to loorin to ti n waye laarin orilẹede mejeeji.
Awon olori awọn orilẹede miran bii Niger, UK pẹlu tun ti ranṣẹ ikinikuroriire si Bọla Ahmed Tinubu.
Awọn kan ko fara mọ esi idibo
Awọn oludije fun ẹgbẹ oṣelu alatako lorilẹede Naijiria ti kọ lati kii ku oriire. Wọn ni awọn ko faramọ eto idibo naa eyi to gbe Tinubu wọle. Wọn ni loju awọn o, magomago wa ninu rẹ.
Atiku abubakar ti ẹgbẹ oṣelu PDP to ṣe ipo peji pelu ida mọkandinlọgbọn ati wi pe oun yoo lọ si ile ẹjọ.
Atiku ni eto idibo naa kuna awon ilana ati gbendeke to yẹ fun idibo.
O ṣe akawe idibo naa gẹgẹ bí 'ẹyi to buru julọ ninu itan ' latigba ti ko jọba ti bọ kuro lọwọ ologun.
Fun oludije ẹgbẹ oṣelu Labour Party, Peter Obi to ṣe ipo kẹta ninu ibo naa, o ni oun yoo fi ilana ofin fi idi rẹ mulẹ pe oun gan lo bori ibo naa.

Oríṣun àwòrán, Peter Obi/twitter
Obi ni eto idibo naa “ ko ba ilana aatẹẹle fun idibo mu”
Amọṣa o, igbimọ ipolongo ibo aarẹ fun APC ti da Obi lohun pe Tinubu lo bori ibo naa.
Igbimọ naa ni iyalẹnu lo jẹ fun oun lati maa gbọ o iruuru ẹsun ti ko l’ẹsẹ nlẹ lati ẹnu Obi lasiko to n ba awọn oniroyin sọrọ lori abajade ibo aarẹ ati ile aṣofin apapọ.
APC ni awọn faramọ igbesẹ rẹ lati gba ile ẹjọ lọ ati wi pe “ Ara ilana idibo ni lilọ si ile ẹjọ wa, o si wuyi pupọ”
Erongba fun iwọde

Oríṣun àwòrán, atiku abubakar/twitter
Alaga ẹgbẹ oṣelu PDP, Iyorchia Ayu pẹlu oludije fun ipo igbakeji aare lẹgbẹ oṣelu PDP gomina Ifeanyi Okowa ni awọn yoo ko iwọde sodi lọ si olu ileeṣẹ INEC nilu Abuja lọjọ Aje.
Ibrahim Bashir to je alamojuto eto akoso ni igbimọ ipolongo ibo lẹgbẹ oṣelu PDP ni iwọde naa yoo wa lati tako esi idibo naa.
Ipenija ti ajọ INEC dojukọ lasiko idibo naa
Bi o tilẹ jẹ pe alaga ajo INEC, Ọjọgbọn Mahmoud Yakubu ko fara mọ ẹsun magomago esi ibo ti wọn fi kan ajọ naa, o ni lootọ lawọn ipenija wa lasiko idibo naa
Oniruru ọrọ leti INEC ti gbọ nipa ti ẹrọ idibo igbalode BVAS ati ihuwasi awọn oṣiṣẹ ajọ naa lasiko idibo to kọja
“Lọsẹ to kọja oniruru awuyewuye lo jade nipa idibo apapọ to waye, eyi to n fẹ amojuto oni kiakia ati ti ọlọjọ gbọọrọ.
“A ṣe eto igbaradi fun idibo yii bi o ti tọ ati bi o ti yẹ, ṣugbọn awọn ipenija kan yọju, ninu eyi ti awọn miran ninu wọn jẹ eyi ti a ko ro ti tẹlẹ”
Alaga ajọ INEC, Ọjọgbọn Mahmoud wa sọ pe lilọ bibọ awọn ohun elo idibo, imọ ẹrọ, ihuwasi awọn oṣiṣẹ ajọ naa kan, ihuwasi awọn aṣoju ẹgbẹ oṣelu ati ololufẹ ẹgbẹ oselu gbogbo kun ara ipenija idibo ni Naijiria.












