Tinubu padà sí Eko, Ó ní iṣẹ́ ti bẹ̀rẹ̀ ní pẹrẹu

Oríṣun àwòrán, Bola Tinubu/twitter
Fun igba akọkọ lẹyin ti wọn kede rẹ gẹgẹ bi olubori ibo aarẹ to waye lorilẹede Naijiria lọjọ karundinlọgbọn oṣu keji ọdun 2023, Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu ti pada si ipinlẹ Eko tii ṣe orirun rẹ bayii.
Idaniloju ti Tinubu si sọ fun awọn eeyan ipinlẹ Eko ni pe oun ko ni ja wọn kulẹ gẹgẹ bi aarẹ ati pe gbogbo ileri ti oun ṣe lasiko ipolongo ni oun yoo ṣiṣẹ tọ.
Ọpọ ero ki Tinubu kaabọ si Eko
Ọpọ ero lo kọwọri lọ pade aarẹ ti ilu ṣẹṣẹ dibo yan lorilẹede Naijiria naa.
Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu lo lewaju awọn oṣiṣẹ ijọba Eko lọ pade rẹ.
Lẹyin eyi ni wọn gba aafin Ọba ilu Eko, Ọba Rilwan Akiolu nibiti obalaye naa, awọn obalaye miran at’awọn agba oloye ni ilu Eko ti gba a lalejo.
‘Eto idibo sipo aarẹ ti mo dije dabi ife ẹyẹ agbaye'

Oríṣun àwòrán, bola Tinubu/twitter
Nigba to n ba awọn ololufẹ rẹ sọrọ aṣiwaju Tinubu ni ọrọ idibo ti oun bori dabi idije bọọlu agbaye ni. O ni oun dupẹ lọwọ Eleduwa at’awọn eeyan ti wọn ṣugba rẹ.
Tinubu ni iṣẹ bẹrẹ fun oun lati da Naijiria pada si ipa idagbasoke ni kete ti oun ba ti de ori alefa.
O fi kun un pe oun yoo ṣe iṣẹ karakara lati rii pe oun ko ja araalu kulẹ.
Bakan naa lo dupẹ lọwọ awọn obalaye gbogbo fun aduroti wọn
Tinubu ti yan kadara adari - Akiolu

Oríṣun àwòrán, Bola Tinubu/twitter
Ọba Akiolu ki Asiwaju Bọla Ahmed Tinubu ku oriire aṣeyọri re.
O ni ko si aniani pe eledumare ti gbe ade aṣiwaju fun Tinubu ti ẹnikẹni ko si lee yii pada
Lara awọn obalaye to wa nikalẹ ni Ọba Elegushi ti Ikate-Elegushi, Oba Saheed Elegushi, ari Oniru ti ilu Iru, Oba Omogbolahan Lawal.












