Ìjọba àpapọ̀ gbọdọ̀ kó owó síta gẹ́gẹ́ bíi àṣẹ ilé ẹjọ́ – Akeredolu

Rotimi Akeredolu Aketi

Oríṣun àwòrán, Olabode Richard Olatunde

Gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu, ti ke si ijọba apapọ lati tẹle aṣẹ ile ẹjọ lori ọrọ owo nairan tuntun.

Akeredolu sọ pe ilana tuntun ti CBN gbe jade nipa owo naa ti ko ọpọ araalu sinu idamu.

O ni idajọ ile ẹjọ to ni ki awọn araalu maa na owo atijọ lọ ti mu idunnu ba awọn eeyan, oun si ṣetan lati lọ sile ẹjọ ti ijọba kankan ba lodi si idajọ ile ẹjọ naa.

Aketi lo sọ ọrọ naa ninu atẹjade kan loju opo Facebook rẹ.

O ni: “A gboṣuba kare fun ile ẹjọ to ga julọ ni Naijiria fun idajọ rẹ.”

“Niṣe ni gomina CBN ati adajọ agba Naijiria ṣi Aarẹ lọna lati sọ fun un pe o le ṣe ohun to ba tẹ ẹ lọrun lai bọwọ fun ofin.”

“Gomina CBN hu iwa alaibikita bo ṣe sọ pe agbara ti ofin fun oun loun n lo, bẹẹ ofin to da CBN silẹ ko fun ni irufẹ agbara bẹẹ.”

“Ijọba ti awọn ọmọ Naijiria ni itikuti, o si fi iya ti ko tọ jẹ wọn.”

“A ke si ijọba apapọ ko bọwọ fun aṣẹ ile ẹjọ lẹsẹkẹsẹ nitori ko si ọna abayọ mii ju ko ṣe bẹẹ lọ.”

Akeredolu sọ siwaju si pe ilana owo naira tuntun naa ni ọrọ oṣelu ninu, awọn araalu ko si tẹwọ gba a, nitori naa o tọ ki ijọba ṣe ohun ti ile ẹjọ pa laṣẹ, ti awon araalu si n bere fun.

Bi ọrọ naa ṣe bẹrẹ

Ti ẹ ko ba gbagbe, opin ọdun to kọja ni CBN kede owo naira tuntun, to si sọ pe opin yoo de ba owo ₦1000, ₦500 ati ₦200 atijọ ki awọn gomina kan to gbe ọrọ naa sile ẹjọ.

Bo tilẹ pe ile ẹjọ sọ pe ki awọn eeyan maa na owo atijọ naa lọ titi ti oun yoo fi gbe idajọ kalẹ, Aarẹ Muhammadu Buhari ati gomina CBN, Godwin Emefiele kọti ikun si aṣẹ naa.

Lẹyin orẹyin, ile ẹjọ ọhun ti sọ pe awọn araalu ṣi lee ma na owo naira atijọ ọhun lọ titi di opin ọdun bayii.

Amọ titi akoko ti a n ko iroyin yii jọ, awọn araalu ko ri owo na, yala owo atijọ ni o tabi owo naira tuntun ti wọn ṣẹṣẹ tẹ.