Ọmọ Ààrẹ tẹ́lẹ̀, Sani Abacha, Abdullahi, gba ojú orun dójú ikú!

Oríṣun àwòrán, @Naija_PR
Ọkan lara awọn ọmọ Sani Abacha, to ti fi akoko igba kan jẹ Aarẹ ologun Naijiria ri, Abdullahi Abacha, ti jade laye.
Iyawo gomina ipinlẹ Yobe, Mai Mala Buni, iyẹn Abacha-Buni, lo kede iku ọkunrin naa loju opo Instagram rẹ.
Ẹni ọdun mẹrindinlogoji ni Abdullahi ki ọlọjọ to de.
Abacha-Buni sọ loju opo Instagram rẹ pe “Ọdọ Ọlọrun ni a ti wa, ọdọ rẹ naa ni a n pada si.”
“Mo ti padanu aburo mi ọkunrin, Abdullahi Sani Abacha to gba oju orun doju iku.”
“Mo gbadura ki Ọlọrun dari gbogbo aiṣedede rẹ jin, ko si tẹ si afẹfẹ rere. Ẹ jọwọ ẹ maṣẹ gbagbe rẹ ninu adura yin.”
Abdullahi jẹ ọkan lara awọn ọmọ mẹsan an ti Sani Abacha fi silẹ saye.
Buhari ba mọlẹbi Abacha kẹdun
Aarẹ Muhammadu Buhari ti fi ọrọ ibanikẹdun ranṣẹ si aya Abacha, Maryam Abacha, lori iku ọmọ rẹ.
Ọrọ ibanikẹdun naa lo wa ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ Buhari, Garba Shehu, fi lede.
Atẹjade naa ni “Aarẹ gbadura fun ẹbi Abacha lori iku ọmọ wọn, Abdullahi.”
“Aarẹ tun gbadura ki Ọlọrun tu gbogbo awọn to n kẹdun iku ọdọkunrin naa ninu.”












