'Mo jẹ ekòló fún ọgbọ̀n ọjọ́ tí mo fi wà nínú aginjù'

Aworan Acosta

Ọkunrin kan, ọmọ orilẹede Bolivia ti ṣalaye bi o ṣe gbiyanju lati laaye fun ọjọ mọkanlelọgbọn to lo ninu ajinju lẹyin to sọnu.

Jhonattan Acosta, ẹni ọgbọn ọdun sọnu nigba ti oun atawọn ọrẹ rẹ mẹrin miiran dọdẹ lọ lapa ariwa orilẹede Bolivia.

O ni oun mu omi ti oun fi bata oun gbe, ti oun si jẹ ekolo ati kokoro miiran nitori oun ko le jade nibi ti oun sa pamọ si ki awọn ẹranko bii Amotekun ati awọn ẹlẹdẹ igbo ma ba ya oun jẹ.

Lẹyin o rẹyin ni awọn to n ṣe iwadii pada ri Acosta atawọn ọrẹ rẹ lẹyin oṣu kan ti wọn ti n wa kiri.

Pẹlu omije, Acosta ni "O yami lẹnu pe awọn eniyan le wa wa fun igba pipẹ bayii."

"Mo jẹ ekolo, mo je kokoro, ẹ ni gbagbọ gbogbo nnkan ti mo ni lati se lati wa laye

Acosta ni oun tun ni lati jẹ eso ati awọn egbogi miiran to yani lẹnu, to jẹ wi pe awọn ẹranko nikan lo maa n jẹ wọn.

"Modupẹ lọwọ Ọlọrun nitori o ti fun mi ni aye tuntun

Awọn mọlẹbi Acosta ni awọn si n gbiyanju lati gbọ gbogbo nnkan ti Acosta la kọja ninu aginju naa sugbọn o nilo akoko diẹ si lati ni alaafia bi o ṣe wa tẹlẹ.

Bakan naa ni wọn ni inu rẹ maa n bajẹ to ba ti ranti gbogbo nnkan ti oju rẹ ri ninu igbo ọhun.

Horacio Acosta to jẹ aburo Jhonattan Acosta sọ fun awọn akọroyin pe ẹgbọn oun fi ẹsẹ da lọjọ kẹrin to sọnu sinu igbo naa.

Horacio ati Jhonattan Acosta.

Oríṣun àwòrán, Reuters

Horacio ṣalaye pe ọta ibọn ẹyọkan lo ku ninu ibọn rẹ, ti ko le rin, pẹlu aini ireti pe ko si ẹnikẹni ti yoo wa oun ri.

Bakan naa lo ni ẹgbọn oun sọ fun oun bo ṣe ba awọn ẹranko nla bii amọtẹkun ati kiniun ja ninu igbo naa.

O ni o fi ibọn ọwọ rẹ le awọn ikoko jina lati ma baa ṣekupa sinu igbo.

O fi kun pe ẹgbọn oun ti pinu lati pa ọdẹ ṣiṣe ti pẹlu nnkan ti oju rẹ ri ninu igbo naa.